Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Méjìlá (12) nínú àwọn arákùnrin tí wọ́n dá lẹ́bi ní 2012 torí pé wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun rèé pẹ̀lú àwọn agbẹjọ́rò wọn (láàárín) ní January 2019

DECEMBER 9, 2019
ÀMÉNÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù Dá Orílẹ̀-èdè Armenia Lẹ́bi Ẹjọ́ Tí Wọ́n Dá Fáwọn Arákùnrin Méjìlélógún (22) Tí Ẹ̀rí Ọkàn Wọn Kò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun

Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù Dá Orílẹ̀-èdè Armenia Lẹ́bi Ẹjọ́ Tí Wọ́n Dá Fáwọn Arákùnrin Méjìlélógún (22) Tí Ẹ̀rí Ọkàn Wọn Kò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun

Ní December 5, 2019, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù dájọ́ pé àwọn arákùnrin méjìlélógún (22) láti orílẹ̀-èdè Armenia tí wọ́n dá lẹ́bi pé wọ́n sá fún iṣẹ́ ológun kò jẹ̀bi rárá. Ilé Ẹjọ́ náà sì ní kí wọ́n san owó gbà-má-bínú tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì ó lé méjìdínláàádọ́rin dọ́là ($267,000) fún àwọn arákùnrin náà. Èyí ni owó tó pọ̀ jù tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù tíì bù rí pé kí wọ́n san fún àwọn arákùnrin wa tí wọ́n pè lẹ́jọ́ nítorí ẹ̀rí ọkàn wọn tí kò jẹ́ kí wọn ṣiṣẹ́ ológun.

Ní 2012, wọ́n dá àwọn arákùnrin yìí lẹ́bi torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun àti pé wọ́n tún kọ̀ láti ṣiṣẹ́ míì tí kì í ṣe iṣẹ́ ológun. Ìdí tí wọ́n fi kọ̀ láti ṣiṣẹ́ míì tí kì í ṣe iṣẹ́ ológun ni pé lákòókò yẹn, àwọn ológun ló ń bójú tó iṣẹ́ náà. Torí náà, a ò lè sọ pé kì í ṣe iṣẹ́ ológun. Nítorí náà, méjì péré nínú àwọn arákùnrin náà ni wọn ò jù sẹ́wọ̀n ṣáájú ọdún 2013, ìyẹn ọdún tí orílẹ̀-èdè Armenia ṣòfin pé kí iṣẹ́ míì wà, tó jẹ́ iṣẹ́ àṣesìnlú lóòótọ́, tí kì í ṣe iṣẹ́ ológun. Ọdún yẹn náà sì ni wọn ò ju àwọn arákùnrin wa sẹ́wọ̀n mọ́ nítorí ẹ̀rí ọkàn wọn tí kò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

Nígbà tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù fẹ́ gbé ìdájọ́ ẹ̀ kalẹ̀ ní December 5, ó tọ́ka sí ìdáláre tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí gbà ní 2017 nínú ẹjọ́ tó wà láàárín orílẹ̀-èdè Armenia àti Adyan pẹ̀lú àwọn ìyókù ẹ̀ (Adyan and Others v. Armenia). Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù sọ pé orílẹ̀-èdè Armenia mọ̀ dáadáa pé ẹjọ́ 2017 yìí jọra gan-an pẹ̀lú ti àwọn arákùnrin méjìlélógún yìí àti pé ṣe ló yẹ kí orílẹ̀-èdè Armenia fìfẹ́ yanjú ọ̀rọ̀ náà. Síbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo bí àwọn arákùnrin wa ṣe sapá tó láti bí ọdún kan sẹ́yìn, ìjọba orílẹ̀-èdè Armenia kọ̀ láti fi wọ́n sílẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ti dá àwọn arákùnrin wa láre.

A dúpẹ́ pé ojú tí ìjọba orílẹ̀-èdè Armenia fi ń wo àwọn tó kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀rí ọkàn wọn ti yàtọ̀ sí i láti 2013. Wọn ò fi àwọn arákùnrin wa sẹ́wọ̀n mọ́, kò sì sí àkọsílẹ̀ mọ́ pé wọ́n jẹ́ ọ̀daràn nítorí wọn ò dá sí tọ̀tún-tòsì. Láti bí ọdún méje sẹ́yìn, orílẹ̀-èdè Armenia ti ṣètò iṣẹ́ míì tí àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun lè ṣe, tí kò sì sí lábẹ́ ìdarí àwọn ológun rárá. Kódà, àwọn orílẹ̀-èdè míì náà ti ń ṣe irú ẹ̀ torí ohun tí wọ́n rí ní Armenia. Àmọ́ ṣá o, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù dá orílẹ̀-èdè Armenia lẹ́bi ní December 5 pé wọn ò tẹ̀ lé òfin àgbáyé ti ọdún 2012.

Pẹ̀lú ìdájọ́ yìí, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ń sọ fún gbogbo ayé pé òun máa fìyà tó tó ìyà jẹ orílẹ̀-èdè èyíkéyìí tó bá tẹ òfin ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àgbáyé lójú. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún àwọn arákùnrin wa tó wà lórílẹ̀-èdè Armenia ní ìdáláre tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí. A gbàdúrà kí Jèhófà ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn arákùnrin wa lórílẹ̀-èdè míì láti má ṣe lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ológun tó jẹ́ dandan, kí wọ́n sì lè ní àǹfààní láti ṣe iṣẹ́ míì dípò iṣẹ́ ológun ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò tíì sí, bí Azerbaijan, South Korea, Turkey àti Turkmenistan.