Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JULY 13, 2018
RỌ́ṢÍÀ

Tọkọtaya Ẹlẹ́rìí Tí Wọ́n Kọ́kọ́ Jù Sẹ́wọ̀n ní Rọ́ṣíà

Tọkọtaya Ẹlẹ́rìí Tí Wọ́n Kọ́kọ́ Jù Sẹ́wọ̀n ní Rọ́ṣíà

Ní July 6, 2018, àwọn aláṣẹ ní ìlú Omsk, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ju tọkọtaya kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí àtìmọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ wọn nílé ẹjọ́, Sergey àti Anastasia Polyakov lorúkọ wọn. Èyí nìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ju Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ obìnrin sí ẹ̀wọ̀n ní Rọ́ṣíà látìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti sọ pé kí wọ́n fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Nígbà tí Ilé iṣẹ́ kan tó máa ń ṣèwádìí, tí wọ́n ń pè ní SOVA Center for Information and Analysis ní ìlú Moscow, ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó ní: “A gbà pé ìpinnu tí wọ́n ṣe yìí, irú bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lápapọ̀, kò bófin mu, ẹ̀tanú ẹ̀sìn gbáà ló jẹ́.”

Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwọn mọ́kànlélógún (21) ọkùnrin àti obìnrin kan ló wà lẹ́wọ̀n lára àwọn ará wa ní Rọ́ṣíà torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Àdúrà wa ni pé kí wọ́n nígboyà, kó sì dá wọn lójú pé Jèhófà ni Olùrànlọ́wọ́ wọn gíga jù lọ.​—Hébérù 13:6.