Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

APRIL 29, 2020
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Fọ́tò Àwọn Ará Wa Níbi Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Kári Ayé Nígbà Ìrántí ikú Kristi Ọdún 2020

Àwọn Ará Wa Kárí Ayé Fi Hàn Pé Àwọn Mọyì Ìràpadà, Bí Wọn Ò Tiẹ̀ Ráyè Pàdé Pọ̀

Fọ́tò Àwọn Ará Wa Níbi Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Kári Ayé Nígbà Ìrántí ikú Kristi Ọdún 2020

Lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀ ní April 7, 2020, àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣe Ìrántí Ikú Kristi níbi gbogbo láyé lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àrùn corona ò jẹ́ kí èyí tó pọ̀ jù nínú wọn kóra jọ, síbẹ̀ gbogbo wọn ló pinnu pé àwọn máa pa àṣẹ Jésù mọ́, tó sọ pé “ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Gbogbo àwọn ará, látorí àwọn tó ń dá gbé, àwọn tọkọtaya, àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn, títí kan àwọn àgbàlagbà wa ọ̀wọ́n ló fi hàn pé àwọn mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù Kristi, Ọmọ Rẹ̀ ṣe.

A fẹ́ kí ẹ wo fọ́tò àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láyé nígbà tí wọ́n ń múra Ìrántí Ikú Kristi ọdún 2020 sílẹ̀ àtìgbà tí wọ́n ń ṣe é.