Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn ọlọ́pàá ya wọ ibi táwọn èèyàn ti ń jọ́sìn nínú ilé àdáni kan nílùú Tomsk

JUNE 20, 2018
RỌ́ṢÍÀ

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tí Wọ́n Fi Sẹ́wọ̀n Pọ̀ sí I Lẹ́yìn Táwọn Agbófinró Fìbínú Ya Wọ Ilé Àwọn Èèyàn ní Rọ́ṣíà

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tí Wọ́n Fi Sẹ́wọ̀n Pọ̀ sí I Lẹ́yìn Táwọn Agbófinró Fìbínú Ya Wọ Ilé Àwọn Èèyàn ní Rọ́ṣíà

Láàárín oṣù kan tó kọjá, inúnibíni táwọn aláṣẹ Rọ́ṣíà ń ṣe ti légbá kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n mú, tí wọ́n sì fi sẹ́wọ̀n ti pọ̀ sí i lórí ẹ̀sùn pé agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n. Àwọn ọlọ́pàá ya wọ ilé àwọn èeyàn nílùú Birobidzhan, Khabarovsk, Magadan, Orenburg, Naberezhnye Chelny, Perm, Pskov, Saratov àti Tomsk. Ọkùnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ni wọ́n tún mú, àpapọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà látìmọ́lé wá jẹ́ ogún (20). Àwọn méjì míì wà táwọn aláṣẹ sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jáde nílé. Ó kéré tán, Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, títí kan àwọn kan tó ti lé ní àádọ́rin (70) tàbí ọgọ́rin (80) ọdún, ni àwọn aláṣẹ ti sọ pé kí wọ́n tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn pé àwọn ò ní kúrò ládùúgbò táwọn ń gbé. Ní June 14, 2018, iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà táwọn aláṣẹ ní Rọ́ṣíà ti fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn ti lé ní ogójì (40). Tí ilé ẹjọ́ bá sọ pé wọ́n jẹ̀bi, wọ́n lè lò tó ọdún mẹ́wàá lẹ́wọ̀n.

Àwọn ibi táwọn agbófinró ti ya wọ ilé àwọn èèyàn ní Rọ́ṣíà

Ohun tí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń ṣe yìí ti ta ko ìlérí tí wọ́n ṣe ní gbangba nílé ẹjọ́ pé báwọn ṣe fòfin de ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin ò ní ṣèdíwọ́ fún Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ọ̀kan láti má ṣe ohun tó gbà gbọ́. Ṣe ni ìjọba kó ọ̀rọ̀ wọn jẹ pátápátá, wọ́n sì ń ṣi Àpilẹ̀kọ 282 Òfin Ìwà Ọ̀daràn lò láti fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n ń ṣètò iṣẹ́ “agbawèrèmẹ́sìn”, wọ́n ń lọ́wọ́ nínú ẹ̀, wọ́n sì ń náwó sí i. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé iṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn kọ́ ni ìjọba Rọ́ṣíà ń gbéjà kò, àwọn ará ìlú wọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run ní ìrọwọ́rọsẹ̀ ni wọ́n ń ṣenúnibíni sí.

Àwọn Ilé Tí Wọ́n Ya Wọ̀ Lẹ́nu Àìpẹ́ Yìí, Àwọn Tí Wọ́n Mú Àtàwọn Tí Wọ́n Tì Mọ́lé

June 12, 2018, ní Saratov. Àwọn ọlọ́pàá ya wọ ilé ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n túlé wọn, wọ́n sì mú ọ́ kéré tán, Ẹlẹ́rìí mẹ́wàá lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá láti fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. Nígbà táwọn aláṣẹ ń tú ilé kan, wọ́n dọ́gbọ́n fi ìwé ẹ̀sìn kan pa mọ́ síbẹ̀, àwọn ilé ẹjọ́ ní Rọ́ṣíà sì ti fòfin de ìwé náà tẹ́lẹ̀. Ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n mú. Nígbà tó yá, wọ́n tú méjì nínú wọn sílẹ̀, àmọ́ àwọn ọlọ́pàá ò jẹ́ káwọn mẹ́ta tó kù lọ, wọ́n sì fẹ̀sùn kan Konstantin Bazhenov àti Felix Makhammadiev pé wọ́n ń ‘bá iléeṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn ṣètò iṣẹ́.’ A ò tíì mọ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Aleksey Budenchuk, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí kẹta. Nígbà tó di June 14, 2018, Ilé Ẹjọ́ Frunzenskiy ní Saratov sọ pé kí Ọ̀gbẹ́ni Bazhenov àti Ọ̀gbẹ́ni Makhammadiev ṣì wà látìmọ́lé títí di August 12, 2018. Ilé ẹjọ́ yìí kan náà tún sọ pé kí Ọ̀gbẹ́ni Budenchuk wà látìmọ́lé, àmọ́ a ò tíì mọ ọjọ́ tí wọ́n máa dá a sílẹ̀. Yàtọ̀ sí àwọn tá a mẹ́nu bà yìí, àwọn ọlọ́pàá sọ fún Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì pé kó tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn pé òun ò ní kúrò ládùúgbò tóun ń gbé.

June 3, 2018, ní Tomsk. Ní aago mẹ́wàá àárọ̀, àwọn ọlọ́pàá àtàwọn ológun tí wọ́n ń pè ní Spetsnaz ya wọ ilé Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì nílùú Tomsk, ní Sàìbéríà. Nǹkan bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ ọgbọ̀n (30) ni wọ́n mú, títí kan ìyá àgbàlagbà kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin (83). Àwọn ọlọ́pàá kó ohun ìní àwọn èèyàn yìí nílé wọn àti nínú mọ́tò wọn, wọ́n sì fi bọ́ọ̀sì kó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ sí Iléeṣẹ́ Tó Ń Gbéjà Ko Agbawèrèmẹ́sìn.

Nígbà tí wọ́n débẹ̀, Ivan Vedrentsev, Aleksandr Ivanov àti Vyacheslav Lebedev fipá fọ̀rọ̀ wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan lẹ́nu wò títí di aago méjì òru ọjọ́ kejì. Wọ́n halẹ̀ mọ́ ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí náà pé àwọn máa gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Lásìkò tí wọ́n ń fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò yìí, ṣe làwọn ọkọ̀ áńbúláǹsì ń pààrà Iléeṣẹ́ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan, ó kéré tán, ni wọ́n sì gbé lọ sílé ìwòsàn.

Wọ́n ti Sergey Klimov, ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n mú, mọ́lé. Nígbà tó di June 5, 2018, Ilé Ẹjọ́ Oktyabrskiy ní Tomsk fẹ̀sùn kàn án pé ó ń ‘bá iléeṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn ṣètò iṣẹ́’, wọ́n sì sọ pé kó wà látìmọ́lé di August 4, 2018. Àwọn èèyàn ẹ̀ bẹ ilé ẹjọ́ pé kí wọ́n jẹ́ kó pa dà sílé, kódà bí wọ́n bá tiẹ̀ sọ pé kò gbọ́dọ̀ jáde nílé, tàbí kí wọ́n jẹ́ káwọn gba béèlì ẹ̀, àmọ́ adájọ́ ò gbà.

June 3, 2018, ní Pskov. Ọ̀pọ̀ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn ọlọ́pàá ya wọ̀ ní Pskov. Nílé kan tí wọ́n dé, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ ni wọ́n mú, tí wọ́n sì fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò, títí kan àwọn méjì tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n kàn wá kí àwọn ará ilé náà. Wọ́n mú àwọn Ẹlẹ́rìí kan lọ sí Oríléeṣẹ́ Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba ní Pskov, Gennadiy Shpakovsky wà lára àwọn tí wọ́n mú. Àwọn ọlọ́pàá fúngun mọ́ àwọn kan lára àwọn tí wọ́n mú lọ sí àgọ́ wọn pé kí wọ́n jẹ́rìí ta ko Ọ̀gbẹ́ni Shpakovsky. Àwọn aláṣẹ fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn án, wọ́n ní ó ń ‘bá iléeṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn ṣètò iṣẹ́.’ Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n pa dà tú u sílẹ̀, ìgbàkígbà làwọn aláṣẹ lè tún ṣíwèé kan ọ̀rọ̀ ẹ̀.

May 30, 2018, ní Khabarovsk. Àwọn ọlọ́pàá ya wọ ilé Ivan Puyda, lẹ́yìn tí wọ́n tú ilé ẹ̀, wọ́n mú un lọ sílùú Magadan, wọ́n sì fi sí àtìmọ́lé. Nígbà tó di June 1, 2018, Ilé Ẹjọ́ Zheleznodorozhniy fẹ̀sùn kan Ọ̀gbẹ́ni Puyda pé ó ń ‘bá iléeṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn ṣètò iṣẹ́’, wọ́n sì sọ pé kó ṣì wà látìmọ́lé di July 30, 2018.

