Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 30, 2021
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

A Ti Fi Apá Tuntun Tá A Pè Ní Appearance Settings Sórí Ìkànnì JW.ORG

A Ti Fi Apá Tuntun Tá A Pè Ní Appearance Settings Sórí Ìkànnì JW.ORG

A ti fi apá tuntun kan tọ́pọ̀ èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí sórí ìkànnì jw.org. Ní báyìí, o lè pinnu bóyá kí ìkànnì jw.org ní àwọ̀ funfun tàbí dúdú.

Tó o bá fi sí àwọ̀ dúdú, ó máa sọ àwọ̀ jw.org di dúdú, àwọn ọ̀rọ̀ orí ìkànnì náà á sì di funfun. Àwọn kan nífẹ̀ẹ́ sí àwọ̀ dúdú yìí torí pé kò ní jẹ́ kí iná ojú ẹ̀rọ wọn mọ́lẹ̀ jù. Ìyẹn ò ní jẹ́ kí ojú máa ro wọ́n pàápàá tí wọ́n bá ń wò ó lọ́wọ́ alẹ́ tàbí níbi tó ṣókùnkùn. Apá tuntun yìí tún máa ṣàǹfààní fáwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ ríran dáadáa àtàwọn tí iná máa ń tètè wọ̀ lójú.

Tó o bá fẹ́ rí apá tuntun yìí, lọ sí ọwọ́ ìsàlẹ̀ ìkànnì wà, kó o sì tẹ Appearance Settings.Bí ẹrọ ṣe wà tó o bá fẹ́ kí ìkànnì jw.org máa tẹ̀ lé ìlànà dúdú tàbí funfun tó o ṣe sórí ẹ̀rọ ẹ. O sì lè yan dúdú tàbí funfun tó bá jẹ́ pé bó o ṣe fẹ́ kó máa ṣí nígbà gbogbo nìyẹn.

Apá tuntun yìí kò tíì sí lórí JW Library, àmọ́ a máa fi sí i tó bá yá. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa fi àwọn ohun tuntun kún ìkànnì àtàwọn ètò ìṣiṣẹ́ wa, ìyẹn sì ń jẹ́ ká lè máa rí ọ̀pọ̀ yanturu ẹ̀kọ́ tó dá lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.