Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JUNE 8, 2018
RỌ́ṢÍÀ

Ìyàwó Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tó Wà Lẹ́wọ̀n ní Rọ́ṣíà Fi Lẹ́tà Ránṣẹ́ sí Agbani-nímọ̀ràn Putin

Ìyàwó Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tó Wà Lẹ́wọ̀n ní Rọ́ṣíà Fi Lẹ́tà Ránṣẹ́ sí Agbani-nímọ̀ràn Putin

Láàárọ̀ June 7, 2018, mẹ́wàá nínú ìyàwó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́tàdínlógún (17) tó wà lẹ́wọ̀n lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí Mikhail Fedotov, tó jẹ́ agbani-nímọ̀ràn Ààrẹ Putin àti alága Ìgbìmọ̀ Ààrẹ Lórí Ọ̀rọ̀ Aráàlú àti Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn.