Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Mark Sanderson tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Croatian àti Serbian

APRIL 29, 2020
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

A Mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tí A Tún Ṣe Jáde ní Èdè Croatian àti Serbian

A Mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tí A Tún Ṣe Jáde ní Èdè Croatian àti Serbian

Ní April 25, 2020, Arákùnrin Mark Sanderson, tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a tún ṣe jáde lédè Croatian àti Serbian, àwọn ará sì wò ó nínú fídíò tá a ti gbà sílẹ̀. Ọ̀nà ìkọ̀wé Roman àti Cyrillic ni wọ́n fi túmọ̀ Bíbélì èdè Serbian.

Àwọn ará ìjọ Bosnia àti Herzegovina, Croatia, Montenegro àti Serbia ò pàdé pa pọ̀ nígbà tá à ń mú Bíbélì yìí jáde, torí pé wọ́n fẹ́ ṣègbọràn sí òfin tí ìjọba ṣe lórí àjàkálẹ̀ àrùn corona. Kàkà bẹ́ẹ̀, orí íńtánẹ́ẹ̀tì ni wọ́n ti wo fídíò ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà nígbà ìpàdé kan tá a ṣe lákànṣe. Àpapọ̀ àwọn tó jẹ́ 12,705 ni wọ́n sì wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà.

Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ní Croatia àti Serbia ń wo ètò náà lórí kọ̀ǹpútà wọn

Ọ̀kan lára àwọn arákùnrin wa tó wo ètò náà pe Bíbélì tá a tún ṣe yìí ní “ìṣúra tó ṣeyebíye,” ó tún sọ pé “ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà ń bá mi sọ̀rọ̀ lójúkojú.” Arákùnrin míì tó jẹ́ alàgbà sọ pé: “Bí mo ṣe ń ka Bíbélì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ṣe yìí lédè àbínibí mi jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere sí mi pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi gan-an, ó sì ń bójú tó mi. Ní báyìí, tí mo bá fẹ́ fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin nínú ìjọ níṣìírí, mo ti túbọ̀ mọ bí mo ṣe lè jẹ́ kí wọ́n rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, ó sì mọyì wọn.”

Àtọdún 1996 ni iṣẹ́ ìtúmọ̀ yìí ti bẹ̀rẹ̀. Nǹkan bí ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, ìyẹn ní July 1999, a mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtúmọ̀ Ayé Titun jáde lédè Croatian àti Serbian. Lọ́dún 2006, ìyẹn ọdún méje lẹ́yìn náà, a mú Bíbélì Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun jáde láwọn èdè méjèèjì yìí.

Bíbélì tá a tún ṣe lédè Croatian àti Serbian péye, ó sì rọrùn kà. Ó dá wa lójú pé ó máa ran gbogbo àwọn tó bá ń kà á lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí i pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà láàyè.”—Hébérù 4:12.