Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

MARCH 7, 2016
AZERBAIJAN

Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova Pe Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn

Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova Pe Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn

Ní March 9, 2016, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó wà ní Baku máa gbọ́ ẹjọ́ Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova torí àwọn obìnrin náà sọ pé kò bófin mu bí wọ́n ṣe sọ pé àwọn jẹ̀bi torí pé àwọn ń pín ìtẹ̀jáde tó dá lórí ẹ̀sìn. Àwọn obìnrin náà fẹ́ kí wọ́n dá àwọn sílẹ̀, kí wọ́n san gbogbo owó tí àwọn ná lórí ẹjọ́ náà pa dà, kí wọ́n sì san owó ìtanràn torí wọ́n fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n bí ìjọba ṣe fi wọ́n sẹ́wọ̀n fún nǹkan bí ọdún kan.

Kó tó di pé wọ́n gbọ́ ẹjọ́ náà, Àwùjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìtinimọ́lé Láìnídìí lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè, ìyẹn UN Working Group on Arbitrary Detention fi Ìpinnu kan lọ́lẹ̀ tó fi hàn pé ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan ti fi ẹ̀tọ́ Arábìnrin Zakharchenko àti Arábìnrin Jabrayilova dù wọ́n, àti pé ó yẹ kí wọ́n san owó ìtanràn fún àwọn obìnrin náà. Ní January 28, 2016, ilé ẹjọ́ fọwọ́ rọ́ ìpinnu náà sẹ́yìn, wọ́n sì sọ pé àwọn obìnrin náà jẹ̀bi.