Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

AZERBAIJAN

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Azerbaijan

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Azerbaijan

Ọdún 1999 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́kọ́ forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ nílùú Baku, ìjọba sì gbà kí wọ́n tún pa dà forúkọ sílẹ̀ lọ́dún 2002. * Láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, àwọn Ẹlẹ́rìí lómìnira láti máa ṣe ẹ̀sìn wọn déwọ̀n àyè kan, àmọ́ ìjọba ń fúngun mọ́ wọn, bí àpẹẹrẹ, àwọn ọlọ́pàá máa ń ya wọ ibi tí wọ́n bá ti ń jọ́sìn, ìjọba sì máa ń fòfin de àwọn ìwé wọn.

Àmọ́ lẹ́yìn tí Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn ṣàtúnṣe sí òfin ìjọba lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, ó túbọ̀ nira fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Azerbaijan láti ṣe ẹ̀sìn wọn. Lọ́dún 2010, àwọn Ẹlẹ́rìí kọ̀wé sí wọn láti tún forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, àmọ́ Ilé Iṣẹ́ Ìjọba yìí ò fọwọ́ sí i, bó ṣe di pé ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Baku ò fi bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ lábẹ́ òfin nìyẹn. Àwọn Ẹlẹ́rìí tún ti gbìyànjú láti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ láwọn ìlú míì lórílẹ̀-èdè Azerbaijan, àmọ́ kò bọ́ sí i.

Wọn ò yéé yọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu lórílẹ̀-èdè yìí, wọn ò sì jẹ́ kí wọ́n lómìnira. Àwọn ọlọ́pàá ti lọ tú ilé àwọn Ẹlẹ́rìí kan, wọ́n sì gba àwọn ohun ìní wọn lọ́wọ́ wọn, títí kan Bíbélì. Àwọn agbófinró ti mú àwọn Ẹlẹ́rìí kan torí pé wọ́n ń sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn míì, wọ́n sì ti pè wọ́n lẹ́jọ́. Ṣe ni ilé ẹjọ́ bu owó ìtanràn gọbọi lé wọn, tí wọ́n sì rán wọn lọ sẹ́wọ̀n. Torí pé ìjọba ò gbà káwọn Ẹlẹ́rìí forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀, ṣe làwọn aláṣẹ máa ń sọ pé kò bófin mu fún wọn láti máa jọ́sìn. Torí náà, wọ́n máa ń da ibi tí wọ́n ti ń jọ́sìn rú, wọ́n á mú àwọn tó wá síbẹ̀, wọ́n á sì bu owó ìtanràn gọbọi lé wọn.

Láti November 2015, Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn ò ní káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máà kó àwọn ìwé wọn tuntun wọ̀lú. Àmọ́ bí ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan ò ṣe jẹ́ kí wọ́n lómìnira ẹ̀sìn yìí ta ko àdéhùn tí ìjọba bá Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, ìjọba ò ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú lórílẹ̀-èdè náà. Èyí ti mú káwọn aláṣẹ máa yọ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu nígbà míì, wọ́n sì ń pè wọ́n lẹ́jọ́ tí wọ́n bá kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn.

Láti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Azerbaijan ò dákẹ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ìwé méjìlélógún [22] ni wọ́n ti kọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù kí wọ́n lè lómìnira ẹ̀sìn, wọ́n sì ti fẹjọ́ sun Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ní ẹ̀ẹ̀mẹrin. Àwọn aṣojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lọ bá àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Azerbaijan lórí ọ̀rọ̀ yìí, kí wọ́n lè wá nǹkan ṣe sí ẹ̀tọ́ tí wọ́n fi ń du àwọn èèyàn yìí.

^ ìpínrọ̀ 2 Orúkọ tí wọ́n pa dà fi sílẹ̀ ni Religious Community of Jehovah’s Witnesses in the Azerbaijani Republic