Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

(Apá òsì) Lára àwọn ohun tá a lè ṣe ká lè dáàbò bo ara wa ni pé ká jẹ́ kí ilé wa àti Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní nígbà gbogbo; (Àárín) Láwọn ibi tí àrùn náà ti ṣọṣẹ́, àwọn akéde kan lè yàn láti wàásù láwọn ọ̀nà míì, bíi kí wọ́n wàásù lórí fóònù; (Ọ̀tún) Tó bá gbà bẹ́ẹ̀ lágbègbè yín, tó sì jẹ́ pé àrùn yìí ti ṣọṣẹ́ níbẹ̀, àwọn alàgbà lè ṣètò bẹ́ ẹ ṣe máa rí àwọn ìpàdé tá a ti gbé sórí ẹ̀rọ

MARCH 3, 2020
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Àrùn Corona àti Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Ṣe

Àrùn Corona àti Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Ṣe

Orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kíyè sí àrùn kan tí wọ́n ń pè ní coronavirus tó ń ṣọṣẹ́ báyìí (wọ́n tún ń pè é ní COVID-19). A mọ̀ pé ara ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ ni pé àjàkálẹ̀ àrùn máa jẹ́ ọ̀kan lára àmì tó máa fi hàn pé a ti wà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. (Lúùkù 21:11) Níbí tí àjàkálẹ̀ àrùn yìí bá ti bẹ́ sílẹ̀, ó bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn kíyè sára kó lè dáàbò bo ara rẹ̀ àtàwọn míì.​—Òwe 22:3.

Ó lè máa ṣe àwọn kan láti mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó wà láwọn ibi tí àrùn náà ti ṣọṣẹ́. Ọṣẹ́ tí àrùn yìí ṣe ti mú kí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kan àtàwọn ìjọ kan ní Ítálì, Japan, South Korea àtàwọn orílẹ̀-èdè míì gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan. Àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kan ti wọ́gi lé ìkésíni táwọn kan ṣe láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn, wọn ò sì gba ẹnikẹ́ni láyé láti ṣè ìbẹ̀wò. Láwọn ibòmíì sì rèé, ìjọba ò gbà kí ọ̀pọ̀ èèyàn pàdé pọ̀ níbi kan, èyí sì tí mú kí ẹ̀ka ọ́fíìsì fagi lé àwọn àpéjọ àyíká kan. Láfikún sí i, àwọn ìjọ kan ti ṣe àtúnṣe sí ètò tí wọn ṣe fún iṣẹ́ ìwàásù àti ìpàdé ìjọ láwọn àgbègbè kan. Láìka gbogbo ìpèníjà yìí sí, àwọn ará wa ń bá a lọ láti gbé ara wọn rò nípa tẹ̀mí, wọ́n sì ń fún ara wọn níṣìírí.​—Júùdù 20, 21.

Torí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, àwọn ará wa ti rí i pé àwọn ìlànà tó wà nísàlẹ̀ yìí gbéṣẹ́ gan-an. Tó bá jẹ́ pé àrùn yìí ti ṣe ọṣẹ́ dé ibi tó ò ń gbé, àwọn ìlànà yìí máa ran ìwọ àti ìdílé rẹ lọ́wọ́.

  • Má Ṣe Bẹ̀rù. Lóòótọ́, ó yẹ kó o wà lójúfò bó o ṣe ń gbọ́ nípa bí àrùn yìí ṣe ń jà ràn-ìn kó o sì gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ, síbẹ̀ àwọn nǹkan tó yẹ kó o ṣe kó o lè dáàbò bó ara rẹ ló yẹ kó gbà ẹ́ lọ́kàn kì í ṣe kó o wá jẹ́ kí ìbẹ̀rù bó ẹ̀ mọ́lẹ̀.​—Òwe 14:15; Àìsáyà 30:15.

  • Ṣe Àwọn Ohun Tí Ìjọba Bá Ni Kó O Ṣe, Kó O sì Tẹ̀ Lé Ìtọ́ni. Àwọn aláṣẹ ìlú tàbí orílẹ̀-èdè sábà máa ń ki àwọn ará ìlú nílọ̀ tàbí kí wọ́n ṣe àwọn òfin kónílé-gbélé kí wọ́n má bàá lùgbàdì àrùn. Ó máa dáa kéèyàn mọ̀ nípa àwọn ìgbésẹ̀ yìí, kó sì tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni ìjọba.​—Róòmù 13:1.

  • Máa Wà Ní Mímọ́. Ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa fọ ọwọ́ rẹ̀ déédéé pẹ̀lú ọṣẹ àti oògùn olómi apakòkòrò tí wọ́n fi ọtí ṣe. A tún gbọ́dọ̀ máa jẹ́ kí ilé wa àti Gbọ̀ngàn Ìjọba wa wà ní mímọ́ tónítóní. Láfikún sí i, àwọn onímọ̀ nípa ìtọ́jú ìṣègùn sọ pé kó dáa kéèyàn máa bọ́ ara wọn lọ́wọ́ láwọn ibi tí àrùn náà bá ti ṣọṣẹ́, torí ó máa jẹ́ kí àrùn náà tètè gbilẹ̀. Nípa àrùn coronavirus yìí, Àjọ Ìlera Àgbáyé ti pèsè àfikún àlàyé tó máa ran àwọn ará ìlú lọ́wọ́.

  • Fi Ìfẹ́ Hàn sí Àwọn Míì. Òótọ́ ni pé, a mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn máa lọ sí ìpàdé Kristẹni àti òde ẹ̀rí déédéé, àmọ́ tó bá rẹ̀ ọ́, ó máa dáa gan-an kó o dúró sílé kí àìsàn náà má bàá ran àwọn míì. Èyí máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, a sì fẹ́ dáàbò bo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa títí kan àwọn aládùúgbò wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí.​—Mátíù 22:39.

  • Tẹ̀ Lé Ètò Tí Ìjọ Ṣe. Láwọn àgbègbè tí àrùn yìí ti ṣọṣẹ́, ó lè pọndandan kí ẹ̀ka ọ́fíìsì sọ fún àwọn ará pé kò ní sí ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àtàwọn àpéjọ Kristẹni míì títí tí àrùn náà á fi kásẹ̀ nílẹ̀. Ohun tá a sì ṣe nìyẹn láwọn ibi tí àrùn yìí ti ṣọṣẹ́ gan-an pàápàá láwọn agbègbè kan ní Ítálì, Japan àti South Korea. Tó bá gbà bẹ́ẹ̀ lágbègbè yín, àwọn alàgbà lè ṣètò bẹ́ ẹ ṣe máa rí àwọn ìpàdé tá a ti gbé sórí ẹ̀rọ, èyí tí àwọn akéde lè wò nínú ilé. Àwọn akéde lè máa wàásù láti orí fóònù, wọ́n lè fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ látorí fóònù, e-mail, tàbí kí wọ́n kọ lẹ́tà.

ÀWỌN ÀFIKÚN ÌSỌFÚNNI TÓ WÀ NÍNÚ ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE WA