Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ọ̀ràn Ẹjọ́ àti Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tí Wọ́n Fi Sẹ́wọ̀n Pọ̀ sí I Lẹ́yìn Táwọn Agbófinró Fìbínú Ya Wọ Ilé Àwọn Èèyàn ní Rọ́ṣíà

Inúnibíni táwọn aláṣẹ Rọ́ṣíà ń ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti légbá kan, wọ́n ń mú wọn, wọ́n sì ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n lórí pé wọ́n ń ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tí Wọ́n Fi Sẹ́wọ̀n Pọ̀ sí I Lẹ́yìn Táwọn Agbófinró Fìbínú Ya Wọ Ilé Àwọn Èèyàn ní Rọ́ṣíà

Inúnibíni táwọn aláṣẹ Rọ́ṣíà ń ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti légbá kan, wọ́n ń mú wọn, wọ́n sì ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n lórí pé wọ́n ń ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́.

Wọ́n Fi Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́—Ibì Kọ̀ọ̀kan

Àwọn ibi tí wọ́n ti fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n torí wọ́n ń ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́, wọ́n sì ń lo ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tí wọ́n ní. Wọ́n máa ń hùwà ìkà sí wọn lẹ́wọ̀n nígbà míì.

RUSSIA

Ẹlẹ́rìí Jèhófà Míì Tún Ti Fojú Ba Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́ṣíà Lórí Ẹ̀sùn Pé Ó Ń Ṣiṣẹ́ Agbawèrèmẹ́sìn

Ẹni àádọ́rin ọdún ni Arkadya Akopyan, aránṣọ tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ni, Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ni. Kò mọwọ́ mẹsẹ̀, kì í tẹ òfin ìlú lójú, ohun tó sì fẹ́ ò ju pé kó máa jọ́sìn Ọlọ́run ní àlàáfíà.

RUSSIA

Ilé Ẹjọ́ Ìlú Oryol Gbọ́ Tẹnu Àwọn Ẹlẹ́rìí Fúngbà Àkọ́kọ́ Níbi Ìgbẹ́jọ́ Dennis Christensen

Dennis Christensen ti wà látìmọ́lé láti May 2017. Wọ́n lè ní kó lọ fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà sí mẹ́wàá gbára torí pé ó kàn ń ṣe ohun tó gbà gbọ́.

RUSSIA

Wọ́n Ti Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣúkaṣùka Lórílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà

Ní báyìí tí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti fòpin sí àjọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò lábẹ́ òfin, àwọn Ẹlẹ́rìí àti ìjọsìn wọn ni wọ́n wá dojú àtakò kọ.

ERITREA

Ẹlẹ́rìí Jèhófà Méjì Tó Ti Dàgbà Kú Sẹ́wọ̀n ní Eritrea

Habtemichael Tesfamariam àti Habtemichael Mekonen kú sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Mai Serwa níbẹ̀rẹ̀ ọdún 2018. Wọ́n fi àwọn méjèèjì sẹ́wọ̀n láìtọ́ torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́, wọ́n fojú wọn gbolẹ̀ gan-an lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n sì hùwà ìkà sí wọn. Wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ lò tó ọdún mẹ́wàá níbẹ̀.

KAZAKHSTAN

Wọ́n Dá Teymur Akhmedov Sílẹ̀ Torí Pé Ààrẹ Dárí Jì Í

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Kazakhstan dárí ji Teymur Akhmedov, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó ti lé lọ́dún kan tó ti wà lẹ́wọ̀n torí pé ó wàásù ohun tó gbà gbọ́ fáwọn èèyàn. Ìdáríjì náà ṣe àfọ̀mọ́ ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kúrò lọ́rùn rẹ̀.

TURKMENISTAN

Orílẹ̀-Èdè Turkmenistan Gbójú Fo Òmìnira Láti Ṣe Ohun Tó Bá Ẹ̀rí Ọ̀kan Ẹni Mu

Wọ́n ju méjì lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Orílẹ̀-èdè Turkmenistan ò tíì gbà pé èèyàn ní ẹ̀tọ́ láti kọ ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò gbà bí wọ́n bá ní kó wá ṣe iṣẹ́ ológun, kò sì ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì dípò iṣẹ́ ológun.