Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀMÉNÍÀ

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Àméníà

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Àméníà

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lómìnira láti jọ́sìn Ọlọ́run fàlàlà lórílẹ̀-èdè Àméníà, kí wọ́n sì máa ṣe ẹ̀sìn wọn láìfi bẹ́ẹ̀ sí ìdíwọ́. October 2004 ni òfin ti fọwọ́ sí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe.

Tó fi di October 2013, ìṣoro tó le jù táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Àméníà máa ń ní ni bí ìjọba ò ṣe ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú, torí pé iṣẹ́ ológun ni ìjọba orílẹ̀-èdè Àméníà fọwọ́ sí, wọ́n sì máa ń fìyà jẹ àwọn tó bá kọ̀ láti ṣe é. Látọdún 1993, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí ọkàn ni ìjọba ti rán lọ sẹ́wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ, àwọn míì sì jìyà gan-an lẹ́wọ̀n. Àmọ́ ní June 8, 2013, ìjọba orílẹ̀-èdè Àméníà tẹ̀ lé ohun tí Ilé Ẹjọ́ ilẹ̀ Yúróòpù sọ, wọ́n fi ṣàtúnṣe sí òfin tó dá lórí Iṣẹ́ Àṣesìnlú. Ní October 23, 2013, Àjọ Republican Commission ní Àméníà fọwọ́ sí ìwé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jẹ́ mẹ́tàdínlọ́gọ́ta [57] kọ sí ìjọba pé àwọn fẹ́ ṣiṣẹ́ àṣesìnlú. Ètò yìí ti yọrí sí rere, ó ti jẹ́ káwọn ọ̀dọ́kùnrin yìí ṣiṣẹ́ sin orílẹ̀-èdè wọn láìṣe ohun tó ta ko ẹ̀rí ọkàn wọn.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ti dáa sí i lórílẹ̀-èdè yìí, àwọn èèyàn ṣì ń ṣe ẹ̀tanú sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn aláṣẹ láwọn ìlú kan ò fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níwèé àṣẹ láti kọ́ ilé ìjọsìn wọn, àwọn agbófinró tó ń rí sí ẹrù tó ń wọlé sí orílẹ̀-èdè náà ń bu owó orí gọbọi lé ìwé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kó wọlé, bẹ́ẹ̀ sì làwọn alátakò ń bà wọ́n lórúkọ jẹ́ kiri lórí tẹlifíṣọ̀n, nínú ìròyìn àtàwọn ètò orí afẹ́fẹ́ míì. Àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sapá kọ́rọ̀ yìí lè lójútùú, wọ́n ti gbé ọ̀rọ̀ náà dé àwọn ilé ẹjọ́ tó wà lórílẹ̀-èdè Àméníà, wọ́n sì ti fi tó àwọn ilé ẹjọ́ gíga lágbàáyé létí.