Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ọ̀mọ̀wé Sergey Igorevich Ivanenko, onímọ̀ nípa ẹ̀sìn àti olùdámọ̀ràn fún ìjọba Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà

OCTOBER 18, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Gbajúgbajà Onímọ̀ Nípa Ẹ̀sìn Jẹ́rìí Gbe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ìlú Saratov

Gbajúgbajà Onímọ̀ Nípa Ẹ̀sìn Jẹ́rìí Gbe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ìlú Saratov

Ní September 4, 2019, nígbà tí wọ́n ń gbẹ́jọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́fà ní ìlú Saratov, wọ́n ní kí onímọ̀ nípa ẹ̀sìn táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó àti olùdámọ̀ràn fún ìjọba Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà, Sergey Igorevich Ivanenko, wá sọ ohun tó mọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níwájú ilé ẹjọ́. Ọ̀mọ̀wé Ivanenko ló ṣe ìwé méjì tó wúlò fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ èyí tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ohun tá a kọ síbí yìí ni ẹ̀rí tó jẹ́ níwájú ilé ẹjọ́:

Ìgbésí ayé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ìjọsìn wọn. “Ohun kan tó mú káwọn Ẹlẹ́rìí yàtọ̀ gédégbé ni pé: Wọn kì í tẹ̀ lé òfin gbòógì kankan tàbí ohun tí aṣáájú kan pàtó bá pa láṣẹ, ṣe ni wọ́n máa ń gbìyànjú láti ran ara wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ẹ̀rí ọkàn tí wọ́n fi Bíbélì kọ́, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sì lè dá ṣe ìpinnu tó bá Bíbélì mu.

“Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé ohun tó wà nínú Bíbélì, ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà tí Jésù Kristi àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbé kalẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni.

“Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe ohun tí wọ́n jọ gbà gbọ́, ìyẹn kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, dídáhùn àwọn ìbéèrè nípa Bíbélì àti kíkọ orin tó bá Bíbélì mu, jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sapá gidigidi láti ṣe gbogbo nǹkan lọ́nà tó bá Bíbélì mu.

“Wọ́n tún gbà pé ìpàdé ìjọ wà lára ohun tí Kristẹni kan gbọ́dọ̀ máa pésẹ̀ sí. Láwọn ìpàdé náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe àyẹ̀wò Májẹ̀mú Tuntun, ohun tó sọ nípa Jésù Kristi àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ àti ìgbà tí ìjọ Kristẹni ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. . . . Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé àwọn gbọ́dọ̀ máa sin Ọlọ́run pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ.

“Wọ́n máa ń tẹnu mọ́ ọn pé ohun tá a fi ń dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi mọ̀ ni ìfẹ́ tí wọ́n ní láàárín ara wọn.”

Iṣẹ́ ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. “A tún ń fi iṣẹ́ ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá wọn mọ̀. Mo lérò pé kò sẹ́ni tó ń wàásù bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò sì sẹ́ni tó ní ìtara tó wọn. Gbogbo wọn gbọ́dọ̀ wàásù kí wọ́n sì lo àkókò díẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

“Wọ́n sábà máa ń sọ pé, ‘Ohun tí Bíbélì sọ nìyí.’ Ẹnì kan lè ṣí Bíbélì kí òun fúnra rẹ̀ sì yẹ̀ ẹ́ wò. Bó bá fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ, á dara pọ̀ mọ́ wọn. Bí kò bá sì fara mọ́ ọn, kò ní dara pọ̀ mọ́ wọn. Wọ́n kì í fipá múni.”

Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn. “Ohun tó mú kí ìjọba kọ́kọ́ sọ pé agbawèrèmẹ́sìn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni pé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé àwọn ìwé wọn kan sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ló ń ṣe ìsìn tòótọ́ àti pé àwọn ìsìn tó kù jẹ́ ìsìn èké. Àwọn ẹlẹ́sìn míì náà máa ń sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n fẹ̀sùn kan nínú ẹjọ́ tó wà nílẹ̀ yìí. Wọ́n ka ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé ìsìn àwọn nìkan ni ìsìn tòótọ́ àti pé àwọn ìsìn tó kù jẹ́ èké sí ìpolongo ẹ̀tàn.

