Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 31, 2018
RỌ́ṢÍÀ

Ẹlẹ́rìí Jèhófà Míì Tún Ti Fojú Ba Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́ṣíà Lórí Ẹ̀sùn Pé Ó Ń Ṣiṣẹ́ Agbawèrèmẹ́sìn

Ẹlẹ́rìí Jèhófà Míì Tún Ti Fojú Ba Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́ṣíà Lórí Ẹ̀sùn Pé Ó Ń Ṣiṣẹ́ Agbawèrèmẹ́sìn

Ẹni àádọ́rin (70) ọdún ni Arkadya Akopyan, aránṣọ tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ni, Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ni. Ó ti tó ọdún kan báyìí tó ti ń fojú ba ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé ó ń ṣiṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn. Tí ilé ẹjọ́ bá dá a lẹ́bi, ṣe ni wọ́n máa bu owó ìtanràn gọbọi lé e, tàbí kí wọ́n ní kó fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin gbára.

Àwọn olùpẹ̀jọ́ fẹ̀sùn kan Ọ̀gbẹ́ni Akopyan pé ó jẹ̀bi bó ṣe ń “mú kí àwọn èèyàn kórìíra ẹ̀sìn míì” torí pé ó ń ṣèwàásù nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó ti ń lọ ṣèjọsìn déédéé látọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Nílé ẹjọ́, àwọn mẹ́fà tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n fẹ́ jẹ́rìí èké ni àwọn olùpẹ̀jọ́ gbára lé. Wọ́n ní ọ̀rọ̀ ìbanijẹ́ ni Ọ̀gbẹ́ni Akopyan sọ nígbà tó ń wàásù, àti pé ó fún àwọn ní ìwé “agbawèrèmẹ́sìn” pé káwọn pín in fáwọn míì.

Àmọ́ Ọ̀gbẹ́ni Akopyan àtàwọn tó mọ̀ ọ́n sọ pé irọ́ làwọn ẹ̀sùn yìí. Agbẹjọ́rò rẹ̀ mú ẹ̀rí wá sílé ẹjọ́ láti fi hàn pé àwọn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí wọ́n fẹ̀sùn èké kàn án yìí ò tiẹ̀ sí ní àyíká ilé ìjọsìn tí wọ́n sọ pé Arákùnrin Akopyan tí sọ àwọn nǹkan tí wọ́n ló sọ. Bákan náà, tó bá dọ̀rọ̀ ká fún àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí ní ìwé ẹ̀sìn pé kí wọ́n wá máa pín in, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í kàn dédé ṣe bẹ́ẹ̀ láìrò ó jinlẹ̀. Sonya, tó jẹ́ ìyàwó Ọ̀gbẹ́ni Akopyan, tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, sọ fún ilé ẹjọ́ nígbà tí wọ́n ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò pé ogójì (40) ọdún lòun àti ọkọ òun ti jọ ń bára àwọn bọ̀, táwọn sì ń láyọ̀, àti pé ọkọ òun ò fipá mú ìkankan nínú àwọn mọ̀lẹ́bí wọn rí pé kí wọ́n wá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Adájọ́ Oleg Golovashko sọ pé káwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí Ọ̀gbẹ́ni Akopyan sọ nígbà tó ń ṣèwàásù, kí wọ́n lè mọ̀ bóyá lóòótọ́ ló ti “mú kí àwọn èèyàn kórìíra ẹ̀sìn míì.” Láìpẹ́ yìí ní May 15, 2018, tí Ọ̀gbẹ́ni Akopyan fojú ba ilé ẹjọ́ gbẹ̀yìn, adájọ́ sọ pé káwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tó ń ṣàyẹ̀wò rí i pé wọ́n ṣe àyẹ̀wò wọn tán ní September 2018, àmọ́ Ọ̀gbẹ́ni Akopyan á ṣì máa wá sílé ẹjọ́. June 5 ni ilé ẹjọ́ á tún fọ̀rọ̀ wá Ọ̀gbẹ́ni Akopyan lẹ́nu wò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò ti Ọ̀gbẹ́ni Akopyan mọ́lé, wọn ò gbà kó rìnrìn àjò látìgbà tí wọ́n ti ń gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ ní May 2017 nílé ẹjọ́ Prokhladny.

Gregory Allen, tó jẹ́ Igbá Kejì Agbẹjọ́rò Àgbà fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Ìjọba Rọ́ṣíà ò mú un ní kékeré rárá, ṣe ni wọ́n ń ṣi òfin agbawèrèmẹ́sìn lò láti fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bí Ọ̀gbẹ́ni Akopyan. Kò kúkú mọwọ́ mẹsẹ̀, kì í tẹ òfin ìlú lójú, ohun tó sì fẹ́ ò ju pé kó máa jọ́sìn Ọlọ́run ní àlàáfíà. Bí ìjọba ṣe dájú sọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́nà òdì yìí fi hàn pé kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọn ò lè fipá mú, ó sì ń ṣèpalára fún aráàlú.”

Ọ̀gbẹ́ni Akopyan ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà kejì tí wọ́n fẹ̀sùn kàn láìtọ́ ní Rọ́ṣíà pé ó ń “ṣiṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn.” February 2018 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ẹjọ́ Dennis Christensen, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó wà nílùú Oryol. Ọdun kan ló ti lò látìmọ́lé, tí ilé ẹjọ́ bá sì dá a lẹ́bi, wọ́n lè ní kó fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá gbára. * Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méje míì wà látìmọ́lé lóríṣiríṣi àgbègbè ní Rọ́ṣíà àmọ́ tí ilé ẹjọ́ ò tíì gbọ́ ẹjọ́ wọn.

^ ìpínrọ̀ 7 Òfin Ìwà Ọ̀daràn ni wọ́n fi fẹ̀sùn kan àwọn méjèèjì, àmọ́ àpilẹ̀kọ tí wọ́n fi mú kálukú yàtọ̀. Àpilẹ̀kọ 282(1) ni wọ́n fi fẹ̀sùn kan Ọ̀gbẹ́ni Akopyan pé ó ń mú kí àwọn èèyàn máa kórìírá ẹ̀sìn míì. Àmọ́ Àpilẹ̀kọ 282(1) ni wọ́n fi fẹ̀sùn kan Dennis Christensen pé ó ń ṣètò ìjọsìn nínú ẹ̀sìn tí ìjọba ti kéde pé ó jẹ́ tàwọn agbawèrèmẹ́sìn. Ìyà tó máa ń bá ẹ̀sùn yìí rìn máa ń pọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lọ.