Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 21, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Wọ́n Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lóró Nílùú Surgut, Lórílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà

Wọ́n Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lóró Nílùú Surgut, Lórílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà

Ọjọ́ mẹ́sàn-án péré lẹ́yìn tí wọ́n dá Arákùnrin Dennis Christensen lẹ́bi nílé ẹjọ́ kan ní Rọ́ṣíà, ó kéré tán àwọn méje míì lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn agbófinró nílùú Surgut lágbègbè Siberia ti mú, tí wọ́n sì dá lóró. Lára ohun tí wọ́n ṣe fún wọn ni pé wọ́n fi iná mànàmáná gbé wọn, wọ́n fi ọ̀rá bo ojú wọn kí wọ́n má bàa ríbi mí dáadáa, lẹ́yìn náà ni wọ́n lù wọ́n nílùkulù. Bí wọ́n ṣe ń dá àwọn ará wa yìí lóró, bẹ́ẹ̀ làwọn agbófinró yẹn ń halẹ̀ mọ́ wọn pé kí wọ́n sọ ibi tí wọ́n ti ń pàdé pọ̀ àti orúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí míì.

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé ní àárọ̀ February 15, 2019 nígbà táwọn agbófinró fọ́n sígboro, tí wọ́n sì ń mú àwọn ará wa nílé wọn. Wọ́n kó wọn lọ sí ọ́fíìsì Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣèwádìí, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. Àmọ́ àwọn ará wa kọ̀ láti sọ orúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí míì àti ibi tí wọ́n ń gbé. Nígbà táwọn agbófinró náà rí i pé amòfin kan ṣoṣo tó wà níbẹ̀ ti lọ, ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dá àwọn ará wa lóró, tí wọ́n sì ṣe wọ́n bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú. Àwọn ará sọ ohun tí wọ́n ṣe fún wọn, wọ́n ní: àwọn agbófinró fi ọ̀rá bo ojú àwọn, wọ́n sì fi téèpù so ó pa, lẹ́yìn náà wọ́n so ọwọ́ wọn sẹ́yìn, wọ́n sì lù wọ́n nílùkulù. Nígbà tó yá, wọ́n bọ́ wọn sí ìhòòhò, wọ́n yí omi dà sí wọn lára, wọ́n wá fi iná mànàmáná gbé wọn. Ó dunni gan-an pé nǹkan bíi wákàtí méjì gbáko ni wọ́n fi hùwà ìkà burúkú yìí sáwọn ará wa.

Ó kéré tán, mẹ́ta nínú àwọn Ẹlẹ́rìí yìí ṣì wà lẹ́wọ̀n. Àwọn tí wọ́n dá sílẹ̀ ti lọ sílé ìwòsàn torí pé wọ́n ṣèṣe gan-an. Wọ́n sì ti gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sọ́dọ̀ àwọn àjọ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.

Ó yani lẹ́nu pé lẹ́yìn táwọn agbófinró ti fojú àwọn ará wa rí màbo, wọ́n tún wá fẹ̀sùn ọ̀daràn kan àwọn Ẹlẹ́rìí mọ́kàndínlógún (19), wọ́n sọ pé wọ́n ń “dara pọ̀ mọ́ àwọn agbawèrèmẹ́sìn,” àti pé wọ́n ń “ṣagbátẹrù àjọ tó ń ṣètìlẹ́yìn fáwọn agbawèrèmẹ́sìn.”

Lábẹ́ òfin ìjọba Rọ́ṣíà, wọ́n máa ń fìyà jẹ ẹni tó bá lo àṣẹ tó ní láti dá ẹlòmíì lóró. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ kí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tẹ̀ lé òfin tí àwọn àjọ àgbáyé gbé kalẹ̀ tó sọ pé kò yẹ kí ẹnikẹ́ni máa fi àṣẹ ìjọba dáni lóró. Torí náà, a máa lo gbogbo ẹ̀tọ́ tá a ní láti gbé ọ̀rọ̀ yìí lọ sí ilé ẹjọ́ ní Rọ́ṣíà, àá sì gbé e lọ sáwọn àjọ àgbáyé míì ká lè rí i dájú pé wọ́n dá ẹjọ́ àwọn ará wa bó ṣe tọ́.

Lékè gbogbo ẹ̀, a mọ̀ pé Jèhófà ń rí bí wọ́n ṣe ń fojú pọ́n àwọn ará wa ní Rọ́ṣíà, ó sì máa gbé ìgbésẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ‘olùrànlọ́wọ́ àti olùgbàlà wọn.’​—Sáàmù 70:5.