Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́—Rọ́ṣíà
Nǹkan ò rọrùn rárá fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Bí ìjọba ṣe ń ṣenúnibíni sí wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń fìyà jẹ wọ́n. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ogún, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn aláṣẹ ti halẹ̀ mọ́ wọn, tí wọ́n sì hùwà ìkà sí wọn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé èèyàn àlàáfíà ni wọ́n, tí wọ́n sì ń pa òfin ìjọba mọ́. Ìjọba Soviet Union fẹ́ káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dara pọ̀ mọ́ àwọn, wọ́n sì pinnu pé ńṣe làwọn máa fipá mú wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, wọn ò fẹ́ ká ní Bíbélì tàbí àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Gbogbo ìgbà làwọn aláṣẹ ń ṣọ́ wọn lọ́wọ́ lẹ́ṣẹ̀, torí náà ìkọ̀kọ̀ ni wọ́n ti máa ń pàdé pọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tọ́wọ́ àwọn agbófinró bá tẹ̀ wọ́n, ńṣe ni wọ́n máa lù wọ́n, tí wọ́n á sì fi wọ́n sí ẹ̀wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ. Kódà, ìjọba rán ọ̀pọ̀ lára wọn lọ sí ìgbèkùn ní Siberia.
Nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà lọ́dún 1991 nígbà tí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà gbà káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà forúkọ sílẹ̀ lábẹ́ òfin, tí wọ́n sì fún wa lómìnira láti máa jọ́sìn láìsí pé àwọn agbófinró ń yọ wọ́n lẹ́nu. Àmọ́, àsìkò tí wọ́n fi fún wa lómìnira yẹn ò pẹ́ rárá.
Nígbà tó di ọdún 2009, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í ta ko àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ń fòfin de iṣẹ́ wa lẹ́yìn tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fara mọ́ ìpinnu ilé ẹjọ́ kan tó sọ pé “agbawèrèmẹ́sìn” làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ọdún lọ̀rọ̀ náà fi wà nílé ẹjọ́. Àmọ́ ní April 2017, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kéde ìdájọ́ lórí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n fẹ̀sùn kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé à ń lọ́wọ́ sí iṣẹ́ àwọn agbawèrèmẹ́sìn, torí náà ilé ẹjọ́ fòfin de iṣẹ́ wa. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fòfin de àwọn ilé táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣiṣẹ́, wọ́n ti àwọn ilé ìjọsìn wa pa, wọ́n sì pe àwọn ìwé wa ní “ìwé àwọn agbawèrèmẹ́sìn.”
Lẹ́yìn táwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fòfin de àjọ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ òfin, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í ta kò wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Ohun tí wọ́n ṣe yìí fi hàn pé wọ́n kọjá àyè wọn, torí ohun tí wọ́n ń sọ ni pé bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn ṣe ń jọ́sìn láyè ara wa, ńṣe là ń ṣètìlẹyìn fún àjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìjọba ti fòfin dè. Làwọn ọlọ́pàá bá bẹ̀rẹ̀ sí í ya wọ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n ń fìyà jẹ wọ́n, wọ́n sì ń fagídí bi wọ́n ní ìbéèrè. Wọ́n ń mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́kùnrin lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà. Wọ́n fi wọ́n sátìmọ́lé, wọ́n dá wọn lẹ́bi nílé ẹjọ́, lẹ́yìn náà wọ́n rán àwọn kan lọ sẹ́wọ̀n, wọ́n sì sé àwọn míì mọ́lé.
Láti April 2017 tí ìjọba ti fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọ̀pọ̀ lára wa ni wọ́n ti fẹ̀sùn kàn pé wọ́n jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn, ìjọba sì ti rán ọ̀pọ̀ lára wọn lọ sí àtìmọ́lé tàbí lọ sẹ́wọ̀n. Nígbà tó fi máa di April 17, 2024, iye àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ti fi sẹ́wọ̀n jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123).
Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ò Fara Mọ́ Bí Ìjọba Rọ́ṣíà Ṣe Ń Fìyà Jẹ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn àjọ tó wà kárí ayé ń sọ fún ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà pé kí wọ́n fòpin sí inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ńṣe làwọn aláṣẹ yìí túbọ̀ ń halẹ̀ mọ́ wa, tí wọ́n sì ń dá wa lẹ́bi pé agbawèrèmẹ́sìn ni wa. Ọ̀pọ̀ ilé ẹjọ́ àtàwọn èèyàn tí ò sí ní Rọ́ṣíà ló ti dá ìjọba Rọ́ṣíà lẹ́bi nítorí ínúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù: Ní June 7, 2022, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù dá ẹjọ́ mánigbàgbé kan, ilé ẹjọ́ náà dẹ́bi fún ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà lórí bí wọ́n ṣe ń ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà (ìyẹn ẹjọ́ Taganrog LRO and Others v. Russia, nos. 32401/10 and 19 others). Wọ́n sọ pé kò bófin mu bí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 2017. Ilé ẹjọ́ náà wá pàṣẹ pé kí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà “rí i pé wọ́n fòpin sí gbogbo ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà . . . kí wọ́n sì dá . . . gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà [tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n] sílẹ̀.” Láfikún sí ìyẹn, wọ́n pàṣẹ fún orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà pé kí wọ́n dá gbogbo ohun ìní àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé pa dà tàbí kí wọ́n san owó ìtanràn tó lé ní ọgọ́ta mílíọ̀nù (60,000,000) dọ́là, kí wọ́n tún fún àwọn tó pe ẹjọ́ náà ní ohun tó ju mílíọ̀nù mẹ́ta (3,000,000) dọ́là gẹ́gẹ́ bíi owó gbà-má-bínú.
Lẹ́tà látọ̀dọ̀ Akọ̀wé Àgbà Àjọ Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù (Council of Europe): Nínú lẹ́tà kan tí àjọ náà kọ sí Mínísítà Ilẹ̀ Òkèrè fún Orílẹ̀-èdè Rọ́síà ní December 9, 2022, Marija Pejčinović Burić sọ pé: “Lórí ẹjọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Moscow àtàwọn míì pè lòdì sí Krupko àtàwọn mìí (Jehovah’s Witnesses of Moscow and Others and Krupko and Others) nípa bí ìjọba ṣe fòfin de iṣé wọn, tí wọ́n mú kó nira fún wọn láti máa ṣe ìjọsìn tí wọ́n máa ń ṣe láìda àlàáfíà ìlú rú, tíyẹn sì mú kí ìjọba fi ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní lábẹ́ òfin dù wọ́n, Ìgbìmọ̀ yìí rọ ìjọba pé kí wọ́n fòpin sí bí wọ́n ṣe fòfin de iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí wọ́n sì fagi lé gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n.”
Ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ Àwọn Mínísítà Àjọ Ilẹ̀ Yúróòpù Ṣe: Níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe ní September 2023, Ìgbìmọ̀ Àwọn Mínísítà náà sọ pé ó kọ àwọn lóminú nígbà táwọn kíyè sí i pé “ṣe làwọn aláṣẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà mọ̀ọ́mọ̀ kọ̀ láti tẹ̀ lé àwọn ohun tó ṣe kedere tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn tọ́ka sí nínú Àpilẹ̀kọ 46 Ìwé Àdéhùn àti nínú ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ ṣe lórí ẹjọ́ Taganrog LRO and Others, pàápàá lórí ọ̀rọ̀ tó kan . . . dídá àwon Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lẹ́wọ̀n sílẹ̀.” Ní báyìí tí àwọn aláṣẹ Rọ́síà sì ti kọ̀ láti ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, Ìgbìmọ̀ náà “pinnu láti gbé àwọn ẹjọ́ yìí wá síwájú Àjọ Tó Ń Rí Sọ́rọ̀ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé, Àjọ Tó Ń Rí sí Títini Mọ́lé Láìnídìí lábẹ́ ìdarí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé àtàwọn àjọ àgbáyé míì tó ń rí sọ́rọ̀ àwọn tó ń ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ìgbìmọ̀ Àwọn Mínísítà yìí fẹ́ rí i dájú pé àwọn aláṣẹ tẹ̀ lé ìlànà tó yẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀.”
