Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 15, 2018
ÀMÉNÍÀ

Bó Ṣe Di Pé Ìjọba Àméníà Fọwọ́ sí I Pé Èèyàn Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Sọ Pé Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kóun Ṣiṣẹ́ Ológun

Bó Ṣe Di Pé Ìjọba Àméníà Fọwọ́ sí I Pé Èèyàn Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Sọ Pé Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kóun Ṣiṣẹ́ Ológun

Ẹjọ́ kan tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ìyẹn ilé ẹjọ́ ECHR) dá lẹ́nu àìpẹ́ yìí jẹ́ kí ẹ̀tọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun túbọ̀ fìdí múlẹ̀ lábẹ́ òfin. Ní October 12, 2017, ilé ẹjọ́ ECHR fi ìpinnu tí wọ́n ṣe lórí ẹjọ́ Adyan and Others v. Armenia ṣe àpẹẹrẹ irú iṣẹ́ àṣesìnlú tó yẹ kí wọ́n ṣètò fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin yìí.

Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi jẹ́ pé Ilé Ẹjọ́ ECHR ò fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ póun ò ṣiṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò bá jẹ́ kó ṣe é, èyí sì mú kí wọ́n ṣenúnibíni sí ọ̀pọ̀ èèyàn, kí wọ́n sì rán wọn lọ sẹ́wọ̀n. Àmọ́ àtọdún 2011 ni Ilé Ẹjọ́ náà ti tún èrò wọn pa, nígbà tí wọ́n ṣèpinnu tó yàtọ̀ lórí ẹjọ́ Bayatyan v. Armenia, pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin láti sọ pé òun ò wọṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kó ṣe é. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí tí wọ́n wá dá ẹjọ́ Ọ̀gbẹ́ni Adyan, Ilé Ẹjọ́ ECHR pinnu pé àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣiṣẹ́ àṣesìnlú. Ṣe niṣẹ́ náà gbọ́dọ̀ jẹ́ irú èyí tó máa jẹ́ kí wọ́n lè ran ìlú lọ́wọ́, kì í ṣe pé wọ́n á fi máa jẹ wọ́n níyà.

Àlàyé ṣókí nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun lórílẹ̀-èdè Àméníà jẹ́ ká rí i bí àwọn ẹjọ́ tí ECHR dá lórí ọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Bayatyan, Ọ̀gbẹ́ni Adyan àtàwọn míì ṣe nípa pàtàkì lórí ọwọ́ tí ìjọba fi ń mú àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

Ìjọba Àménìa Ṣèlérí Pé Àwọn Máa Ṣètò Iṣẹ́ Àṣesìnlú, àmọ́ Wọn Ò Ṣe É

Kò sí àfidípò, àfi kí wọ́n jìyà. Nígbà tí Àméníà wọnú Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù lọ́dún 2001, wọ́n ṣèlérí pé àwọn máa ṣòfin tó fọwọ́ sí iṣẹ́ àṣesìnlú bó ṣe wà nínú àwọn ìlànà ìjọba ilẹ̀ Yúróòpù. Iṣẹ́ àṣesìnlú yìí kò ní ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ ológun, kì í sì í ṣe iṣẹ́ tí wọ́n á fi máa fìyà jẹ àwọn tó ń ṣe é. Ìjọba tún sọ pé àwọn ò ní máa fìyà jẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. * Àmọ́ ìjọba orílẹ̀-èdè Àméníà ò tíì ṣe ohun tí wọ́n láwọn máa ṣe tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí Vahan Bayatyan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kó wá wọṣẹ́ ológun, bẹ́ẹ̀ ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ kò gbà á láyè láti wọṣẹ́ ológun. Nígbà tó di 2002, ilé ẹjọ́ dá a lẹ́bi, wọ́n sì rán an lọ sẹ́wọ̀n torí pé ó lóun ò ṣiṣẹ́ ológun, ìjọba ò sì ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú gẹ́gẹ́ bí àfidípò. Lọ́dún 2003, Ọ̀gbẹ́ni Bayatyan kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ ECHR pé bí ìjọba orílẹ̀-èdè Àméníà ṣe fi òun sẹ́wọ̀n yìí fi hàn pé wọ́n tẹ ẹ̀tọ́ tóun ní láti lómìnira ẹ̀rí ọkàn àti ẹ̀sìn lójú.

Wọn ò ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú dáadáa, wọ́n tún wá fìyà jẹ wọ́n. Lọ́dún 2004, ìjọba Àméníà ṣòfin lórí iṣẹ́ àṣesìnlú, àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì gbà láti ṣe é dípò kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Àmọ, gbàrà tí wọ́n forúkọ sílẹ̀ ni wọ́n rí i pé àwọn ológun láá máa bójú tó iṣẹ́ náà, kì í ṣe àwọn aláṣẹ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìlú. Ni wọ́n bá fi tó ìjọba létí, wọ́n sì fiṣẹ́ náà sílẹ̀. Torí ohun tí wọ́n ṣe yẹn, wọ́n mú wọn, wọ́n fojú ba ilé ẹjọ́, wọ́n sì rán àwọn kan lọ sẹ́wọ̀n. Ní May 2006, Hayk Khachatryan àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìdínlógún (18) míì tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ ECHR, wọ́n sọ pé bí wọ́n ṣe pe àwọn lẹ́jọ́ láìtọ́ yìí fi hàn pé wọ́n ti fi ẹ̀tọ́ àwọn du àwọn. *

Ibi pẹlẹbẹ lọ̀be ń fi lélẹ̀ fọ́pọ̀ ọdún. Ọ̀pọ̀ ọdún ni ìjọba Àméníà ò fi ṣàtúnṣe sí òfin iṣẹ́ àṣesìnlú tí wọ́n ṣe. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò fìgbà kan fara mọ́ ètò iṣẹ́ àṣesìnlú tí ìjọba láwọn ṣe, ìjọba ò sì yéé fi wọ́n sẹ́wọ̀n. Láàárín ọdún 2004 (tí wọ́n ṣe òfin iṣẹ́ àṣesìnlú) sí ọdún 2013 (tí wọ́n tún òfin náà ṣe), ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mẹ́tàdínlógún (317) làwọn tí wọ́n dá lẹ́bi, ẹ̀wọ̀n ọdún méjì sí mẹ́ta ni wọ́n sì máa ń sọ pé kí wọ́n fi gbára.

Láàárín àkókò yìí, Ilé Ẹjọ́ ECHR ò fi bẹ́ẹ̀ rí nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà. Lọ́dún 2009, wọ́n gbọ́ ẹjọ́ Ọ̀gbẹ́ni Bayatyan, tó sọ pé bóun ṣe lóun ò ṣiṣẹ́ ológun bá ohun tó wà nínú Àpilẹ̀kọ 9 nínú ìwé àdéhùn European Convention mu. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ sí òmìnira ẹ̀rí ọkàn àti ẹ̀sìn. Àmọ́ Ilé Ẹjọ́ ECHR ò paṣọ èṣí dà. Ohun tí wọ́n máa ń sọ tẹ́lẹ̀ náà ni wọ́n tẹnu mọ́. Wọ́n ní ìjọba orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ló máa kọ́kọ́ pinnu bóyá àwọn máa fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ póun ò ṣiṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀rí ọkàn. Tí ìjọba orílẹ̀-èdè kan ò bá ti fọwọ́ sí i, a jẹ́ pé ẹnikẹ́ni tó bá lóun ò wọṣẹ́ ológun ò lè fi Àpilẹ̀kọ 9 gbèjà ara ẹ̀ nìyẹn. Torí pé ìpinnu yìí yàtọ̀ sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé lórí ọ̀rọ̀ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, àwọn agbẹjọ́rò Ọ̀gbẹ́ni Bayatyan kọ̀wé pé kí wọ́n gbé ẹjọ́ rẹ̀ lọ sí Ìgbìmọ̀ Tó Ga Jù Lọ nínú Ilé Ẹjọ́ ECHR kí wọ́n lè tún ẹjọ́ rẹ̀ gbé yẹ̀ wò.

Ìgbìmọ̀ Tó Ga Jù Lọ ní Ilé Ẹjọ́ ECHR ń gbọ́ ẹjọ́ Bayatyan v. Armenia, ní November 24, 2010

Ọ̀nà là. Omi tuntun rú, ẹja tuntun rú wọ̀ ọ́ nígbà tí Ìgbìmọ̀ Tó Ga Jù Lọ nínú Ilé Ẹjọ́ ECHR tún ọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Bayatyan gbé yẹ̀ wò. Fúngbà àkọ́kọ́, ní July 7, 2011, Ilé Ẹjọ́ ECHR jẹ́ kó ṣe kedere pé Àpilẹ̀kọ 9 nínú ìwé àdéhùn Convention fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ póun ò wọṣẹ́ ológun. Wọ́n sọ pé ìwé àdéhùn Convention gbéṣẹ́ lọ́jọ́kọ́jọ́, tó fi jẹ́ pé ó yẹ kí wọ́n máa ro ohun tó sọ mọ́ òfin ilẹ̀ Yúróòpù àti tàwọn ilẹ̀ míì kí ẹnu lè kò. Ẹjọ́ tí Ìgbìmọ̀ Tó Ga Jù Lọ náà dá fìdí ẹ̀tọ́ téèyàn ní láti sọ póun ò wọṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn múlẹ̀ ní Yúróòpù, wọ́n tún fi dandan lé e pé kí ìjọba Àméníà ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àfidípò fún àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

“Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ̀rí ọkàn ẹnì kan tàbí ohun tó gbà gbọ́ tọkàntọkàn forí gbárí pẹ̀lú àṣẹ ìjọba láti wá wọṣẹ́ ológun, tẹ́ni náà sì sọ pé òun ò ní lè ṣe é, ó ṣe pàtàkì gan-an, ó sì ṣe kókó láti tẹ̀ lé ohun tí Àpilẹ̀kọ 9 sọ.”—Bayatyan v. Armenia [GC], no. 23459/03, § 110, ECHR 2011

Ìjọba Àméníà Ṣàtúnṣe sí Òfin Tí Wọ́n Ṣe Lórí Iṣẹ́ Àṣesìnlú

Iṣẹ́ àṣesìnlú tí wọn ò ṣètò bó ṣe yẹ ṣì ń dá wàhálà sílẹ̀. Nígbà ìrúwé ọdún 2011, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rin ní Àméníà, títí kan Artur Adyan, ni ilé ẹjọ́ dá lẹ́bi, tí wọ́n sì rán lọ sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ àṣesìnlú tí àwọn ológun ń darí. Wọ́n kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ ECHR pé ìjọba Àméníà ti fi ẹ̀tọ́ àwọn du àwọn, torí pé iṣẹ́ àṣesìnlú tí ìjọba ṣètò bí àfidípò látọdún 2004 ò bá ìlànà ilẹ̀ Yúróòpù mu, ó sì ta ko ẹ̀rí ọkàn àwọn.

Bí iṣẹ́ àṣesìnlú ṣe wà lábẹ́ àwọn ológun ṣì ń dá ìṣòro sílẹ̀. Ní November 27, 2012, Ilé Ẹjọ́ ECHR ṣèpinnu lórí ẹjọ́ Khachatryan and Others v. Armenia, tó ní ín ṣe pẹ̀lú Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́kàndínlógún (19) tó fi iṣẹ́ àṣesìnlú náà sílẹ̀ torí pé abẹ́ àwọn ológun ló wà, kì í ṣe abẹ́ àwọn aláṣẹ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìlú. Ilé Ẹjọ́ ECHR sọ pé bí ìjọba ṣe pe àwọn ọkùnrin náà lẹ́jọ́, tí wọ́n sì fi wọ́n sátìmọ́lé ò bófin mu. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹjọ́ rí i pé àwọn olùpẹ̀jọ́ ṣàlàyé pé abẹ́ àwọn ológun ni iṣẹ́ àṣesìnlú tíjọba ṣètò wà, wọn ò sọ nǹkan kan lórí kókó yẹn nínú ẹjọ́ Khachatryan.

Wọ́n ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú tó mọ́yán lórí. Nígbà ìrúwé ọdún 2013, ìjọba orílẹ̀-èdè Àméníà ṣàtúnṣe sí òfin wọn, wọ́n ṣòfin tó fọwọ́ sí iṣẹ́ àṣesìnlú bí wọ́n ṣe ṣèlérí páwọn máa ṣe lọ́dún 2001. Nígbà tó fi máa di October 2013, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lẹ́wọ̀n ní Àméníà ni wọ́n ti dá sílẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn mélòó kan tí wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lo àkókò wọn pé lẹ́wọ̀n sọ pé àwọn máa kúkú dúró lò ó pé. Àtìgbà yẹn ni wọ́n ti ń jẹ́ káwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun máa ṣiṣẹ́ àṣesìnlú lórílẹ̀-èdè Àméníà.

Ọ̀rọ̀ Ò Tíì Tán Lórí Ẹjọ́ Tó Wà Nílé Ẹjọ́ ECHR

Ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ ECHR ṣe nínú ẹjọ́ Bayatyan àti Khachatryan jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin láti sọ pé àwọn ò ṣiṣẹ́ ológun, ìjọba Àméníà ò sì gbọ́dọ̀ fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n. Àmọ́ ó ṣì ku kí Ilé Ẹjọ́ ECHR sọ pé ètò iṣẹ́ àṣesìnlú ò gbọ́dọ̀ sí lábẹ́ àwọn ológun.

