Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JUNE 15, 2018
RỌ́ṢÍÀ

Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Gbẹ́sẹ̀ Lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Tẹ́lẹ̀

Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Gbẹ́sẹ̀ Lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Tẹ́lẹ̀

Ní May 3, ọdún 2018, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Saint Petersburg fara mọ́ ìpinnu tí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe ní December 2017 pé kí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tẹ́lẹ̀ èyí tó wà ní abúlé Solnechnoye. Kété ṣáájú ìgbẹ́jọ́ kòtẹ́milọ́rùn, akọ̀ròyìn kan, onímọ̀ nípa ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kan àtàwọn agbẹjọ́rò méjì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí túdìí àṣírí àìṣèdájọ́ òdodo nínú ọ̀ràn òfin yìí. Tọkọtaya kan tí wọ́n lọ́wọ́ sí kíkọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì náà tún ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ṣe rí lára wọn.