Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

APRIL 30, 2020
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Àwọn Ará Wa Kárí Ayé Ń Pèsè Ìtùnú fún Àwọn Tí Èèyàn Wọn Kú Nínú Àjàkálẹ̀ Àrùn Yìí

Àwọn Ará Wa Kárí Ayé Ń Pèsè Ìtùnú fún Àwọn Tí Èèyàn Wọn Kú Nínú Àjàkálẹ̀ Àrùn Yìí

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa èèyàn Jèhófà ń ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti dáàbò bo ara wa lákòókò àjàkálẹ̀ àrùn tó gbòde kan yìí, síbẹ̀ àrùn yìí ti mú ẹ̀mí àwọn ará wa kan lọ. (Oníwàásù 9:11) Ó bani nínú jẹ́ pé, lásìkò tá à ń kọ ìròyìn yìí, ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti méjìléláàádọ́rin (872) àwọn ará wa ni àrùn Corona ti pa yíká ayé. Àwọn ará wa sì ti pèsè ìrànwọ́ àti ìtùnú láìjáfara fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀. (1 Kọ́ríńtì 12:26) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, àwọn ará wa túbọ̀ gbára lé Jèhófà, ẹni tó ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ bó ṣe wà nínú Fílípì 4:7 pé òun máa fún wa ní “àlàáfíà Ọlọ́run.”

Arákùnrin àti Arábìnrin Unnützer

Ọ̀kan lára àwọn ará wa tó rí ìtìlẹ́yìn ètò Jèhófà ni Arábìnrin Hannchen Unnützer tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nílùú Bolzano, ní apá àríwá orílẹ̀-èdè Ítálì. Ó bani nínú jẹ́ pé, ọkọ rẹ̀, Arákùnrin Manfred Unnützer, kú ní March 28, 2020, nítorí àrùn Corona. Arákùnrin Unnützer sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún méjìdínlọ́gọ́ta (58), òun àti ìyàwó rẹ̀ sì ti jọ ń ṣiṣẹ́ náà fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta (54). Àwọn méjèèjì lo ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) pa pọ̀ nínú iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí iye wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún kan (1,000) láti onírúurú orílẹ̀-èdè ló dara pọ̀ mọ́ wọn níbi ètò ìsìnkú náà lórí fídíò alátagbà orí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

Arábìnrin Unnützer sọ pé: “Mo mọrírì àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi gan-an. Wọn ò fi mí sílẹ̀ nígbà kankan, kódà fún wákàtí kan. Ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí mi kọyọyọ! Wọ́n tọ́jú mi nípa tara àti nípa tẹ̀mí, wọ́n sì tù mí nínú. Mo nífẹ̀ẹ́ gbogbo wọn.”

Tọkọtaya míì tó tún rí ìrànlọ́wọ́ gbà nígbà tí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ ni Maria Jose Moncada àti Darwin, ọkọ rẹ̀. Wọ́n ń sìn ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń sọ èdè Quichua ní àwọn orí-òkè Ecuador. Ó bani nínú jẹ́ pé, àrùn yìí pa àwọn òbí Arábìnrin Moncada, ìyẹn Arábìnrin Fabiola Santana Jordan, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (56), tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé, àti Arákùnrin Ricardo Jordan, ẹni ọgọ́ta ọdún (60), tó jẹ́ ìráńṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ nínú ìjọ Praderas nílùú Guayaquil. Àwọn méjèèjì kú láàárín ọjọ́ mẹ́fà síra. Àrùn COVID-19 tún dá àwọn arákùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá Arábìnrin Moncada dùbúlẹ̀, àmọ́ ara wọn ti yá.

Arákùnrin àti Arábìnrin Moncada níbi Ìrántí Ikú Kristi

Ẹ̀dùn ọkàn tó bá Arábìnrin Moncada pọ̀ gan-an, ó sì fẹ́ rìnrìn àjò wákàtí mẹ́rin, kó lè wà pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, láti bá wọn kẹ́dùn, kí wọ́n sì jọ ṣètò ìsìnkú náà. Àmọ́, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ àdúrà, wọ́n pinnu pé kò ní bọ́gbọ́n mu láti rìnrìn àjò náà lọ sí ìlú Guayaquil. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n jọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí wọn lórí fídíò alátagbà orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Arábìnrin Moncada sọ pé: “Ká ní a lọ síbi ìsìnkú yẹn láti wà pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí wa, à bá fi ìlera tiwa àti tàwọn míì sínú ewu.”

Arábìnrin Moncada sọ pé òun ‘ṣàníyàn, ẹ̀dùn ọkàn sì bá òun gan-an.’ Àmọ́, òun àti ọkọ ẹ̀ ń bá ìjọsìn wọn sí Jèhófà lọ láì dáwọ́ dúró, wọn ò sì “yéé gbàdúrà sí Jèhófà nígbà gbogbo pé kó tọ́ àwọn sọ́nà.” Láti múra Ìrántí Ikú Kristi sílẹ̀, ìdílé Moncada pe àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ka àwọn apá Bíbélì tó sọ nípa bí Jésù ṣe parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n tún lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù nípa kíkọ lẹ́tà, wọ́n sì ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn ará ìjọ wọn lórí fídíò alátagbà orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Mẹ́sàn-án nínú àwọn mọ̀lẹ́bí Arábìnrin Moncada tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló gba ìkésíni tó fún wọn láti dara pọ̀ mọ́ Ìrántí Ikú Kristi tí wọ́n máa ṣe látorí ẹ̀rọ lédè Sípáníìṣì.

Arábìnrin Moncada sọ pé: “Inú wa dùn láti rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa tí nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún, àmọ́ tí wọ́n ṣètò láti wà pẹ̀lú wa lórí ẹ̀rọ alátagbà, kí wọ́n lè gbádùn àsọyé Ìrántí Ikú Kristi. Ó tún yà mí lẹ́nu gan-an láti rí àwọn mọ̀lẹ́bí mi tí wọ́n ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè míì, tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ wa lórí ẹ̀rọ alátagbà náà.”

Arábìnrin Moncada tún sọ pé: “Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa gan-an, àmọ́ ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé, béèyàn bá tẹra mọ́ ìjọsìn Jèhófà, ó máa lè borí ẹ̀dùn ọkàn èyíkéyìí, á sì tipa bẹ́ẹ̀ rí ìbùkún Jèhófà gbà.”

Àwọn ará wa kárí ayé ń ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ti pàdánù àwọn èèyàn wọn nínú ikú lákòókò àjàkálẹ̀ àrùn yìí, a ó sì máa báa lọ láti gbàdúrà fún wọn. À ń retí ọjọ́ tí Jèhófà máa mú òpin dé bá gbogbo ohun tó ń fa ìrora, irú bí àjàkálẹ̀ àrùn, tó sì máa jí àwọn ìráńṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tó ti kú dìde.​—1 Kọ́ríńtì 15:21, 22.