Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 19, 2018
RỌ́ṢÍÀ

Wọ́n Parọ́ Mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà Pé Wọ́n Ká Ohun Ìjà Mọ́ Wọn Lọ́wọ́ Tí Wọ́n Fi Ń Ṣiṣẹ́ Agbawèrèmẹ́sìn

Wọ́n Parọ́ Mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà Pé Wọ́n Ká Ohun Ìjà Mọ́ Wọn Lọ́wọ́ Tí Wọ́n Fi Ń Ṣiṣẹ́ Agbawèrèmẹ́sìn

Àwọn ilé iṣẹ́ oníròyìn bíi mélòó kan gbé ìròyìn kan jáde pé, nígbà táwọn aláṣẹ ń wo ilé àwọn èèyàn ní agbègbè Kirov lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, wọ́n rí àwọn ohun kan tí wọ́n pè ní ohun ìjà tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ ẹni tí wọ́n rí ohun tí wọ́n pè ní ohun ìjà yìí nílé rẹ̀ kìí ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn àdó olóró tí wọ́n lò kù nígbà Ogun Àgbáyé Kejì ni ohun ìjà tí wọ́n láwọn rí yìí, méjì nínú wọn jẹ́ èyí tí wọ́n máa ń jù, ọ̀kan tó kù sì jẹ́ èyí tí wọ́n ń rì mọ́lẹ̀. Gbogbo wọn ló ti dípẹtà, tí wọn ò sì ṣeé lò mọ́. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ìyàwó onílé yìí, kódà òun gan-an ò mọ̀ pé ọkọ òun nírú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́.

Ọ̀gbẹ́ni tó ni àwọn nǹkan yìí ti fìgbà kan jẹ́ ọ̀gá nínú àwùjọ àwọn tó máa ń wá òkú àwọn ọmọ ogun tó kú nígbà Ogun Àgbáyé Kejì kí wọ́n lè sin wọ́n bó ṣe yẹ. Tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́, wọ́n sábà máa ń rí àwọn nǹkan tí wọ́n fi jagun nígbà yẹn, títí kan àwọn ohun ìjà tí kò wúlò mọ́.

Bí àwọn aláṣẹ nílẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe ń hùmọ̀ irọ́ kí wọ́n lè bà wá lórúkọ jẹ́ pé a kìí ṣe èèyàn àlàáfíà yìí ń rán wa létí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé àwọn alátakò máa “parọ́ oríṣiríṣi ohun burúkú mọ́” àwọn ọmọlẹ́yìn òun.—Mátíù 5:11.