Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Puneet Aggarwal, Arákùnrin Delroy Williamson, Arákùnrin Ashok Patel (lápá òkè, láti apá òsì sí ọ̀tún); Arákùnrin Mark Sleger, Arákùnrin Jouni Palmu, Arákùnrin Hiroshi Aoki (lápá ìsàlẹ̀, láti apá òsì sí ọ̀tún)

JULY 10, 2020
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

A Tún Ti Mú Bíbélì Tuntun Mẹ́fà Míì Jáde Bíi ti Òpin Ọ̀sẹ̀ Tó Kọjá

A Tún Ti Mú Bíbélì Tuntun Mẹ́fà Míì Jáde Bíi ti Òpin Ọ̀sẹ̀ Tó Kọjá

Ní July 4 àti July 5, 2020, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú Bíbélì tuntun mẹ́fà jáde, ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá. Ní July 4, 2020, a mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní èdè Bislama àti Oromo. Ní ọjọ́ kejì, ìyẹn July 5, a mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní èdè Latvian àti Marathi, a sì mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì jáde ní èdè Bengali àti Karen (S’gaw) ní ọjọ́ kan náà. Àwọn ará wo àwọn àsọyé tá a ti gbà sílẹ̀, ibẹ̀ sì ni wọ́n ti mú àwọn Bíbélì náà jáde ní ẹ̀dà ti orí ẹ̀rọ. Inú àwọn ará dùn láti rí ẹ̀bùn tẹ̀mí yìí gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà.

Bislama

Arákùnrin Mark Sleger tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Fíjì ló mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe jáde lédè Bislama. Àwọn akéde tó wà ní Vanuatu gbádùn ètò náà lédè Bislama, wọ́n sì tún tú u sí Èdè Adití Lọ́nà ti Bislama.

Ó lé lọ́dún mẹ́ta tí wọ́n fi túmọ̀ Bíbélì náà, àwùjọ atúmọ̀ èdè méjì ló sì tú u. Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè náà sọ pé: “Àwọn ará máa gbádùn Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe yìí gan-an torí àwọn ọ̀rọ̀ tá à ń lò lójoojúmọ́ ló wà nínú rẹ̀, á jẹ́ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ yé wọn dáadáa.”

Ó dá wa lójú pé Bíbélì tá a tún ṣe yìí máa mú kí nǹkan rọrùn fáwọn akéde tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje (700) tó ń sọ èdè Bislama tí wọ́n bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ àti nígbà tí wọ́n bá wà lóde ẹ̀rí.

Oromo

Arákùnrin Delroy Williamson tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Etiópíà ló mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Oromo. Àwọn ará tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlá, ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti méjìdínláàádọ́ta (12,548) ló wo ètò náà lórí ẹ̀rọ, lára wọn sì ni àwọn akéde ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) tó ń sọ èdè Oromo.

Torí bí nǹkan ṣe rí lágbègbè yẹn, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé ká tàtagbà ètò tá a ti gbà sílẹ̀ náà lórí tẹlifíṣọ̀n. Àwọn akéde tún láǹfààní láti gbọ́ ètò náà lórí tẹlifóònù.

Ọdún márùn-ún làwọn atúmọ̀ èdè márùn-ún fi túmọ̀ Bíbélì náà. Bíbélì tuntun yìí máa wúlò fún àwọn ará wa tó ń wàásù fún àwọn tó ń sọ èdè Oromo.

Latvian

Ọdún méjìlá (12) gbáko ni àwọn atúmọ̀ èdè fi ṣiṣẹ́ kára láti túmọ̀ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Latvian. Gbogbo àwọn ará tó ń sọ èdè Latvian àti àwọn tó wà ní ìjọ tó ń sọ èdè Russian lórílẹ̀-èdè Latvia ló wo ètò náà.

Arákùnrin Jouni Palmu tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Finland ló sọ àsọyé tá a fi mú Bíbélì náà jáde. Ó sọ pé: “Inú wa dùn láti mú Bíbélì tó rọrùn kà yìí jáde fún àwọn tó ń sọ èdè Latvian. A nígbàgbọ́ pé á jẹ́ kó rọrùn fáwọn ará láti dá kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì túbọ̀ ronú jinlẹ̀ lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”

Nígbà tí atúmọ̀ èdè kan sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun téèyàn lè fi ṣèwádìí tó wà nínú Bíbélì náà, ó sọ pé: “Bíbélì tuntun yìí á ran àwọn ará lọ́wọ́ láti walẹ̀ jìn, torí ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà nínú ẹ̀, á tún mú kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀ nípa Jèhófà, pàápàá tí wọ́n bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́.”

Marathi

Arákùnrin Puneet Aggarwal tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Íńdíà ló mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní èdè Marathi. Ibi ètò tí wọ́n ṣe fún gbogbo ìjọ tó ń sọ èdè Marathi ní Íńdíà ni wọ́n ti mú Bíbélì náà jáde.

