Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

AZERBAIJAN

Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́

Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́

Ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan ṣì ń fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé wọ́n ń ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Ilé ẹjọ́ ń dá wọn lẹ́bi torí pé wọ́n ń kóra jọ láti jọ́sìn, torí pé wọ́n ń sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn míì àti pé wọ́n ń kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun torí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí ọkàn. Àwọn adájọ́ sábà máa ń bu owó ìtanràn gọbọi lé wọn, wọ́n sì máa ń tì wọ́n mọ́lé.

Wọ́n Fi Obìnrin Méjì Sẹ́wọ̀n Torí Wọ́n Ń Sọ Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́ Fáwọn Míì

Ní December 17, 2015, ilé ẹjọ́ Pirallahi nílùú Baku bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ẹjọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì, ìyẹn Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova. Àwọn obìnrin méjèèjì yìí ti wà látìmọ́lé láti February 17, 2015 kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ wọn, wọ́n fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ń pín ìwé ẹ̀sìn láìgba “àṣẹ tó yẹ.”

Oṣù mẹ́wàá tí wọ́n lò látìmọ́lé yìí ti kó bá ìlera àwọn obìnrin méjèèjì yìí, inú wọn ò sì dùn rárá. Àmọ́ nígbà tí ilé ẹjọ́ kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ wọn, adájọ́ ò gba gbogbo ohun tí wọ́n sọ. Wọ́n tiẹ̀ tún ní kó jẹ́ káwọn kúrò látìmọ́lé, káwọn pa dà sílé káwọn má sì jáde nílé títí wọ́n á fi gbọ́ ẹjọ́ àwọn, àmọ́ adájọ́ kọ̀ jálẹ̀. Ó ti sún ìgbẹ́jọ́ náà sí January 7, 2016.

Ìjọba Azerbaijan Ò Ṣe Ojúṣe Wọn

Ní May 2011, Àjọ Ilẹ̀ Yúróòpù Tó Ń Gbógun Ti Ìwà Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti Ẹ̀tanú (ìyẹn àjọ ECRI) tó ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù gbé ìròyìn kan jáde. Wọ́n rọ ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan léraléra pé kí wọ́n rí i pé “òfin tí wọ́n ń lò . . . fàyè gba òmìnira ẹ̀sìn délẹ̀délẹ̀, bó ṣe wà nínú àdéhùn European Convention on Human Rights.” Lọ́dún 2012, Àjọ ti ìlú Venice tó wà lábẹ́ Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù ṣe ìwé kan tí àlàyé rẹ̀ kún rẹ́rẹ́, wọ́n fi dábàá fún ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan pé kí wọ́n ṣàtúnṣe sí Òfin tí wọ́n ṣe lórí ọ̀rọ̀ òmìnira ẹ̀sìn. Ìwé náà sọ pé: “Ó jọ pé Òfin yìí sọ oríṣiríṣi nǹkan tó ń káni lọ́wọ́ kò, tó sì ta ko ìlànà tí ìjọba àpapọ̀ fi lélẹ̀ kárí ayé. . . . Ó yẹ kí wọ́n ṣàtúnṣe sí àwọn ohun pàtàkì kan tó wà nínú òfin náà, bí ohun tí òfin náà dá lé, àwọn tó lẹ́tọ̀ọ́ láti lómìnira ẹ̀sìn àti ẹ̀rí ọkàn, fífi orúkọ ẹ̀sìn sílẹ̀, àwọn ẹ̀sìn tó lè dá dúró àtàwọn tí wọ́n lè fòfin dè; ọ̀rọ̀ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, ọ̀rọ̀ yíyí àwọn èèyàn lẹ́sìn pa dà, títí kan ọ̀rọ̀ títẹ ìwé ìsìn àti pípín in kiri.”

Ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan kì í tún fọwọ́ sí i pé káwọn èèyàn kọ iṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kí wọ́n ṣe é. Nígbà tí orílẹ̀-èdè náà fẹ́ wọ Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù lọ́dún 1996, wọ́n tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn pé àwọn máa (1) ṣe òfin tó fọwọ́ sí iṣẹ́ àṣesìnlú láàárín ọdún méjì táwọn bá ti dara ìgbìmọ̀ náà, (2) dá gbogbo àwọn tó wà lẹ́wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun sílẹ̀, àti pé àwọn máa (3) jẹ́ kí àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun yan iṣẹ́ àṣesìnlú dípò. Ó ti lé ní ọdún mẹ́tàlá [13] báyìí tí orílẹ̀-èdè Azerbaijan ti di ara Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù, àmọ́ wọn ò tíì ṣe ojúṣe wọn.

