Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 16, 2017
ÀMÉNÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù Dá Àwọn Tí Ẹ̀rí Ọkàn Wọn Kò Gbà Láyè Láti Wọṣẹ́ Ológun Láre Lórílẹ̀-Èdè Armenia

Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù Dá Àwọn Tí Ẹ̀rí Ọkàn Wọn Kò Gbà Láyè Láti Wọṣẹ́ Ológun Láre Lórílẹ̀-Èdè Armenia

Ní October 12, 2017, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ECHR) dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rin láre. Ìjọba orílẹ̀-èdè Armenia jù wọ́n sẹ́wọ̀n láìtọ́ nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú lábẹ́ ìdarí àwọn ológun. Ilé ẹjọ́ náà sọ pé àwọn ẹlẹ́rìí mẹ́rin yẹn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n torí pé orílẹ̀-èdè Armenia kò gbà wọ́n láyè láti ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú míì tí kò sí lábẹ́ ìdarí àwọn ológun.

Nínú ẹjọ́ Adyan and Others v. Armenia, àwọn arákùnrin mẹ́rin ni ọ̀rọ̀ náà kan. Orúkọ wọn ni: Artur Adyan, Vahagn Margaryan, Harutyun Khachatryan àti Garegin Avetisyan tí wọ́n fẹ̀sùn kàn tí wọ́n sì jù sẹ́wọ̀n fún ọdún méjì àtààbọ̀ lọ́dún 2011. Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù sọ pé ẹjọ́ náà kò tọ́ àti pé ìjọba ti fi ẹ̀tọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà dù wọ́n láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n kí wọ́n sì ṣe ohun tó bá ẹ̀rí ọkàn wọn mu. Wọ́n ní ohun tí ìjọba ṣe yìí ta ko Abala Kẹsàn-án nínú Àdéhùn Àjọṣe Ti Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn. Torí náà, Ilé ẹjọ́ pàṣẹ pé kí ìjọba ilẹ̀ Armenia san EUR 12,000 (ìyẹn ₦5,119,100.00) owó ìtanràn fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn mẹ́rin náà nítorí wàhálà àti ìdààmú tí ọ̀rọ̀ náà ti fà fún wọn àti ìyà tí wọ́n ti jẹ.

Léyìn tí ẹ̀ka Grand Chamber ti ECHR parí ẹjọ́ ọ̀gbẹ́ni Bayatyan àti Armenia lọ́dún 2011, wọ́n sọ pé Abala Kẹsàn-án nínú Àdéhùn Àjọṣe Ti Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn dáàbò bo ẹ̀tọ́ ẹni tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò gbà láyè láti wọṣẹ́ ológun. * Ó wá yani lẹ́nu pé kété lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n pe àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́rin yìí lẹ́jọ́. Pẹ̀lú ohun tí ilé ẹjọ́ sọ yẹn, ó ti di dandan pé kí ìjọba ilẹ̀ Armenia pèsè iṣẹ́ àṣesìnlú míì fáwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà wọ́n láyè láti wọṣẹ́ ológun. Àmọ́ iṣẹ́ àṣesìnlú tí ìjọba Armenia gbé kalẹ̀ kò bá ìlànà ohun tí òfin àgbáyé sọ mu torí pé iṣẹ́ náà wà lábẹ́ ìdarí àwọn ologun ní tààràtà. Àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú náà, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi jù wọ́n sẹ́wọ̀n, kódà wọ́n tún fi ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n jọ ń jọ́sìn sẹ́wọ̀n pẹ̀lú. Nínú ẹjọ́ Adyan, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù dájọ́ pé ìjọba ilẹ̀ Armenia gbọ́dọ̀ pèsè “iṣẹ́ àṣesìnlú míì táwọn aráàlú lè ṣe tí kò sì la iṣẹ́ ológun lọ lọ́nàkọnà.”

Ní ìparí ọdún 2013, lẹ́yìn tí wọ́n dá àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́rin náà sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ìjọba ilẹ̀ Armenia ṣètò ojúlówó iṣẹ́ àṣesìnlú míì tí kò la iṣẹ́ ológun lọ tí kò sì sí lábẹ́ ìdárí àwọn ológun. Nípa bẹ́ẹ̀, ìjọba Armenia ò fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n mọ́ torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà wọ́n láyè láti wọṣẹ́ ológun. Wọ́n mọyì bí ìjọba ṣe pèsè ojúlówó iṣẹ́ àṣesìnlú míì fáwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà láyè láti ṣiṣẹ́ ológun.

^ ìpínrọ̀ 3 Bayatyan v. Armenia [GC], no. 23459/03, ECHR 2011