Ìròyìn Kárí Ayé
Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2025 #2
Nínú ìròyìn yìí, a sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tá à ń ṣe ká lè kọ́ àwọn ará kí wọ́n lè kàwé dáadáa, àti bí ẹbọ ìràpadà Jésù ṣe mú kí ọkàn wa balẹ̀. A tún sọ̀rọ̀ nípa orin tuntun tá a máa kọ ní àpéjọ agbègbè tọdún 2025.
Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2025 #1
Nínú ìròyìn yìí, a máa rí bá a ṣe lè lo apá “Ohun Tá À Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn” tó wà ní àfikún A nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn. Apá yìí máa jẹ́ ká lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lóde ìwàásù, ká sì gbádùn ẹ̀.
Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2024 #8
Nínú ìròyìn yìí, àá sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sí àwọn tó bá kópa nínú àwọn fídíò wa.
Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2024 #7
Nínú ìròyìn yìí, a máa gbọ́ nípa bí nǹkan ṣe ń lọ fáwọn ará wa kárí ayé, àá sì gbọ́rọ̀ lẹ́nu Arákùnrin Jody Jedele àti Arákùnrin Jacob Rumph tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí.
Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2024 #6
Nínú ìròyìn yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí kò fi yẹ ká ṣíwọ́ àtimáa bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2024 #5
Nínú ìròyìn yìí, a máa rí ohun tá a lè ṣe táá mú ká túbọ̀ fọkàn sí i pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè yanjú ìṣòro aráyé.
Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2024 #4
Nínú ìròyìn yìí, a máa rí báwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ṣe ń “fi ire ṣẹ́gun ibi.”—Róòmù 12:21.
Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2024 #3
Nínú ìròyìn yìí, a máa jíròrò àwọn ìlànà Bíbélì tó máa jẹ́ ká lè ṣèpinnu tó dáa tó bá dọ̀rọ̀ ìmúra wa.
Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2024 #2
Nínú ìròyìn yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà Baba wa onífẹ̀ẹ́ ṣe fi hàn pé òun “fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.” (2 Pét. 3:9) Àá tún rí àtúnṣe tá a ṣe nípa ọ̀nà tá a lè gbà múra tá a bá ń lọ sáwọn ìpàdé àti àpéjọ.
Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2024 #1
Wàá rí bí ìfẹ́ tá a ní sáwọn èèyàn ṣe máa jẹ́ ká túbọ̀ nítara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.
Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2023 #2
Ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ṣe ń lọ sí fáwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Türkiye, ó sì tún fọ̀rọ̀ wá àwọn arákùnrin kan lẹ́nu wò.
Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2023 #1
A fẹ́ kẹ́ ẹ wo fídíò yìí kẹ́ ẹ lè gbọ́ àwọn ìròyìn amóríyá nípa iṣẹ́ ìkọ́lé Ramapo àti iṣẹ́ ìwàásù àwọn aṣáájú-ọ̀nà.
Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2022 #7
Ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí gbà wá níyànjú pé ká má ṣe máa fi nǹkan falẹ̀ nígbà tí ewu bá ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lágbègbè wà.
Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2022 #6
Ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó sì jẹ́ ká mọ ohun tó máa jẹ́ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2023.
Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2022 #5
Ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí jẹ́ ká mọ ohun tó ran àwọn ará wa tó wà ní Soviet Union lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin láìka inúnibíni tí wọ́n dojú kọ sí, wọ́n sì jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà á máa tì wá lẹ́yìn.