Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lára àwọn márùndínláàádọ́rin (65) ará wa tí wọ́n dá sílẹ̀ lẹ́yìn tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ dájọ́ pé ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn fẹ́ kì í ṣe ìwà ọ̀daràn.

MARCH 7, 2019
SOUTH KOREA

Wọ́n Ti Dá Gbogbo Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tó Wà Lẹ́wọ̀n Torí Pé Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun Sílẹ̀ ní South Korea

Wọ́n Ti Dá Gbogbo Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tó Wà Lẹ́wọ̀n Torí Pé Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun Sílẹ̀ ní South Korea

Ní February 28, 2019, wọ́n dá ẹni tó gbẹ̀yìn lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lẹ́wọ̀n torí àìdá sọ́rọ̀ òṣèlú sílẹ̀ ní South Korea. Gbogbo àwọn tí wọ́n dá sílẹ̀ náà dúpẹ́ torí òmìnira tí wọ́n rí gbà àti bí wọ́n ṣe sapá láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run.

Lẹ́yìn ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe ní November 1, 2018, tó fi hàn pé ẹni tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò bá gbà láyè láti ṣiṣẹ́ ológun kì í ṣe ọ̀daràn, wọ́n ti dá arákùnrin márùndínláàádọ́rin (65) sílẹ̀. Ìdájọ́ yìí ló fòpin sí bí wọ́n ṣe ń ju àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun sẹ́wọ̀n látọdún márùndínláàádọ́rin sẹ́yìn.

Ìgbàgbọ́ àti ìṣòtítọ́ àwọn ará wa ní Korean jẹ́ kóríyá fún gbogbo wa láti ‘túbọ̀ máa fi ìgboyà’ àti òtítọ́ sin Ọba wa àti ìjọba rẹ̀. (Fílípì 1:14) À ń gbàdúrà fún àwọn ará wa tó ṣì wà lẹ́wọ̀n ní Eritrea, Rọ́ṣíà, Singapore àti Turkmenistan.—Hébérù 10:34.