Ìpinnu tí wọ́n ṣe lórí ẹjọ́ Adyan and Others v. Armenia ní October 12, 2017 ni wọ́n ti ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mẹ́nu ba ìyẹn. Nínú ẹjọ́ Ọ̀gbẹ́ni Adyan, Ilé Ẹjọ́ ECHR sọ pé níwọ̀n ìgbà tó ti jẹ́ pé òfin dáàbò bo àwọn tó kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn, wọ́n ní dandan ni kí ìjọba Àméníà ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú tó mọ́yán lórí, tó sì bá ìlànà ilẹ̀ Yúróòpù mu fún àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Wọ́n ní kò gbọ́dọ̀ sí lábẹ́ ìdarí àti àbójútó àwọn ológun, wọn ò sì gbọ́dọ̀ lò ó láti fìyà jẹ àwọn tó ń ṣe é. Ilé Ẹjọ́ ECHR sọ pé kí wọ́n sanwó gbà-máà-bínú fún àwọn ọkùnrin tí wọ́n fìyà jẹ yẹn torí pé wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ àṣesìnlú tí ìjọba láwọn ṣètò.

“Ilé Ẹjọ́ wò ó pé ṣe ni ẹ̀tọ́ tí Àpilẹ̀kọ 9 sọ pé àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun ní kò ní lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ rárá tá a bá gbà kí ìjọba orílẹ̀-èdè kan ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú tó jẹ́ pé abẹ́ ìdarí àwọn ológun ló wà tàbí tí ìjọba ń lò ó láti fìyà jẹ àwọn tó ń ṣe é.”— Adyan and Others v. Armenia, no. 75604/11, § 67, ECHR 2017

Ọ̀rọ̀ Náà Yanjú

Nígbà tó fi máa di January 2018, mọ́kànlélọ́gọ́jọ (161) làwọn ọ̀dọ́kùnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti parí iṣẹ́ àṣesìnlú wọn ní Àméníà, àwọn márùndínláàádọ́fà (105) ṣì wà lẹ́nu ẹ̀. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn aláṣẹ tó ń bójú tó iṣẹ́ náà ń dùn torí àṣeyọrí tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀. Iṣẹ́ náà ń jẹ́ kí wọ́n lè pèsè ohun táwọn aráàlú nílò gangan, àwọn ọkùnrin tó sì láwọn fẹ́ ṣiṣẹ́ àṣesìnlú gẹ́gẹ́ bí àfidípò fara mọ́ èyí tíjọba ṣe lọ́tẹ̀ yìí. Ètò náà tún fòpin sí ìṣòro tó ti wà lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tẹ́lẹ̀ ní Àméníà.

André Carbonneau, ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò tó ṣojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Àméníà gbóríyìn fún ìjọba lórí bí wọ́n ṣe yanjú ọ̀rọ̀ náà. Ó ní: “Àtìgbà tí Ilé Ẹjọ́ ECHR ti ṣèpinnu lórí ẹjọ́ Bayatyan lọ́dún 2011 la ti ń rí ìtẹ̀síwájú lórí bí ilé ẹjọ́ náà ṣe ń dá sí ohun tó ń lọ ní Àméníà. Ẹjọ́ tí wọ́n dá lórí ọ̀rọ̀ Khachatryan àti Adyan jẹ́ kó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ gan-an pé àwọn ológun ò gbọ́dọ̀ ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ àṣesìnlú. A retí pé kí àwọn orílẹ̀-èdè míì tí ò tíì ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú tó mọ́yán lórí kíyè sí àṣeyọrí tí orílẹ̀-èdè Àméníà ti ṣe nígbà tí wọ́n ṣètò tiwọn lọ́nà tí kò ní ṣèpalára fún àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, tó sì máa ṣe àwọn aráàlú láǹfààní.”

