Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

APRIL 12, 2016
AZERBAIJAN

Àwọn Ọlọ́pàá Ṣèdíwọ́ Nígbà Tí Ìrántí Ikú Kristi Ń Lọ Lọ́wọ́ Nílùú Azerbaijan

Àwọn Ọlọ́pàá Ṣèdíwọ́ Nígbà Tí Ìrántí Ikú Kristi Ń Lọ Lọ́wọ́ Nílùú Azerbaijan

Ní March 23, 2016, àwọn ọlọ́pàá nílùú Gakh ṣàdédé ya wọ ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi, tó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù táwọn Ẹlẹ́rìí máa ń ṣe lọ́dọọdún. Inú ilé kan ni wọ́n kóra jọ sí tí wọ́n ti ń ṣe é. Àwọn ọlọ́pàá náà mú ìwé kan jáde tí wọ́n ní òfin fọwọ́ sí pé àwọn láṣẹ láti túlé. Bí àwọn ọlọ́pàá ọ̀hún ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í túlé wọn nìyẹn, wọ́n sì kó àwọn ìtẹ̀jáde ẹ̀sìn wọn, títí kan Bíbélì. Wọ́n wá kó gbogbo àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi náà lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, wọ́n fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò, wọ́n sì ní kí wọ́n kọ ohun tó ṣẹlẹ̀. Wọ́n wá dá gbogbo wọn sílẹ̀, àmọ́ àwọn ọlọ́pàá fẹ̀sùn kan ọkùnrin mẹ́fà lára àwọn Ẹlẹ́rìí náà. Ìyẹn sì lè mú kí àwọn ọkùnrin náà pa dà fojú ba ilé ẹjọ́ pé wọ́n rú òfin ìjọba.