“Lójú tèmí gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa ẹ̀sìn, [ìpinnu ti ilé ẹjọ́ ṣe yìí] ò tọ̀nà, torí pé béèyàn bá yàn láti wádìí ọ̀rọ̀ náà wò, kò sí ẹlẹ́sìn tí ò ní sọ pé tòun ni ìsìn tòótọ́, ìsìn èké làwọn tó kù tàbí pé wọ́n ti ṣì wọ́n lọ́nà.

“Gbogbo ẹlẹ́sìn ló máa ń sọ pé tiwọn nìkan ni ìsìn tòótọ́, tí wọ́n á sì ka àwọn ẹ̀sìn tó kù sí ẹ̀sìn èké tàbí èyí tí kò fi taratara jóòótọ́. Bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn àfi bí wọ́n bá máa ṣe àgàbàgebè ló kù.

“Àmọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sapá nígbà gbogbo láti pa òfin ìjọba mọ́ bí kò bá ti forí gbárí pẹ̀lú òfin Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń gbọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá pọ́ọ̀sì tí wọ́n rí he pa dà, wọ́n sì sanwó ìtanràn tàbí owó orí bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè ṣàì ṣe bẹ́ẹ̀. Ìpinnu àtọkànwá lèyí jẹ́ mi ò sì ní fi ẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn tó wulẹ̀ ń díbọ́n.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Lo Bíbélì. “Ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni pé wọ́n máa ń lo onírúurú ìtumọ̀ Bíbélì fún ìkẹ́kọ̀ọ́ àti lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wọn. Wọ́n rí i bí ohun tó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n mú káwọn èèyàn ní Bíbélì ní oríṣiríṣi èdè. Wọn ò dà bí àwọn ẹlẹ́sìn yòókù torí pé wọ́n pọkàn pọ̀ sórí Bíbélì. Àwọn aláṣẹ ka ìtumọ̀ Bíbélì wọn sí ìwé àwọn agbawèrèmẹ́sìn . . . Bóyá àwọn tó ṣe ìpinnu yẹn rò pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fẹ́ràn Bíbélì wọn jù àti pé wọ́n á ṣíwọ́ iṣẹ́ ìwàásù tí wọn ò bá jẹ́ kí wọ́n lo Bíbélì yẹn mọ́. Àṣìrò nìyẹn jẹ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò fọwọ́ rọ́ ìtumọ̀ Bíbélì kankan sẹ́yìn.”

Lílo àjọ tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lábẹ́ òfin. “Ìpinnu Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà fi hàn pé. . . èyí tó pọ̀ jù nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ní àjọ tó ń bójú tó iṣẹ́ wọn lábẹ́ òfin . . . Torí náà, kò tọ̀nà láti sọ pé olúkúlùkù Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní agbègbè pàtó kan gbọ́dọ̀ jẹ́ ara àjọ tó ń bójú tó iṣẹ́ wọn lábẹ́ òfin.

“Ní ti àwọn àjọ tó ń bójú tó iṣẹ́ wọn lábẹ́ òfin . . . , mo fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìwé òfin tí wọ́n fi dá wọn sílẹ̀, wọn ò dárúkọ alábòójútó, alàgbà, aṣáájú-ọ̀nà; irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ò sí níbẹ̀. Orúkọ àwọn olùdásílẹ̀ àjọ náà ló máa ń wà níbẹ̀, àwùjọ kéréje tí kì í ju nǹkan bí èèyàn mẹ́wàá lọ. Àwọn tí orúkọ wọn ò sí nínú ìwé yẹn kọ́ ló ń ṣojú fún òfin, ohun tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n ń bójú tó. . . . Ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ò sì yàtọ̀ síra láìka orílẹ̀-èdè tàbí ẹkùn ìpínlẹ̀ tí wọ́n wà sí.