Ọdún mẹ́ta ni àwọn atúmọ̀ èdè mẹ́fà fi parí iṣẹ́ lórí ìtumọ̀ Bíbélì náà. Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè náà sọ pé: “Bíbélì tuntun yìí máa ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn, ó sì tún máa ran àwọn ará lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”

Atúmọ̀ èdè míì sọ pé: “Inú wa dùn, ọkàn wa sì balẹ̀ pé a ti dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sí gbogbo ibi tó wà nínú Bíbélì tí wọ́n kọ níbẹ̀rẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ibi táwọn tó ń ka Bíbélì yìí bá ṣí ni wọ́n á ti rí orúkọ Jèhófà, ìyẹn á sì jẹ́ kí wọ́n fògo fún Jèhófà kí wọ́n sì máa yìn ín.”

Àwọn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́tàlélọ́gọ́rin (83) ló ń sọ èdè Marathi lórílẹ̀-èdè Íńdíà.

Bengali

Arákùnrin Ashok Patel tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Íńdíà ló mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì jáde lédè Bengali. Àwọn akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún méjì (1,200) ló wo ètò náà láti orílẹ̀-èdè Íńdíà àti Bangladesh.

Èdè Bengali wà lára àwọn èdè tí wọ́n ń sọ jù lágbàáyé, òun ló wà nípò keje. Àwọn tó lé ní ọgọ́rùn-ún méjì ààbọ̀ mílíọ̀nù (265,000,000) ló sì ń sọ èdè náà. Kó lè ṣeé ṣe láti mú Bíbélì tó rọrùn lóye jáde fún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń sọ èdè Bengali, àwọn àwùjọ atúmọ̀ èdè láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórílẹ̀-èdè Íńdíà àti Bangladesh lo ọdún mẹ́ta láti túmọ̀ Bíbélì náà.

Arákùnrin Patel sọ pé: “Bengali wà lára àwọn èdè àkọ́kọ́ tí wọ́n túmọ̀ Bíbélì sí lórílẹ̀-èdè Íńdíà. Ọdún 1801 ni wọ́n kọ́kọ́ mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì jáde lédè Bengali. Ohun tó jẹ́ kí Bíbélì yẹn yàtọ̀ ni bí wọ́n ṣe fi orúkọ Jèhófà sí àwọn ibi tó yẹ kó wà. Àmọ́ nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì òde òní, wọ́n ti fi orúkọ oyè náà ‘Olúwa’ rọ́pò orúkọ Jèhófà. Ní ti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tá a tún ṣe yìí, ó rọrùn lóye, ìtumọ̀ ẹ̀ péye, orúkọ Jèhófà sì wà ní gbogbo ibi tó yẹ kó wà.”

Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè náà sọ pé: “Bíbélì tá a túmọ̀ yìí fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn láìka ibi tí wọ́n ti wá sí, ó sì fẹ́ kí gbogbo wa kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun àti Jésù Kristi ọmọ òun.”

Karen (S’gaw)

Arákùnrin Hiroshi Aoki tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Myanmar ló mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì jáde lédè Karen (S’gaw). Àwọn ará tí iye wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé mẹ́wàá (510) láti ìjọ mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti àwùjọ mẹ́rin ló wo ètò náà.

Ó lé díẹ̀ lọ́dún kan táwọn atúmọ̀ èdè Karen (S’gaw) fi parí ìtumọ̀ Bíbélì náà. Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè náà sọ pé: “Àwọn ará àtàwọn èèyàn tó ń sọ èdè Karen (S’gaw) máa gbádùn Bíbélì yìí gan-an torí pé àwọn ọ̀rọ̀ tá à ń lò lójoojúmọ́ la fi túmọ̀ rẹ̀, orúkọ Jèhófà sì tún wà láwọn ibi tó yẹ kó wà. Àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ò lọ́jú pọ̀ rárá, ó péye, ó sì rọrùn lóye. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó fún wa ní ẹ̀bùn àtàtà yìí ní èdè àbínibí wa, ó dájú pé ẹ̀bùn yìí á jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn.”

Atúmọ̀ èdè míì sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ tá à ń lò lóde òní ni wọ́n fi túmọ̀ Bíbélì náà, kó lè ṣeé ṣe fún àwọn tó ń kà á láti mọ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn èèyàn inú Bíbélì, kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n dojú kọ, kíyẹn sì mú kí wọ́n fara wé wọn.”

Inú wa dùn pé àwọn ará wa rí àwọn Bíbélì yìí gbà lédè wọn. Ó dá wa lójú pé àwọn Bíbélì tá a mú jáde yìí máa ran àwọn ará tó ń sọ àwọn èdè yìí lọ́wọ́, kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kó sì wù wọ́n láti máa sọ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn míì.​—Jòhánù 17:17.