Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MARCH 5, 2020
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Ìròyìn Iṣẹ́ Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí 2019​​—Bá A Ṣe Ń Ran Àwọn Ará Wa Lọ́wọ́ Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀

Ìròyìn Iṣẹ́ Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí 2019​​—Bá A Ṣe Ń Ran Àwọn Ará Wa Lọ́wọ́ Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀

Ìròyìn Iṣẹ́ Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí ọdún 2019 tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ Bá A Ṣe Ń Ran Àwọn Ará Wa Lọ́wọ́ Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀ ṣàlàyé bí ètò Ọlọ́run ṣe máa ń ran àwọn ará kárí ayé lọ́wọ́ nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì bá wáyé. Nínú ìròyìn náà, a sọ̀rọ̀ nípa ohun táwọn ará ṣe nígbà tí ìmìtìtì ilẹ̀ àti àkúnya omi wáyé ní Indonéṣíà, a sì máa rí ohun táwọn ará ṣe ní Nàìjíríà nígbà tí ibà pọ́njú bẹ̀rẹ̀ lágbègbè kan. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí tí àrùn novel coronavirus (tá a mọ̀ sí COVID-19) ń ṣọṣẹ́ kárí ayé, Ìgbìmọ̀ Olùdarí a máa fún àwọn ará tó wà láwọn agbègbè tí àrùn náà ti ń ràn ní ìtọ́ni tí wọ́n á máa tẹ̀ lé.