Àpẹẹrẹ Àwọn Ìdájọ́ Tó Le Tó Wáyé Lẹ́nu Àìpẹ́ Yìí
Ní January 25, 2024, wọ́n rán Sona Olopova lọ sẹ́wọ̀n ọdún méjì pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Ẹni ọdún mẹ́tàdínlógójì (37) ni, ó sì ti lọ́kọ. Ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní agbègbè Samara ni wọ́n rán an lọ.
Ní July 2018, àwọn agbófinró tó dira ogun ya wọ ilé tí Dmitriy àti Yelena Barmakin ń gbé, tí wọ́n ti ń tọ́jú ìyá-ìyá Yelena tó jẹ́ ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún. Wọ́n gbé Dmitriy àti Yelena pa dà sí Vladivostok tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ wọn, ibẹ̀ làwọn ọlọ́pàá sì ti mú Dmitriy. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn án pé ó “ń ṣètò iṣẹ́ àwọn agbawèrèmẹ́sìn.” Nígbà tó di February 6, 2024, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn dá a lẹ́bi, ilé ẹjọ́ yẹn ló sì gbà dé àtìmọ́lé. Wọ́n ní kó lọ parí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́jọ tí wọ́n rán an lọ. Wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ Yelena ìyàwó ẹ̀ náà lọ́wọ́ báyìí, wọ́n fẹ̀sùn kàn án torí ohun tó gbà gbọ́.
Ilé ẹjọ́ Tsentralniy tó wà nílùú Tolyatti lágbègbè Samara rán Aleksandr Chagan, tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́ta (53) tó sì ti níyàwó, lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́jọ. Ó wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ ọkùnrin tí wọ́n tíì rán lọ sẹ́wọ̀n fọ́dún tó pọ̀ jù lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ní February 29, 2024, lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀ tán, ilé ẹjọ́ ló gbà dé àtìmọ́lé. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ọgbà Detention Center No. 4 lágbègbè Samara ló wà.
Ilé ẹjọ́ kan lágbègbè Irkutsk ní ìlà oòrùn Siberia dá ọkùnrin mẹ́sàn-án tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́bi pé wọ́n jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn. Ní March 5, 2024, wọ́n rán àwọn ọkùnrin náà lọ sẹ́wọ̀n, àkókò tí kálukú máa lò lẹ́wọ̀n yàtọ̀ síra, ẹni tó sì máa lo àkókò tó pọ̀ jù á fẹ́rẹ̀ẹ́ lò tó ọdún méje. Ẹni tó dàgbà jù nínú wọn jẹ́ ẹni ọdún méjìléláàádọ́rin (72). October 2021 ni gbogbo ọ̀rọ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́, nígbà táwọn agbófinró bẹ̀rẹ̀ sí í lọ yẹ ilé àwọn èèyàn wò, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ̀sùn ọ̀daràn kan àwọn kan. Nígbà tí wọ́n fi máa rán àwọn ọkùnrin yẹn lọ sẹ́wọ̀n, Yaroslav Kalin tó jẹ́ ọ̀kan nínú wọn ti lo ohun tó lé ní ọdún méjì látìmọ́lé láìtíì gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀. Ó ṣàlàyé pé ohun tójú òun rí látìmọ́lé kọjá ohun tẹ́nu lè ròyìn, àti pé “ibẹ̀ ò yẹ ọmọlúàbí.”