May 30, 2018, ní Magadan. Àwọn ọlọ́pàá tó dira ogun, tí wọ́n sì fi nǹkan bojú ya wọ ilé àwọn èèyàn ní Magadan, wọ́n sì mú Konstantin Petrov, Yevgeniy Zyablov àti Sergey Yerkin. Wọ́n wá fi wọ́n sátìmọ́lé. Nígbà tó di June 1, 2018, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Magadan fẹ̀sùn kan Ọ̀gbẹ́ni Petrov àti Ọ̀gbẹ́ni Zyablov pé wọ́n ń ‘bá iléeṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn ṣètò iṣẹ́.’ Lọ́jọ́ yẹn kan náà, Ilé Ẹjọ́ Magadanskiy fẹ̀sùn kan Ọ̀gbẹ́ni Yerkin. Ilé ẹjọ́ ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣì wà látìmọ́lé títí di July 29, 2018.

Dmitriy Mikhailov

May 29, 2018, ní Shuya, Àgbègbè Ivanovo. Ẹ̀ẹ̀kejì táwọn aláṣẹ máa mú Dmitriy Mikhailov rè é, tí wọ́n á sì tì í mọ́lé. Ní April 20, lẹ́yìn táwọn ọlọ́pàá ya wọ ilé rẹ̀, wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó ń ‘lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tí iléeṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn ń ṣe’, wọ́n sì ní kó tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn pé òun ò ní kúrò lágbègbè náà. Nígbà tó di May 29, àwọn aláṣẹ tún fẹ̀sùn kàn án pé ó ń ‘fi owó ti iṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn lẹ́yìn.’ Ní June 3, 2018, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Shuya sọ pé kó ṣì wà látìmọ́lé títí di July 19, 2018.

May 27, 2018, ní Naberezhnye Chelny, Republic of Tatarstan. Lóru mọ́jú, àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba tú ilé àdáni mẹ́wàá, wọ́n gba àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé, fóònù àti ìwé ìrìnnà. Wọ́n mú Ilkham Karimov, Konstantin Matrashov àti Vladimir Myakushin, wọ́n sì tì wọ́n mọ́lé. Nígbà tó di May 29, 2018, Ilé Ẹjọ́ Naberezhnochelninskiy fẹ̀sùn kan àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pé wọ́n ń bá iléeṣẹ́ “agbawèrèmẹ́sìn” ṣiṣẹ́, wọ́n ń bá wọn ṣètò iṣẹ́, wọ́n sì ń bá wọn gba èèyàn síṣẹ́. Ilé ẹjọ́ sọ pé kí wọ́n ṣì wà ní àtìmọ́lé títí di July 25, 2018. Nígbà tó yá, wọ́n mú Aydar Yulmetyev náà, nígbà tó sì di May 31, 2018, ilé ẹjọ́ sọ pé kóun náà ṣì wà látìmọ́lé.

May 22, 2018, ní Perm. Lẹ́yìn tí Aleksandr àti Anna Solovyev dé láti Moldova pa dà sílùú Perm, àwọn ọlọ́pàá lọ ká wọn mọ́ ibùdókọ̀ ọkọ̀ ojú irin. Wọ́n de Ọ̀gbẹ́ni Solovyev ní ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀, wọ́n gba nǹkan ìní ẹ̀, wọ́n sì fi mọ́tò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ gbé òun àti ìyàwó ẹ̀ lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá. Nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni Solovyev ṣì wà látìmọ́lé, àwọn ọlọ́pàá lọ tú ilé ẹ̀, wọ́n sì fọ̀rọ̀ wá ìyàwó ẹ̀ lẹ́nu wò. Ní May 24, 2018, Ilé Ẹjọ́ Sverdlovskiy fẹ̀sùn kan Ọ̀gbẹ́ni Solovyev pé ó ń ‘lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tí iléeṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn ń ṣe’, wọ́n wá ní kó máa lọ sílé, àmọ́ kò gbọ́dọ̀ jáde nílé.

May 17, 2018, ní Birobidzhan. Àádọ́jọ (150) ọlọ́pàá àtàwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba kóra wọn jọ, wọ́n sì ya wọ ilé Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìlélógún (22). Àwọn ọlọ́pàá náà gba tablet wọn, fóònù àti owó wọn. Wọ́n mú Alam Aliev, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34) tí wọ́n yẹ ara wọn wò bí wọ́n ṣe ń ya wọ ilé káàkiri, wọ́n sì fi sẹ́wọ̀n. Ní May 18, Ilé Ẹjọ́ Birobidzhanskiy fẹ̀sùn kàn án pé ó ń ‘bá iléeṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn ṣètò iṣẹ́’, wọ́n sì ní kó wà látìmọ́lé títí di July 13, 2018. Nígbà tó di May 25, 2018, Adájọ́ A. V. Sizova ti ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn Appellate Court of the Jewish Autonomous Region fọwọ́ sí ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Ọ̀gbẹ́ni Aliev pè, ó sì ní kí wọ́n dá a sílẹ̀ látìmọ́lé.

