Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ilé ẹjọ́ Kaluga Regional Court ní Rọ́ṣíà

OCTOBER 16, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Sọ Pé Adájọ́ Kan Nílẹ̀ Rọ́ṣíà Kò Gbọ́ Ẹjọ́ Arákùnrin Kuzin Lọ́nà Tó Bófin Mu

Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Sọ Pé Adájọ́ Kan Nílẹ̀ Rọ́ṣíà Kò Gbọ́ Ẹjọ́ Arákùnrin Kuzin Lọ́nà Tó Bófin Mu

Ní September 9, 2019, Adájọ́ Svetlana Anatolyevna Prokofyeva ti ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó ń jẹ́ Kaluga Regional Appeals Court sọ pé ilé ẹjọ́ agbègbè Kaluga, ìyẹn Kaluga District Court tẹ òfin lójú nígbà tó dájọ́ pé kí wọn fi arákùnrin  Dmitriy Kuzin sí àhámọ́ láì tíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀.

Ìdájọ́ tí Adájọ́ Prokofyeva ṣe yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an ni, torí pé ó ṣọ̀wọ́n kí adájọ́ kan gbà pé ilé ẹjọ́ fi ẹ̀tọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dù wọ́n lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Adájọ́ yìí bẹnu àtẹ́ lu ilé ẹjọ́ agbègbè náà fún bí wọn ṣe tẹ òfin lójú láìmọye ìgbà bí wọ́n ṣe ń gbọ́ ẹjọ́ náà. Wọ́n rí i pé ilé ẹjọ́ agbègbè náà fi Arákùnrin Kuzin ṣe ẹlẹ́yà nítorí ohun tó gbà gbọ́, wọn ò sì jẹ́ kó gbèjà ara rẹ̀ bó ṣe yẹ. Adájọ́ Prokofyeva tún sọ nínú ìdájọ́ rẹ̀ pé “kò ṣeéṣe láti sọ pé alága ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ náà jẹ́ aláìṣègbè.”

Arákùnrin  Dmitriy Kuzin àti ìyàwó rẹ̀ Svetlana, ní ọjọ́ ìgbeyàwó wọn ní ọdún 2013

Wọ́n mú Arákùnrin Kuzin ní June 26, 2019, nígbà tí àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ FSB tó wà ní Kaluga gbọn ilé rẹ̀ yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́. Lọ́jọ́ méjì lẹ́yìn náà, ilé ẹjọ́ agbègbè Kaluga dájọ́ pé kí wọ́n fi Arákùnrin  Kuzin sí àhámọ́ oṣù méjì láì tíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Ní August 19, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ agbègbè yìí tún béèrè pé kí ilé ẹjọ́ sún ìgbà tí Arákùnrin Kuzin á fi wà ní àhámọ́ ṣáájú ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ fún oṣù méjì míì. Ilé ẹjọ́ sì fọwọ́ sí ohun tí wọn béèrè fún yìí.

Arákùnrin Kuzin gbé ẹjọ́ náà lọ sí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, Adájọ́ Prokofyeva ló sì dá ẹjọ́ náà. Nítorí pé adájọ́ yìí rí i pé adájọ́ ilé ẹjọ́ kékeré tẹ òfin lójú, ó pàṣẹ pé kí wọ́n gbé ẹjọ́ Arákùnrin Kuzin pa dà sí ilé ẹjọ́ kékeré náà, kí ẹlòmíì míì sì tún ẹjọ́ náà gbọ́ níbẹ̀. Àmọ́, ní September 23, ilé ẹjọ́ agbègbè yìí lábẹ́ alága míì tún sọ pé kí Arákùnrin Kuzin ṣì tún wà ní àhámọ́ fún oṣù méjì míì.

Ó dá wa lójú pé Jèhófà, Ọlọ́run olóòótọ́ àti olódodo á máa bójú tó àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa tó wà ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà bí wọ́n ṣe ń gbẹ́kẹ̀ lé e.​—Diutarónómì 32:4, 9-11.