Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Paulos Eyasu, Isaac Mogos àti Negede Teklemariam nìyí. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti wà lẹ́wọ̀n ní Eritrea láti September 17, 1994

SEPTEMBER 17, 2019
ERITREA

Wọ́n Ti Lo Ọdún Mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) Lọ́gbà Ẹ̀wọ̀n ní Eritrea

Wọ́n Ti Lo Ọdún Mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) Lọ́gbà Ẹ̀wọ̀n ní Eritrea

Orílẹ̀-èdè Eritrea jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ibi tí wọ́n ti ń ṣe inúnibíni tó gbóná janjan sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Ní September 17, 2019, àwọn arákùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, Paulos Eyasu, Isaac Mogos, àti Negede Teklemariam ti wà lẹ́wọ̀n fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Láfikún sí i, àwọn arákùnrin wa mọ́kàndínlógójì (39) àtàwọn arábìnrin mẹ́wàá míì ní wọn ti jù sẹ́wọ̀n.

Gbogbo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n báyìí ni ìjọba ilẹ̀ náà kò gbọ́rọ̀ wọn lọ ilé ẹjọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ilé ẹjọ́ kankan ò dá wọn lẹ́bi. Wọn ò mọ ìgbà tí wọ́n máa dá wọn sílẹ̀. Àwọn arákùnrin mẹ́rin ló ti kù sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n, nígbà tí àwọn mẹ́tà míì kú lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, torí ìyà tí wọ́n fi jẹ wọ́n nígbà tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n.

Inúnibíni ní Eritrea bẹ̀rẹ̀ sí gbóná sì i ní October 25, 1994 tó jẹ́ nǹkan bí ọdún kan ààbọ̀ lẹ́yìn tí orílẹ̀ èdè Eritrea gbòmìnira lọwọ́ orílẹ̀ èdè Ethiopia. Ààrẹ orílẹ̀ èdè tuntun níbẹ̀ sọ pé gbogbo àwọn ọmọ ìbílẹ̀ orílẹ̀ èdè Eritrea tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní wọn kìí ṣe ọmọ ìbílẹ̀ orílẹ̀ èdè náà mọ́, kìkì ní torí pé, wọ́n dúró láìyẹsẹ̀ lórí ìpinnu wọn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni láti má ṣe dá sí tọ̀tún tòsì. Ààrẹ náà tún fi àwọn ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní dù wọ́n. Lára àwọn ẹ̀tọ́ tí wọ́n tún fi dù wọ́n ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò lè lọ sílé ìwé, wọn ò lè dá okòwò tiwọn sílẹ̀ tàbí rìnrìn àjò kúrò lórílẹ̀ èdè náà.

Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn tó lórúkọ láwùjọ ti sọ léraléra pé ó ń ká àwọn lára bí ìjọba orílẹ̀ èdè Eritrea ṣe fọwọ́ rọ́ ìlànà nípa ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lágbàáyé sẹ́yìn tí wọ́n sì ń fojú àwọn Ẹlẹ́rìí gbolẹ̀. Ìjọba orílẹ̀-èdè Eritrea ti kọ̀ jálẹ̀ láti tẹ̀ lé ohun tí àwọn àjọ yìí sọ..

Wo: “ÀKÀNṢE ÌRÒYÌN: Wọ́n Ń Ṣenúnibíni Sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórílẹ̀-Èdè Eritrea

Àá máa bá a lọ láti máa sọ fún àwọn aláṣẹ ìjọba àtàwọn míì tó wà nípò àṣẹ nípa bí nǹkan ṣe rí ní Eritrea. Bí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ṣe ń fi ìgbàgbọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ àti ìgboyà hàn lójú inúnibíni tó gbóná janjan yìí, a ń wojú Jèhófà pẹ̀lú ìdánilójú pé ó máa jẹ́ Olùrànlọ́wọ́ àti “àpáta ààbò” fún wọn.—Sáàmù 94:22.