Ohun Táwọn Èèyàn Ń Ṣe Láti Fòpin sí Bí Ìjọba Rọ́ṣíà Ṣe Ń Tini Mọ́lé Lọ́nà Àìtọ́
Ṣe ni inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà kárí ayé máa ń bà jẹ́ tá a bá gbọ́ bí ìjọba Rọ́ṣíà ṣe ń fìyà jẹ àwọn ará wa tó wà lórílẹ̀-èdè náà. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé la ti kọ lẹ́tà sí ìjọba Rọ́ṣíà láti bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n dá àwọn ará wa tó wà lẹ́wọ̀n sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn agbẹjọ́rò tó ń gbèjà àwa Ẹlẹ́rìí tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní oríṣiríṣi ilé ẹjọ́ tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́síà, títí kan Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ti fẹjọ́ sun Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí Sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé, a sì ti fẹjọ́ sun Àjọ Tó Ń Rí Sí Títini Mọ́lé Láìnídìí. Bákan náà, a ti gbé ọ̀pọ̀ ìròyìn lọ sọ́dọ̀ oríṣiríṣi àwọn ẹgbẹ́ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lágbàáyé. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa lo gbogbo àǹfààní tá a bá rí láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa ìyà tí ìjọba Rọ́ṣíà fi ń jẹ àwọn ará wa tó wà lórílẹ̀-èdè náà, kí ìjọba lè fòpin sí inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sí wa torí ohun tá a gbà gbọ́.
Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀
April 17, 2024
Iye àwa Ẹlẹ́rìí tó wà lẹ́wọ̀n di mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123).
October 24, 2023
Àjọ CCPR, ìyẹn Àjọ Tó Ń Rí Sọ́rọ̀ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé ṣe Ìpinnu méjì lórí ọ̀rọ̀ Ètò Ẹ̀sìn Elista àti Abinsk. Ohun tí àjọ CCPR parí èrò sí lórí ọ̀rọ̀ méjèèjì ni pé àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ti fi ẹ̀tọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dù wọ́n, bó ṣe wà nínú Àpilẹ̀kọ 18.1 (“ẹ̀tọ́ sí òmìnira èrò, ẹ̀rí ọkàn àti ẹ̀sìn”) àti Àpilẹ̀kọ 22.1 (“ẹ̀tọ́ sí òmìnira ìkórajọ”) nínú ìwé àdéhùn International Covenant on Civil and Political Rights. Ìpinnu tí àjọ CCPR ṣe yìí fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé kò sí ohunkóhun nínú ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń mú káwọn èèyàn kórìíra ara wọn tàbí hùwà ipá.
June 7, 2022
Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù dá ẹjọ́ mánigbàgbé kan, ìyẹn Taganrog LRO and Others v. Russia, wọ́n dẹ́bi fún orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà torí bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
January 12, 2022
Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fòfin de JW Library, wọ́n sọ pé Ẹrù Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn ni. JW Library ni ètò orí kọ̀ǹpútà tí wọ́n máa kọ́kọ́ fi orúkọ ẹ̀ sára àwọn nǹkan tí wọ́n pè ní ẹrù àwọn agbawèrèmẹ́sìn lórílẹ̀-èdè náà.
September 27, 2021
Ilé ẹjọ́ ìlú Saint Petersburg wọ́gi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tá a pè lórí ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ dá ní March 31, 2021 pé ẹnì kankan ò gbọ́dọ̀ lo JW Library lórílẹ̀ èdè Rọ́ṣíà àti Crimea. Ohun tí ilé ẹjọ́ sọ tẹ́lẹ̀ náà ló ṣì fìdí múlẹ̀.
April 26, 2019
Àjọ Tó Ń Rí sí Títini Mọ́lé Láìnídìí lábẹ́ ìdarí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé rí i pé wọ́n ti fi ẹ̀tọ́ Dimtriy Mikhailov dù ú, àjọ náà sì bẹnu àtẹ́ lu bí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe ń fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
April 20, 2017
Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà sọ pé kí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà àtàwọn àjọ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó dín márùn-ún (395) tá à ń lò lábẹ́ òfin.