Àwọn Orílẹ̀-èdè Kan Tó Kan Iṣẹ́ Ológun Nípá, Tí Wọn Ò sì Ní Ètò Tó Mọ́yán Lórí fún Iṣẹ́ Àṣesìnlú

 

Kò sí ètò iṣẹ́ àṣesìnlú

Wọ́n ń lo iṣẹ àṣesìnlú láti fìyà jẹni

Wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣiṣẹ́ àṣesìnlú, àmọ́ wọn ò gbà wọ́n láyè láti ṣe é

Azerbaijan

 

 

X

Belarus

 

X

 

Eritrea

X

 

 

Lithuania

X *

 

 

Singapore

X

 

 

South Korea

X

 

 

Tajikistan

 

 

X

Turkey

X

 

 

Turkmenistan

X

 

 

Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀

 1. October 12, 2017

  Ilé Ẹjọ́ ECHR ṣèpinnu lórí ẹjọ́ Adyan and Others v. Armenia

 2. January 2014

  Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kọ́kọ́ forúkọ sílẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àṣesìnlú tuntun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn

 3. November 12, 2013

  Fúngbà àkọ́kọ́ láti ohun tó lé ní ogún (20) ọdún, kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan lẹ́wọ̀n lórí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun

 4. June 8, 2013

  Ìjọba Àméníà gbà láti ṣàtúnṣe sí òfin tó dá lórí iṣẹ́ àṣesìnlú. Òfin túntun yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní October 2013

 5. November 27, 2012

  Ilé Ẹjọ́ ECHR ṣèpinnu lórí ẹjọ́ Khachatryan and others v. Armenia

 6. January 10, 2012

  Ilé Ẹjọ́ ECHR ṣe ohun tí wọ́n ṣe nínú ẹjọ́ Bayatyan nígbà tí wọ́n ń dá ẹjọ́ Bukharatyan v. Armenia àti Tsaturyan v. Armenia, wọ́n rí i pé bí ìjọba Àméníà ṣe fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n ta ko ohun tó wà nínú Àpilẹ̀kọ 9

 7. July 7, 2011

  Ìgbìmọ̀ Tó Ga Jù Lọ ní Ilé Ẹjọ́ ECHR rí i pé ìjọba tẹ ẹ̀tọ́ òmìnira ẹ̀rí ọkàn lójú (Àpilẹ̀kọ 9 nínú ìwé àdéhùn European Convention), wọ́n sì fi ẹjọ́ Bayatyan v. Armenia gbèjà ẹ̀tọ́ táwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun ní lábẹ́ òfin

 8. October 27, 2009

  Ilé Ẹjọ́ ECHR ṣèpinnu lórí ẹjọ́ Bayatyan v. Armenia, wọ́n ní Àpilẹ̀kọ 9 nínú ìwé àdéhùn European Convention ò kan ọ̀rọ̀ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun; wọ́n gbé ẹjọ́ náà lọ sí Ìgbìmọ̀ Tó Ga Jù Lọ ní Ilé Ẹjọ́ ECHR

 9. 2004

  Ìjọba Àméníà gbà láti ṣe òfin lórí iṣẹ́ àṣesìnlú, àmọ́ abẹ́ ìdarí àwọn ológun ló máa wà

 10. 2001

  Ìjọba Àméníà sọ pé àwọn máa ṣòfin lórí iṣẹ́ àṣesìnlú

^ ìpínrọ̀ 6 Ìpinnu No. 221 (2000) tí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù ṣe ni pé wọ́n rọ Àméníà láti dara pọ̀ mọ́ Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù tí wọ́n bá lè fọwọ́ sí àdéhùn yìí: . . . pé láàárín ọdún mẹ́ta tí wọ́n bá dara pọ̀, kí wọ́n ṣòfin tó fọwọ́ sí iṣẹ́ àṣesìnlú ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà ilẹ̀ Yúróòpù, kí wọ́n sì rí i pé wọ́n dá gbogbo àwọn tó wà lẹ́wọ̀n tàbí níbi tí wọ́n ti ń dá wọn lóró sílẹ̀ lórí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Tí òfin iṣẹ́ àṣesìnlú bá ti wá múlẹ̀, kí wọ́n jẹ́ kí wọ́n yàn bóyá wọ́n á ṣiṣẹ́ ológun láìgbé ohun ìjà àbí bóyá iṣẹ́ àṣesìnlú ni wọ́n á ṣe.”

^ ìpínrọ̀ 7 Bí ìjọba Àméníà ṣe pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́kàndínlógún (19) lẹ́jọ́, tí wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n kò bófin mu torí pé nígbà tí ilé ẹjọ́ dá wọn lẹ́bi lọ́dún 2005, kò sí òfin ní Àméníà tó sọ pé ẹ̀ṣẹ̀ ni téèyàn bá sọ pé òun ò ṣiṣẹ́ àṣesìnlú mọ́.

^ ìpínrọ̀ 39 Àwọn ológun ló ń darí “àfidípò iṣẹ́ ológun” tí ìjọba orílẹ̀-èdè Lithuania ṣètò.