Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Andrzej Oniszczuk wà nínú àhámọ́ kótópó ní kóòtù lásìkò tí wọ́n ń ṣe ẹjọ́ rẹ̀ tí wọ́n fi sún ìgbà tó fi máa wà látìmọ́lé síwájú

AUGUST 9, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ó Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Tó Ọdún Kan Tí Arákùnrin Andrzej Oniszczuk Ti Wà Látìmọ́lé

Ó Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Tó Ọdún Kan Tí Arákùnrin Andrzej Oniszczuk Ti Wà Látìmọ́lé

Láti October 9, 2018 táwọn agbófinró ti mú Anrzej Oniszczuk, tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Poland àti arákùnrin kan, wọn ò tíì gbọ́ ẹjọ́ wọn títí di báyìí. Ẹ̀karùn-ún rèé tí wọ́n máa sún àkókò tó fi wà látìmọ́lé síwájú. October 2 ni wọ́n ṣètò pé kó parí àtìmọ́lé rẹ̀, ìyẹn ọjọ́ díẹ̀ kó pé ọdún kan tó ti wà ní àhámọ́.

Arákùnrin Andrzej àti ìyàwó rẹ̀ Anna, ṣáájú kí wọ́n tó mú un lọ sí àtìmọ́lé. Wọn ò gba Anna láyè láti rí ọkọ rẹ̀ láti oṣù mẹ́wàá sẹ́yìn

Àtìmọ́lé ni Andrzej wà látìgbà tí wọ́n ti mú un. Orí ìdúró ló máa ń wà láti aago mẹ́fà àárọ̀ títí di aago mẹ́sàn-án alẹ́. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ ni wọ́n fàyè gbà á láti fi omi tó ń lọ́ wọ́ọ́rọ́ wẹ̀ fún ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Fún oṣù mẹ́wàá tó fi wà láhàámọ́, wọn ò jẹ́ kí Anna ìyàwó rẹ̀ rí i. Lẹ́tà ni wọ́n fi ń bára wọn sọ̀rọ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Anna ti kọ̀wé sí àwọn aláṣẹ pé kí wọ́n gbà á láyè láti rí ọkọ rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn ò dá a lóhùn.

Bá a ṣe sọ ṣáájú, ìgbà tí àwọn ọlọ́pàá àtàwọn ológun tó fi nǹkan bojú fipá ya wọ ilé Andrzej àtàwọn méjìdínlógún (18) míì nílùú Kirov ni wọ́n mú un. Wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn àn torí ó ń kọrin ìjọba Ọlọ́run, ó sì tún ń ka ìtẹ̀jáde wa.

Lọ́dún tó kọjá, wọ́n mú Andrzej àtàwọn arákùnrin mẹ́rin míì nílùú Kirov (ìyẹn, Maksim Khalturin, ẹni ọdún mẹ́rìnlélógójì (44), Vladimir Korobeynikov, ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rin (66), Andrey Suvorkov, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) àti Evgeniy Suvorkov, ẹni ọdún mọ́kànlélógójì (41) sátìmọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ wọn. Àtìgbà yẹn ni wọ́n ti ní wọn ò gbọdọ̀ jáde nílé. Ní báyìí, ẹjọ́ Andrzej àti tàwọn arákùnrin mẹ́rin yẹn ti wà ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù.

Lọ́dún yìí, ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tún ti fẹ̀sùn ọ̀daràn kan àwọn arákùnrin méje míì ní Kirov, Yevgeniy Udintsev tó jẹ́ ẹni àádọ́rin ọdún (70) ló dàgbà jù. Ní báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń kojú ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn ní Kirov nítorí ìgbàgbọ́ wọn ti di méjìlá (12).

Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí Andrzej, Anna àtàwọn ará wa ọwọ̀n tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ń rán wa létí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, tó sọ pé: “Ẹ máa rántí àwọn tó wà nínú ẹ̀wọ̀n, bí ẹni pé ẹ jọ wà lẹ́wọ̀n àti àwọn tí wọ́n ń fìyà jẹ, torí pé ẹ̀yin fúnra yín náà wà nínú ara.”​—⁠Hébérù 13:3.