JUNE 12, 2020
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Àwọn Ará Wa Lórílẹ̀-Èdè Rùwáńdà àti Sìǹbábúwè Rí Oúnjẹ Gbà Lásìkò Àjàkálẹ̀ Àrùn

Àwọn Ará Wa Lórílẹ̀-Èdè Rùwáńdà àti Sìǹbábúwè Rí Oúnjẹ Gbà Lásìkò Àjàkálẹ̀ Àrùn

Ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Rùwáńdà àti Sìǹbábúwè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà ìjọ, kí wọ́n lè rí i dájú pé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ní àwọn nǹkan tí wọ́n nílò, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àrùn corona ò jẹ́ kí wọ́n lówó lọ́wọ́.

Rùwáńdà

Ní April 2, 2020, Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Rùwáńdà fi ìfilọ̀ kan ránṣẹ́ sáwọn alàgbà ìjọ, wọ́n ní kí wọ́n wá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí àrùn corona tó tàn kálẹ̀ ò jẹ́ kí wọ́n lówó lọ́wọ́, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Torí náà, àwọn alàgbà tó wà káàkiri orílẹ̀-èdè náà bẹ̀rẹ̀ sí í kó oúnjẹ lọ fáwọn ará ọ̀hún, wọ́n tún fún wọn láwọn nǹkan míì tí wọ́n nílò.

Lẹ́yìn nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì, ẹ̀ka ọ́fíìsì Rùwáńdà ti dá ìgbìmọ̀ mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31) tó ń pèsè ìrànwọ́ nígbà àjálù sílẹ̀. Ìgbìmọ̀ yìí pín oríṣiríṣi oúnjẹ fáwọn ìdílé tí kò lóúnjẹ, wọ́n pín àgbàdo lílọ̀, ìrẹsì, ẹ̀wà, iyọ̀, ṣúgà àti òróró. Ní báyìí, ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ìdílé tó ti jàǹfààní ètò yìí.

Lẹ́yìn tí Arábìnrin Nizeyimana Charlote rí oúnjẹ gbà, òun àtàwọn ọmọ ẹ̀ mẹ́ta sọ pé: “Ẹ ṣeun gan-an tẹ́ ẹ̀ ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tù wá nínú, tẹ́ ẹ tún fún wa ní oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì tá a nílò lásìkò tí àjàkálẹ̀ àrùn corona mú kí nǹkan le koko yìí. A ò mọ bá a tún ṣe lè dúpẹ́ lọ́wọ́ yín, ẹ ṣé gan-an ni.”

Arákùnrin kan sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ tí wọ́n sọ fún un pé ìdílé ẹ̀ máa rí oúnjẹ gbà. Ó ní: “Lọ́jọ́ yẹn, ìyàwó mi dákú torí pé kò rí oúnjẹ jẹ. Àmọ́, ṣàdédé ni arákùnrin kan pè mí lórí fóònù, ó sì sọ bí mo ṣe máa gba oúnjẹ tó kan ìdílé mi. Ó yà mí lẹ́nu gan-an ni. Tílẹ̀ ọjọ́ kejì fi mọ́, ṣe ni mò ń gbàdúrà sí Jèhófà, tí mo sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.”

Sìǹbábúwè

Àrùn corona tó ń jà ràn-ìn ti jẹ́ kí ìṣòro àìtó oúnjẹ tó wà lórílẹ̀-èdè yìí túbọ̀ peléke sí i.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Sìǹbábúwè yan ìgbìmọ̀ márùn-ún tó ń pèsè ìrànwọ́ nígbà àjálù, kí wọ́n lè bójú tó ètò ìrànwọ́ lórílẹ̀-èdè náà. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣètò bí àwọn akéde ṣe máa fi oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì ṣètìlẹyìn fáwọn ará tó ṣaláìní. Ohun táwọn akéde yẹn fi ṣètìlẹyìn ni ìgbìmọ̀ náà ń pín fáwọn ará.

Títí di báyìí, ìgbimọ̀ yìí ti pín àgbàdo tó tó kìlógíráàmù 62,669, wọ́n tún pín 6,269 lítà òróró, 3,337 kìlógíráàmù ẹja gbígbẹ àti 5,139 kìlógíráàmù ẹ̀wà fún àwọn akéde tó jẹ́ 7,319.

Tọkọtaya kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó sì ń wá sáwọn ìpàdé wa déédéé nílò oúnjẹ. Inú wọn dùn gan-an nígbà tí ẹni tó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó oúnjẹ wá fún wọn. Lọ́jọ́ tó ṣáájú ọjọ́ yẹn, pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ń lọ tẹ́lẹ̀ pè wọ́n, ó sì sọ pé kí wọ́n fi ọrẹ wọn ránṣẹ́, kí òun àti ìyàwó òun lè rówó ra oúnjẹ sílé. Bí tọkọtaya náà ṣe wá rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sí pásítọ̀ yẹn, wọ́n pinnu láti kọ̀wé fi ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀.

Ó dá wa lójú pé Jèhófà á máa pèsè ohun táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lórílẹ̀-èdè Rùwáńdà àti Sìǹbábúwè nílò.​—Ìṣe 11:29.