Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Aleksey Budenchuk, Konstantin Bazhenov, Feliks Makhammadiyev, Aleksey Miretskiy, Roman Gridasov àti Gennadiy German ṣáájú kí wọ́n tó mú wọn

SEPTEMBER 23, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Wọ́n Dá Àwọn Arákùnrin Mẹ́fà Míì Lẹ́bi, Wọ́n Sì Jù Wọ́n Sẹ́wọ̀n ní Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà

Wọ́n Dá Àwọn Arákùnrin Mẹ́fà Míì Lẹ́bi, Wọ́n Sì Jù Wọ́n Sẹ́wọ̀n ní Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà

Ní Thursday, September 19, 2019, ilé ẹjọ́ dá àwọn arákùnrin mẹ́fà láti ìlú Saratov, ní Rọ́ṣíà lẹ́bi wọ́n sì jù sẹ́wọ̀n, kìkì nítorí pé wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Adájọ́ Dmitry Larin ti ilé ẹjọ́ Leninsky District Court of Saratov dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ fún Arákùnrin Konstantin Bazhenov àti Arákùnrin Aleksey Budenchuk; ó dá ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta fún Arákùnrin Feliks Makhammadiyev; ó sì dá ẹ̀wọ̀n ọdún méjì fún Arákùnrin Roman Gridasov, Arákùnrin  Gennadiy German, àti Arákùnrin Aleksey Miretskiy. Yàtọ̀ síyẹn, ilé ẹjọ́ sọ pé lẹ́yìn tí gbogbo wọn bá ṣẹ̀wọ̀n tán, wọn ò ní lé mú ipò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba èyíkéyìí fún odindi ọdún márùn-ún. Àwọn arákùnrin náà máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ yìí.

Ìgbà táwọn aláṣẹ ya wọ ilé méje táwọn Ẹlẹ́rìí ń gbé nílùú Saratov ní June 12, 2018 ni ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n fi ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kan àwọn arákùnrin mẹ́fà yìí. Gbogbo àwọn arákùnrin wọ̀nyí ló ní ìdílé, àmọ́ Arákùnrin Budenchuk ní tiẹ̀ ní ọmọ méjì tí wọ́n ṣì wà ní ilé ìwé. Arákùnrin Budenchuk, Arákùnrin Bazhenov àti Arákùnrin Makhammadiyev ti lo ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún kan látìmọ́lé lẹ́yìn tí wọ́n mú wọn kó tó wá di pé wọ́n gbọ́ ẹjọ́ wọn.

Nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ gbẹ̀yìn nílé ẹjọ́, àwọn arákùnrin mẹ́fà wọ̀nyí tọ́ka sí ọ̀pọ̀ àwọn ẹsẹ Bíbélì amóríyá tó sún wọn láti jẹ́ adúróṣinṣin, wọ́n sì fi kún un pé àwọn ò ní ẹ̀tanú èyíkéyìí sí ẹnikẹ́ni lára àwọn tó fẹ̀sùn kan àwọn.

Ní báyìí, ìjọba Rọ́ṣíà, ti dá àwọn arákùnrin wa méje lẹ́bi tí wọ́n sì ti jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Ó ju igba ó lé àádọ́ta (250) àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa ní Rọ́ṣíà tí wọ́n ti fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn. Àwọn mọ́kànlélógójì (41) wà ní àtìmọ́lé (ìyẹn àwọn tí wọ́n tì mọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ wọn tàbí àwọn tí wọ́n ti dá lẹ́bi tí wọ́n sì ti jù sẹ́wọ̀n), wọ́n ò sì gbá àwọn mẹ́tàlélógún (23) láyè láti jáde kúrò ní ilé wọn.

A gbàdúrà fún gbogbo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa olóòótọ́ àti onígboyà ní Rọ́ṣíà pé ‘kí agbára [Jèhófà] ológo fún [wọn] ní gbogbo agbára tí [wọn] nílò, kí [wọn] lè fara dà á ní kíkún pẹ̀lú sùúrù àti ìdùnnú.’​—Kólósè 1:11.