OCTOBER 19, 2016
ERITREA

Ìgbà Àkọ́kọ́ Rèé tí Ìyà Tó Ń Jẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Eritrea Máa Dé Etí Iléeṣẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ Lágbàáyé

Ìgbà Àkọ́kọ́ Rèé tí Ìyà Tó Ń Jẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Eritrea Máa Dé Etí Iléeṣẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ Lágbàáyé

Ní gbogbo ayé yìí, orílẹ̀-èdè Eritrea làwọn aláṣẹ ti ń fúngun mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jù. Àtìgbà tí Eritrea ti gbòmìnira lọ́dún 1993 ni wọ́n ti ń fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n léraléra, tí wọ́n ń fìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n sì ń fọwọ́ rọ́ wọn sẹ́yìn láwùjọ. Bẹ́ẹ̀, torí pé wọn ò dá sí òṣèlú, tí wọ́n sì kọ̀ láti gbé nǹkan ìjà láti pa ẹnì kejì wọn ni wọ́n ṣe ń fínná mọ́ wọn.

Mẹ́rìnlélàádọ́ta [54] làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lẹ́wọ̀n lọ́wọ́lọ́wọ́ ní Eritrea. Láti ohun tó lé ní ọdún méjìlélógún [22] sẹ́yìn, àwọn aláṣẹ kì í jẹ́ kí gbogbo àwọn tí wọ́n ń fi sẹ́wọ̀n kọ́kọ́ fojú ba ilé ẹjọ́, débi pé wọ́n á gbọ́ ẹjọ́ wọn. Àwọn mẹ́ta ló ti wà lẹ́wọ̀n látọdún 1994.

Kárí Ayé Ni Àwọn tí Kò Fara Mọ́ Ọn Ti Ń Pọ̀ Sí I

Àtìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í fúngun mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn iléeṣẹ́ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àtàwọn iléeṣẹ́ ìjọba ò ti fara mọ́ ìyà táwọn aláṣẹ fi ń jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí lórílẹ̀-èdè Eritrea. Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Àjọ Tó Ń Ṣèwádìí Lórí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní Eritrea (ìyẹn àjọ COIE), tó ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè, ti fi ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ìjọba àpapọ̀ létí. Ìgbà àkọ́kọ́ tírú ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ nìyí. Nígbà tí àjọ náà kọ́kọ́ ń jábọ̀ fún Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè (ìyẹn àjọ HRC) ní June 2015, àjọ COIE dìídì ya apá kan sọ́tọ̀ nínú ìwé tí wọ́n kọ láti fi ṣàlàyé bí àwọn èèyàn ṣe ń ṣẹ̀tanú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n sì ń fìyà jẹ wọ́n.

Ní June 21, 2016, àjọ COIE tún jábọ̀ tó kún rẹ́rẹ́ fún àjọ HRC. Àjọ COIE rọ ìjọba orílẹ̀-èdè Eritrea pé kí wọ́n “gbà pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n, kí wọ́n sì gba ohun tó wù wọ́n gbọ́” àti pé kí wọ́n “jáwọ́ nínú bí wọ́n ṣe ń mú àwọn èèyàn láìnídìí, tí wọ́n sì ń tì wọ́n mọ́lé lórí ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn wọn, pàápàá àwọn ẹlẹ́sìn kan, bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, . . . kí wọ́n sì dá gbogbo àwọn tí wọ́n mú láìbófin mu sílẹ̀ àtàwọn tí wọ́n tì mọ́lé láìnídìí, láìsí pé wọ́n ń béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ wọn tàbí kí wọ́n ní káwọn èèyàn yìí ṣe nǹkan kan kí wọ́n tó lè dá wọn sílẹ̀.”

Ibi tí àjọ COIE parí èrò sí lórí ìwádìí tí wọ́n ṣe ni pé, kéèyàn máa “fúngun mọ́ àwọn èèyàn lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn àti àṣà ìbílẹ̀” ta ko òfin táwọn orílẹ̀-èdè ń tẹ̀ lé kárí ayé, “ìwà ìkà gbáà” sì ni. Kárí ayé, ìjọba àpapọ̀ gbà pé ṣe ni ẹni tó bá hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ ń tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú lọ́nà tó bùáyà. Àjọ COIE máa tún jábọ̀ ibi tọ́rọ̀ náà dé níbi ìpàdé táwọn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè máa ṣe ní October 27, 2016.

Ṣé Ìjọba Orílẹ̀-èdè Eritrea Máa Wá Nǹkan Ṣe sí Bó Ṣe Ń Fìyà Jẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Láìtọ́ Yìí?

Kárí ayé ni inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò ti dùn sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọ́n ní Eritrea. Taratara ni wọ́n ń bẹ ìjọba orílẹ̀-èdè Eritrea pé kí wọ́n yéé fúngun mọ́ àwọn Kristẹni olóòótọ́ yìí, kí wọ́n sì fi wọ́n lọ́rùn sílẹ̀ kí wọ́n lè gbádùn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tí wọ́n ní lábẹ́ òfin.