“Ṣe ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbìyànjú láti fara mọ́ [ìpinnu Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ tó fi òfin de àjọ tó ń bójú tó iṣẹ́ wọn lábẹ́ òfin yìí] kí wọ́n má bàa ta ko ìpinnu Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ náà délẹ̀délẹ̀. Torí náà, wọ́n ń bá iṣẹ́ wọn nìṣó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn tí àwọn aláṣẹ ò fi òfin dè. Wọ́n ń bá iṣẹ́ wọn lọ bí olùjọsìn tó wà láyè ara ẹ̀. Lójú wọn àti bí ìwádìí nípa ẹ̀sìn ṣe fi hàn, iṣẹ́ wọn ò ta ko ìpinnu Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ.”

Ojú tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo gbígba ẹ̀jẹ̀. “Bíbélì sọ pé ‘inú ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí wà’; torí náà ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀. Ọ̀rọ̀ nípa irú oúnjẹ téèyàn ò gbọ́dọ̀ jẹ ni ibí yìí ń sọ, amọ́ wọ́n mú kí ìtumọ̀ rẹ̀ túbọ̀ gbòòrò. Wọ́n gbà pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ní ọ̀nà èyíkéyìí, yálà nínú oúnjẹ (wọn kì í jẹ sọ́séèjì tí wọ́n po ẹ̀jẹ̀ mọ́) tàbí nípa gbígbà á sára. Ṣùgbọ́n, wọ́n máa ń lo àwọn ìpín kékeré látara èròjà ẹ̀jẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ìyẹn . . . Kì í ṣe pé wọ́n fẹ́ kú ni wọ́n ṣe ń sọ pé àwọn ò gbẹ̀jẹ̀, ṣe ni wọ́n fẹ́ ìtọ́jú tó péye àti àbójútó ìṣègùn tó dáa. Wọ́n mọ̀, àwọn oníṣègùn náà sì gbà pé ìgbẹ̀jẹ̀sára léwu torí pé ẹni tó gbẹ̀jẹ̀ sára lè kó àrùn Éèdì tàbí irú àrùn míì. Iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ ló fọkàn ẹni balẹ̀ jù, mo sì ti rí i nígbà tí mo ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ ìṣirò pé àwọn ọlọ́rọ̀ kì í sábà fẹ́ láti gbẹ̀jẹ̀ torí pé ìyẹn ni ò ní jẹ́ kí wọ́n kó àrùn tàbí kí wọ́n ní ìṣòro.”

Ojú tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo ọrẹ. “Ẹnì kan lè pinnu pé òun ò ní fi owó ṣètọrẹ. Ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó má sì dá kọ́bọ̀. Ọwọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan ló kù sí láti pinnu bóyá òun á fi owó ṣètọrẹ tàbí òun ò ní ṣe bẹ́ẹ̀.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀mọ̀wé Ivanenko fi ìdánilójú jẹ́rìí sí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe arúfin, wọ́n sì máa ń pa òfin mọ́, ilé ẹjọ́ kó àlàyé rẹ dà nù wọ́n sì ní kí àwọn arákùnrin mẹ́fẹ̀ẹ̀fà lọ lògbà tó yàtọ̀ síra lẹ́wọ̀n.

Bí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe ń bá a nìṣo láti máa fi ẹ̀sùn èké kan àwọn ará wa tí wọ́n sì ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n láìtọ́, a ò ní yé gbàdúrà pé kí Jèhófà máa rọ̀jò ibùkún rẹ̀ sórí àwọn ará wa tí wọ́n jẹ́ onígboyà àti olóòótọ́ kí inú wọn lè máa dùn pé àwọn ní ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀.—Sáàmù 109:2-4, 28.