Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ìsọfúnni Tó Ṣeé Wà Jáde

 

Àwọn Wo Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Àlàyé ṣókí nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Yúróòpù, títí kan àlàyé ṣókí nípa àwọn pàtàkì kan tí wọ́n gbà gbọ́.

Àǹfààní Tó Wà Nínú Ìtẹ̀jáde Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ìtẹ̀jáde táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe máa ń mú káwọn èèyàn lóye Bíbélì, kí wọ́n sì rí bí ọ̀rọ̀ Bíbélì ṣe wúlò tó.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Àwọn Aráàlú

Gbogbo èèyàn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kà sí láwùjọ, ọ̀rọ̀ àwọn aráàlú jẹ wọ́n lógún, wọ́n sì máa ń fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti rọ̀ mọ́ ohun tí wọ́n gbà gbọ́.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Iṣẹ́ Ìwàásù Wọn

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọyì ẹ̀tọ́ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n ní. Ara ọ̀nà tí wọ́n ń gbà lo ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní yìí ni pé wọ́n máa ń sọ ìròyìn ayọ̀ tó wà nínú Bíbélì fáwọn aládùúgbò wọn.

Ìdílé

Ọwọ́ pàtàkì ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi mú ọ̀rọ̀ ìdílé, wọ́n sì máa ń sapá láti tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì kí wọ́n lè ṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé láǹfààní. Wọ́n mọyì ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti fi ohun tí wọ́n gbà gbọ́ kọ́ àwọn ọmọ wọn.

Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè

Ìdáhùn sí ìbéèrè mẹ́wàá táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ìtọ́jú Nílé Ìwòsàn

Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá fẹ́ gbàtọ́jú nílé ìwòsàn, ìtọ́jú tí kò ní la gbígba ẹ̀jẹ̀ sára lọ ni wọ́n máa ń fẹ́. Wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti gba irú ìtọ́jú tí wọ́n bá fẹ́, ìtọ́jú tó dáa jù lọ sì ni wọ́n máa ń fẹ́ fún ara wọn àtàwọn ọmọ wọn.

Ẹ̀rí Ọkàn Kì Í Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun

Òfin ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ̀ pé òun ò ṣiṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kó ṣe é. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dùn tí ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè ò bá fi ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti kọ iṣẹ́ ológun dù wọ́n, ìyẹn, tí wọ́n bá jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun tàbí tí wọn ò tiẹ̀ fà wọ́n wọṣẹ́ ológun rárá.

Wọn Kì Í Dá sí Òṣèlú

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé òfin ìlú, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í dá sí òṣèlú.

Òfin Fọwọ́ sí Ẹ̀sìn Wọn ní Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù

Àlàyé ṣókí nípa bí òfin ṣe fọwọ́ sí ìsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù.

A Máa Ń Kóra Jọ Láti Jọ́sìn

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọyì ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti kóra jọ lómìnira pẹ̀lú àwọn ará wọn. Tí wọ́n bá kóra jọ láti jọ́sìn, wọ́n máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹnikẹ́ni ló sì lè wá bá wọn jọ́sìn.

Ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nílùú Moscow àti Ìjọba Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà

Àlàyé ṣókí nípa bí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ṣe dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Moscow láre.