Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 30, 2019
ERITREA

ÀKÀNṢE ÌRÒYÌN: Wọ́n Ń Ṣenúnibíni Sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórílẹ̀-Èdè Eritrea

ÀKÀNṢE ÌRÒYÌN: Wọ́n Ń Ṣenúnibíni Sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórílẹ̀-Èdè Eritrea

Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde tó jẹ́ ẹ̀ka tó ń rí sí bá a ṣe ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ àti bá a ṣe ń fèròwérò pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ló gbé àkànṣe ìròyìn yìí jáde lóṣù August 2019. Ìròyìn náà dá lórí bí ìjọba orílẹ̀-èdè Eritrea ṣe ń ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Wà á jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì

Ní August 2019, Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìléláàádọ́ta (52) ló wà lẹ́wọ̀n lórílẹ̀-èdè Eritrea. Ìwé yìí á jẹ́ kó o mọ ìsọfúnni ṣókí nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn Ẹlẹ́rìí náà.

Wà á jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì

Ní April 28, 2018, àjọ African Commission on Human and Peoples’ Rights (ACHPR) ṣàyẹ̀wò bí ìjọba orílẹ̀-èdè Eritrea ṣe ń fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè náà. Ìwé tó wà nísàlẹ̀ yìí ṣàkópọ̀ ibi tí àjọ náà fẹnu kò sí lẹ́yìn àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe lórí ohun tí ìjọba orílẹ̀-èdè yẹn ń ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. October 24 2018 sí November 13, 2018 ni wọ́n ṣe ìpàdé tí wọ́n ti fẹnu kò lórí ọ̀rọ̀ náà.

Wà á jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì