Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JUNE 22, 2018
RỌ́ṢÍÀ

Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò: Àwọn Arábìnrin Márùn-ún Ròyìn Bí Àwọn Ọlọ́pàá Ṣe Já Wọlé Àwọn ní Ìlú Ufa, Lórílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà

Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò: Àwọn Arábìnrin Márùn-ún Ròyìn Bí Àwọn Ọlọ́pàá Ṣe Já Wọlé Àwọn ní Ìlú Ufa, Lórílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà

Láàárọ̀ kùtù April 10, ọdún 2018, àwọn tó ń ṣèwádìí àtàwọn ọlọ́pàá àrà ọ̀tọ̀, tí lára wọn fi nǹkan bojú tí wọ́n sì gbé ìbọn arọ̀jò ọta, já wọlé àwọn Ẹlẹ́rìí ní ìlú Ufa, olú ìlú Bashkortostan, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, wọ́n tú gbogbo ilé wọn yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́. Wọ́n mú Arákùnrin Anatoliy (Tolya) Vilitkevich, àwọn aláṣẹ sì fì í sí àtìmọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Àwọn arábìnrin márùn-ún láti ìlú Ufa, tó fi mọ́ Alyona, ìyàwó Tolya ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n já wọlé wọn.