May 16, 2018, ní Orenburg. Àwọn ọlọ́pàá ya wọ ilé àwọn èèyàn, wọ́n sì túlé wọn. Wọ́n mú Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́ta, ìyẹn Aleksandr Suvorov, Vladimir Kochnev àti Vladislav Kolbanov. Ní May 18, Ilé Ẹjọ́ Promyshlenniy fẹ̀sùn kan Ọ̀gbẹ́ni Kolbanov pé ó ń ‘fi owó ti iṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn lẹ́yìn.’ Ilé ẹjọ́ dá a sílẹ̀ pé kó máa lọ sílé, àmọ́ kò gbọ́dọ̀ jáde nílé. Lọ́jọ́ kejì, ilé ẹjọ́ yìí kan náà fẹ̀sùn kan Ọ̀gbẹ́ni Kochnev àti Ọ̀gbẹ́ni Suvorov pé wọ́n ń ‘bá iléeṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn ṣètò iṣẹ́’, wọ́n sì sọ pé kí wọ́n wà látìmọ́lé títí di July 14, 2018. Ẹni tó fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò tún sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méje míì pé kí wọ́n tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn pé àwọn ò ní kúrò nílùú lásìkò tí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ṣì ń lọ lọ́wọ́.

Lápá òsì: Aleksandr Suvorov; Lápá ọ̀tún: Vladimir Kochnev

Ṣé Nǹkan Á Yí Pa Dà Pẹ̀lú Bí Gbogbo Èèyàn Lágbàáyé Ṣe Ń Bá Ìjọba Rọ́ṣíà Wí Yìí?

Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù (ìyẹn EU) àti ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti kọ̀wé sí ìjọba Rọ́ṣíà láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn ò fara mọ́ ọwọ́ tí wọ́n fi mú òmìnira àwọn aráàlú lábẹ́ òfin. Ìgbìmọ̀ EU sọ fún ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà pé “kí wọ́n ṣe ohun tó bá àdéhùn tí wọ́n ti tọwọ́ bọ̀ lọ́dọ̀ ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé mu, ìyẹn lórí ọ̀rọ̀ òmìnira ẹ̀sìn tàbí ìgbàgbọ́, òmìnira ọ̀rọ̀ àti òmìnira láti kóra jọ.” Bákan náà, ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà rọ ìjọba Rọ́ṣíà pé kí wọ́n “dá gbogbo àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n lórí pé wọ́n ń lo òmìnira ẹ̀sìn tàbí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”

Philip Brumley, tó jẹ́ Agbẹ́jọ́rò Àgbà fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Ọkàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ò balẹ̀ rárá lórí inúnibíni tó rorò táwọn aláṣẹ ń ṣe sí àwọn ará wọn ní Rọ́ṣíà. Ohun tójú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí kọjá lábẹ́ ìjọba Kọ́múníìsì lojú wọn tún ń rí lónìí. Ohun tí ìjọba Rọ́ṣíà ń ṣe yìí, tí wọn ò sì yéé fojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbolẹ̀ ta ko àdéhùn tí wọ́n ṣe pátápátá, pé àwọn ò ní fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn táwọn èèyàn ní dù wọ́n.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti wà látìmọ́lé tẹ́lẹ̀ *

 • Dennis Christensen

  Ẹni ọdún 45, nílùú Oryol, ó ti wà látìmọ́lé láti May 25, 2017, wọ́n ní kó ṣì wà níbẹ̀ títí di August 1, 2018.

 • Valentin Osadchuk

  Ẹni ọdún 42, nílùú Vladivostok, ó ti wà látìmọ́lé láti April 19, 2018, wọ́n ní kó ṣì wà níbẹ̀ títí di June 20, 2018.

 • Viktor Trofimov

  Ẹni ọdún 61, nílùú Polyarny, ó ti wà látìmọ́lé láti April 18, 2018, wọ́n ní kó ṣì wà níbẹ̀ títí di October 11, 2018.

 • Roman Markin

  Ẹni ọdún 44, nílùú Polyarny, ó ti wà látìmọ́lé láti April 18, 2018, wọ́n ní kó ṣì wà níbẹ̀ títí di October 11, 2018.

 • Anatoliy Vilitkevich

  Ẹni ọdún 31, nílùú Ufa, ó ti wà látìmọ́lé láti April 10, 2018, wọ́n ní kó ṣì wà níbẹ̀ títí di July 2, 2018.

^ ìpínrọ̀ 21 Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, wo àpilẹ̀kọ yìí tó wà ní abala Ìròyìn lórí ìkànnì jw.org tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Wọ́n Ti Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣúkaṣùka Lórílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà.”