Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìdílé Oh ní orílẹ̀-èdè Korea ṣe Ìrántí Ikú Kristi pa pọ̀. Àwọn ọmọbìnrin méjì àti bàbá wọn (apá òsì) ṣe Ìrántí Ikú Kristi nínú ilé wọn. Ìyá wọn (apá ọ̀tún) tó ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nílé ìwosàn dara pọ̀ mọ́ wọn nípasẹ̀ ẹrọ fídíò tó ń jẹ́ ká ríra ẹni, ká sì gbọ́ra ẹni.

APRIL 22, 2020
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Ìrántí Ikú Kristi Tá A Ṣé Lọ́dún 2020—Ní Éṣíà

Àwọn Arákùnrin àti Arábìnrin tó Ní Àìlera ní Japan àti South Korea Pésẹ̀ Síbi Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Náà Láìka Ìṣòro Wọn Sí

Ìrántí Ikú Kristi Tá A Ṣé Lọ́dún 2020—Ní Éṣíà

Nítorí àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19, ìpèníjà ńlá ló jẹ́ fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà ní ilé ìwòsàn àti ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó láti pésẹ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọn ò lè jáde kúrò níbi tí wọ́n wà, ẹnì kankan ò sì lè lọ síbẹ̀. Láìka àwọn ìṣòro yìí sí, àwọn alàgbà ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pésẹ̀ síbi ìpàdé tó ṣe pàtàkì jù lọ lọ́dún.

Orílẹ̀-Èdè South Korea

Ní ìlú ńlá Naju, Arábìnrin Lee Jeom-soon, ẹni ọdún mọ́kànléláàádọ́rùn-ún (91) àti Arábìnrin Kwon Ae-soon tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínláàádọ́rùn-ún (88), pẹ̀lú obìnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún (96) pinnu láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ̀kan nínú àwọn dókítà ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó tí wọ́n wà. Lẹ́yìn tó ti ṣe Ìrántí ikú Kristi pẹ̀lú ìjọ ẹ̀, ó pa dà sí ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó náà, ó sí ran àwọn arábìnrin méjì náà àti obìnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ yìí lọ́wọ́ láti wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìrántí ikú Kristi lórí ìkànnì jw.org. Arákùnrin náà tún pèsè àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ.

Ní ìlú ńlá Uijeongbu, Arákùnrin Choi Jae-cheol ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó kan níbi tí àwọn arákùnrin àti arábìnrin àgbàlagbà mẹ́rìnlá (14) ń gbé. Láìka ti àjàkálẹ̀ àrùn yìí sí, arákùnrin wa ran àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó ń gbébẹ̀ àtàwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe Ìrántí Ikú Kristi látorí fídíò. Díẹ̀ lára àwọn olùfìfẹ́hàn tó pésẹ̀ síbẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Arábìnrin Kim Tae-sun tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́ta (59) ń gbé ní ìlú Cheonan. Ní ọdún márùn-ún sẹ́yìn, àyẹ̀wò fi hàn pé Arábìnrin Kim ní àrùn jẹjẹrẹ. Láìpẹ́ yìí, ó di èrò ilé ìwòsàn nítorí ìrora tó pọ̀ sí i tó ń ní. Yàrá ilé ìwòsàn kan náà ni Tae-sun àti arábìnrin míì tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kim Jeong-mi wà. Ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rin (69) ni arábìnrin náà, ó sì ni àrùn jẹjẹrẹ tó le gan-an. Àwọn arábìnrin wa ò lè kúrò nílé ìwòsàn ní àkókò àjàkálẹ̀ àrùn yìí. Àmọ́, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn alàgbà, àwọn arábìnrin méjèèjì ló pésẹ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi, tí wọ́n sì ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ará ìjọ wọn látorí ẹ̀rọ fídíò alátagbà tó ń jẹ́ ká ríra ẹni, ká sì gbọ́ra ẹni.

Àwọn arábìnrin méjèèjì yìí fi ẹ̀mí ìmoore wọn hàn sí àwọn alàgbà nínú lẹ́tà kan tí wọn kọ. Wọ́n sọ pé: “A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún bẹ́ ẹ ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti gbádùn Ìrántí Ikú Kristi, láìka ti àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 àti àìlera wa sí ẹ jẹ́ ká ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tá a jọ ń jọ́sìn Jèhófà”.

Orílẹ̀-Èdè Japan

Arábìnrin Mieko Fujiwara, ẹni àádọ́rin ọdún tó ń gbé ní Ìpínlẹ̀ Mie, lórílẹ̀-èdè Japan, wà nílé ìwòsàn. Torí pé kò sí Íńtánẹ́ẹ̀tì ní ilé ìwòsàn náà, kò ṣeé ṣe fún arábìnrin wa láti ṣe Ìrántí ikú Kristi pẹ̀lú ìjọ ẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀rọ fídíò tó ń jẹ́ ká ríra ẹni, ká sì gbọ́ra ẹni. Àmọ́, ṣáájú ọjọ́ náà ni alàgbà kan àti ìyàwó ẹ̀ ti fi fídíò àsọyé Ìrántí Ikú Kristi tí wọ́n ti ká sílẹ̀ ránṣẹ́ sí orí fóònù arábìnrin náà, èyí tó mú kó ṣeéṣe fún-un láti wo ètò náà láti yàrá ilé ìwòsàn tó wà.

Arábìnrin Yuki Takeuchi tó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rùn-ún (102) ń gbé ní ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó tó wà ni ìlú Zama,Ìpínlẹ̀ Kanagawa. Ní ìmúrasílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi, ọkọ ọmọ ẹ̀ àti ìyàwó ẹ̀ fi àkàrà aláìwú àti wáìnì ránṣẹ́ sí Arábìnrin Takeuchi nínú páálí kékeré kan. Èyí ló mú kó ṣeéṣe fún-un láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi pẹ̀lú ọmọbìnrin ẹ̀ àti ọkọ ọmọ náà, lórí fóònù.

Arákùnrin Mimura, tó jẹ́ ọkọ ọmọ ẹ̀, sọ pé: “Ìyá ìyàwó mi ṣèrìbọmi ní ọdún 1954, kò sì sí Ìrántí Ikú Kristi tí kò ṣe láti ìgbà náà. Inú ẹ̀ dùn gan-an láti ṣe ti ọdún yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣàrà ọ̀tọ̀”.

Ó dá wa lójú pé Jèhófà rí ìsapá àwọn akéde aláìlera wọ̀nyí láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn alàgbà.​—Hébérù 6:10.