Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SINGAPORE

Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́​—Singapore

Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́​—Singapore

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin mọ́kànlá (11) tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wà lẹ́wọ̀n lórílẹ̀-èdè Singapore torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Ìgbà kejì nìyí tí mẹ́fà lára wọn máa ṣẹ̀wọ̀n torí pé wọn ò yíhùn pa dà lẹ́yìn tí wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n nígbà àkọ́kọ́. Kò sí báwọn ọ̀dọ́ yìí ṣe lè fi ọ̀rọ̀ òfin tọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn torí ìjọba orílẹ̀-èdè Singapore ti sọ pé dandan ni káwọn èèyàn wọṣẹ́ ológun, wọn ò sì gbà pé ẹnikẹ́ni lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé ẹ̀rí ọkàn òun ò gba òun láyè.

Tí ọ̀dọ́kùnrin kan bá ti pé ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) lórílẹ̀-èdè Singapore, wọ́n máa ní kó wá wọṣẹ́ ológun. Tó bá kọ̀, torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣe é, wọ́n á fi sí àtìmọ́lé ní àgọ́ àwọn ológun fún nǹkan bí oṣù méjìlá (12). Tó bá ti lo ọjọ́ ẹ̀ pé lẹ́wọ̀n, wọ́n á dá a sílẹ̀. Wọ́n á wá pàṣẹ pé kó wọ aṣọ ológun lójú ẹsẹ̀, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ológun. Tó bá tún kọ̀ pé òun ò ṣe, wọ́n á ní kó fojú ba ilé ẹjọ́ lẹ́ẹ̀kejì, wọ́n sì lè jù ú sẹ́wọ̀n fún nǹkan bí oṣù méjìdínlógún (18). Nítorí náà, ẹ̀ẹ̀mejì làwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n wọṣẹ́ ológun máa ń ṣẹ̀wọ̀n, àpapọ̀ àsìkò tí wọ́n ń lò lẹ́wọ̀n sì máa ń tó ọgbọ̀n (30) oṣù.

Orílẹ̀-Èdè Singapore Ò Gbà Láti Ṣe Ohun Tí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé Ní Kí Wọ́n Ṣe

Ọjọ́ pẹ́ tí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé ti ń rọ àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ wọn pé “kí wọ́n má fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà láyè láti ṣiṣẹ́ ológun dù wọ́n torí pé ẹ̀tọ́ láti ní èrò tó wuni, láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn ẹni gbà láyè àti ẹ̀sìn tó wuni ni wọ́n ń tẹ̀ lé, ìyẹn sì bófin mu torí ó wà nínú ìwé Universal Declaration of Human Rights.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Singapore ti wà lábẹ́ Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé látọdún 1965, kò fara mọ́ ohun tí àjọ náà sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Nínú lẹ́tà tí òṣìṣẹ́ ìjọba kan lórílẹ̀-èdè Singapore kọ sí Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé ní April 24, 2002, ó sọ pé “tí ohun tí ẹnì kan gbà gbọ́ tàbí tó ń ṣe bá ti ta ko [ẹ̀tọ́ láti gbèjà orílẹ̀-èdè], ẹ̀tọ́ tí orílẹ̀-èdè ní láti pèsè ààbò ló gbọ́dọ̀ gbawájú.” Òṣìṣẹ́ náà sojú abẹ níkòó pé, “A ò fara mọ́ ọn pé ibi gbogbo láyé ni àwọn èèyàn ti lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè.”

Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀

 1. February 16, 2024

  Lápapọ̀, Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́kànlá (11) ni wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè láti ṣiṣẹ́ ológun.

 2. April 24, 2002

  Òṣìṣẹ́ ìjọba fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé orílẹ̀-èdè Singapore ò fara mọ́ ọn pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ ò gbà á láyè.

 3. February 1995

  Wọ́n túbọ̀ ń ká àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Singapore tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ kò, wọ́n sì ń mú wọn.

 4. August 8, 1994

  Ilé Ẹjọ́ Gíga lórílẹ̀-èdè Singapore ò fọwọ́ sí ohun táwa Ẹlẹ́rìí béèrè.

 5. January 12, 1972

  Lẹ́yìn táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, ìjọba orílẹ̀-èdè Singapore yọ orúkọ wa kúrò.