Ìròyìn kan náà tó jáde ní May 2011 yẹn sọ pé: “Àjọ ECRI rọ àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Azerbaijan pé kí wọ́n yára ṣòfin tó fọwọ́ sí iṣẹ́ àṣesìnlú bí ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ Yúróòpù ṣe sọ. . . . [àjọ ECRI] ò fọ̀rọ̀ yìí ṣeré rárá, wọ́n ń tún un sọ pé kí àwọn aláṣẹ má ṣe dá àwọn tó kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun lẹ́bi tàbí kí wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n, àmọ́ kí wọ́n jẹ́ kí wọ́n ṣe ojúṣe wọn fún ìlú lọ́nà tí kò ní ta ko ẹ̀rí ọkàn wọn.”

Ṣé Ìjọba Azerbaijan Máa Ṣohun Tó Fi Hàn Pé Òótọ́ Làwọn Jẹ́ Kí Àwọn Ẹlẹ́sìn Lómìnira, Bí Wọ́n Ṣe Sọ?

Ní June 25, 2015, àjọ Helsinki Commission lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ bó ṣe ká wọn lára pé “lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n ti túbọ̀ ń fúngun mọ́ àwọn ẹlẹ́sìn kéékèèké lórílẹ̀-èdè Azerbaijan, pàápàá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Representative Chris Smith tó jẹ́ alága àjọ náà sọ pé: “Ìjọba máa ń yin ara wọn pé àwọn jẹ́ káwọn aráàlú lómìnira ẹ̀sìn, àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni wọ́n ti fi sẹ́wọ̀n torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Mò ń fi gbogbo ẹnu sọ ọ́ pé kí Ìjọba Orílẹ̀-èdè Azerbaijan dá Arábìnrin Zacharchenko àti Arábìnrin Jabrayilova sílẹ̀ lójú ẹsẹ̀.”

Kárí ayé lọ̀rọ̀ Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova ti ń ká àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lára. Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè kọ̀wé sílé ẹjọ́ pé kí wọ́n dá Arábìnrin Zakharchenko sílẹ̀ kó máa lọ ilé àmọ́ kí wọ́n má jẹ́ kó jáde nílé, ṣùgbọ́n ilé ẹjọ́ ò fọwọ́ sí i. Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni Arábìnrin Zacharchenko àti Arábìnrin Jabrayilova pẹ̀lú ìdílé wọn àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn ń bẹ ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan pé kí wọ́n dá àwọn sílẹ̀ lójú ẹsẹ̀, kí wọ́n sì dá wọn láre.

Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀

 1. December 17, 2015

  Ilé Ẹjọ́ Pirallahi nílùú Baku kọ̀ láti dá Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Wọ́n ti sún ìgbẹ́jọ́ náà sí January 7, 2016.

 2. September 4, 2015

  Ilé Ẹjọ́ Sabail nílùú Baku sún àtìmọ́lé Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova títí di December 17, 2015 kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ wọn, ìgbà yẹn ló máa pé oṣù mẹ́wàá tí wọ́n ti wà látìmọ́lé.

 3. May 7, 2015, àti July 4, 2015

  Ilé Ẹjọ́ Sabail nílùú Baku sún àtìmọ́lé Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova síwájú.

 4. February 17, 2015

  Ilé Ẹjọ́ Sabail nílùú Baku sọ pé kí wọ́n fi Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova sí àtìmọ́lé lójú ẹsẹ̀ fún oṣù mẹ́ta kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ wọn, torí wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn wọ́n pé wọ́n ń pín ìwé ẹ̀sìn láìbófin mu.

 5. March 12, 2013

  Ilé ẹjọ́ dá Kamran Mirzayev, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́bi torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun, wọ́n sì rán an lọ sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́sàn-án. Kò tíì pẹ́ lẹ́wọ̀n tí wọ́n fi dá a sílẹ̀ nígbà tí ìjọba ń dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀.

 6. September 25, 2012

  Ilé ẹjọ́ dá Fakhraddin Mirzayev, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́bi torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun, wọ́n sì rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan.

 7. September 8, 2010

  Ilé ẹjọ́ dá Farid Mammadov, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́bi torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun, wọ́n sì rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́sàn-án.

 8. August 19, 2009

  Wọ́n tún mú Mushfig Mammedov torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun, wọ́n wá tì í mọ́lé kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, wọ́n sì bu owó ìtanràn lé e lẹ́ẹ̀kejì tí wọ́n dá a lẹ́bi.

 9. March 7, 2008

  Àwọn agbẹjọ́rò Ọ̀gbẹ́ni Mushfig Mammedov àti Samir Huseynov kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù torí pé ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan dá wọn lẹ́bi pé ọ̀daràn ni wọ́n torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

 10. October 4, 2007

  Ilé ẹjọ́ dá Samir Huseynov, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́bi torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun, wọ́n sì rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́wàá.

 11. 2006

  Wọ́n fi Mushfig Mammedov, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí àtìmọ́lé kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, wọ́n dá a lẹ́bi torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun, wọ́n wá ní kó máa lọ, àmọ́ wọ́n á ṣì máa ṣọ́ ọ fún oṣù mẹ́fà.