Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 3, 2020
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Àpéjọ Ọdún 2020​—⁠Àpéjọ Àkọ́kọ́ Tá A Gbélé Wò Kárí Ayé

Àpéjọ Ọdún 2020​—⁠Àpéjọ Àkọ́kọ́ Tá A Gbélé Wò Kárí Ayé

Ní oṣù July àti August ọdún 2020, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin, títí kan àwọn olùfìfẹ́hàn, ni wọ́n para pọ̀ wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ ọdún 2020.

Ètò ti wà nílẹ̀ pé ká ṣe Àpéjọ “Ẹ Máa Yọ̀ Nígbà Gbogbo”! tí gbogbo wa ti ń fojú sọ́nà fún yìí láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ, gbọ̀ngàn ìṣeré, àwọn gbọ̀ngàn míì tá a háyà, àtàwọn pápá ìṣeré, ní igba ó lé ogójì [240] ilẹ̀. Ṣùgbọ́n torí àtidáàbò bo ìlera àwọn tó máa pésẹ̀ sí àpéjọ náà, Ìgbìmọ̀ Olùdarí pinnu pé kí gbogbo wa kárí ayé wo ìpàdé kan ṣoṣo nínú ilé wa, dípò ká kóra jọ síbì kan. Láti ọdún 1897 tí ètò Ọlọ́run ti ń ṣe àpéjọ, èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí a ò ṣe àpéjọ ní àwọn gbọ̀ngàn tá a máa ń lò.

Ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí, Kenneth Cook, Jr., sọ pé: “Nígbà tí a wọ́gi lé àpéjọ agbègbè yẹn, ṣe la ní in lọ́kàn pé ká kúkú ṣe ìpàdé kan ṣoṣo táwọn èèyàn níbi gbogbo kárí ayé á wò láàárín àsìkò kan náà. A mọ̀ pé ó máa pọn dandan ká túmọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè kí oṣù mẹ́rin tó pé. Irú ìtumọ̀ bẹ́ẹ̀ sábà máa ń gbà tó ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kó tó parí. Ní July 6, ọdún 2020, inú wa dùn gan-an pé apá àkọ́kọ́ lára àpéjọ náà jáde ní nǹkan bí irinwó [400] èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. A ṣì retí pé gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ṣì máa tó èdè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta-lé-mọ́kànlá [511]!”

Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn arábìnrin wa tó ń dá tọ́ ọmọ mẹ́ta ń ṣàlàyé àǹfààní tó wà nínú àpéjọ agbègbè tá a gbélé wò náà, ó ní: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò kóra jọpọ̀ síbì kan pẹ̀lú àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin, àwọn ọmọ mi gbádùn ẹ̀ gan-an ni. Bí apá kọ̀ọ̀kan àpéjọ náà kò ṣe fi bẹ́ẹ̀ gùn mú kí wọ́n túbọ̀ pọkàn pọ̀. Bí wọ́n bá fẹ́ sinmi, a lè dá a dúró díẹ̀. Gbogbo ẹ̀ la jọ wò látìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Friday fi àwọn ọmọ wa wé ọfà, ó sì jẹ́ kó ṣe kedere pé béèyàn ò bá ní àfojúsùn tó dáa, ọfà ò ní balẹ̀ síbi tá a fẹ́ kó lọ. Lọ́nà kan náà, a gbọ́dọ̀ ní àfojúsùn tó dáa káwọn ọmọ lè láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Bá a ṣe gbélé wo àpéjọ náà ti ń ràn mí lọ́wọ́ kí n lè ní irú àfojúsùn bẹ́ẹ̀.”​—Sáàmù 127:4.

Àpéjọ agbègbè mánigbàgbé tá a gbélé wò náà gbàfiyèsí àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn kárí ayé. Bí àpẹẹrẹ, Robert Hendriks, tó ń bójú tó iṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Gbéròyìn Jáde lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ọ̀pọ̀ akọ̀ròyìn ló kọ àpilẹ̀kọ nípa àpéjọ tá a gbélé wò náà. Wọ́n ṣàlàyé bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe lo ẹ̀rọ ìgbàlódé láti ṣe àpejọ́ náà tá a sì tún fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ààbò.”

Àpéjọ “Ẹ Máa Yọ̀ Nígbà Gbogbo”! ti ọdún 2020 ti mú ká rí ọ̀nà míì tó gbádùn mọ́ni tí Jèhófà gbà jẹ́ Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá.​—Àìsáyà 30:20.