Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Dmitriy Mikhaylov rèé nígbà tí wọ́n ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fàṣẹ ọba mú un ní May 29, 2018, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ lo oṣù mẹ́fà lẹ́wọ̀n

JUNE 18, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ìgbìmọ̀ Àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n Ti Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáye Sọ Pé Kò Bófin Mu Bí Ìjọba Rọ́ṣíà Ṣe Fi Arákùnrin Mikhaylov Sẹ́wọ̀n

Ìgbìmọ̀ Àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n Ti Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáye Sọ Pé Kò Bófin Mu Bí Ìjọba Rọ́ṣíà Ṣe Fi Arákùnrin Mikhaylov Sẹ́wọ̀n

Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n lórí ọ̀rọ̀ òfin ti àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé ti sọ pé bí ìjọba Rọ́ṣíà ṣe fàṣẹ ọba mú Arákùnrin Dmitriy Mikhaylov tí wọ́n sì fi í sẹ́wọ̀n “nítorí ohun tó gbà gbọ́ fi hàn pé wọ́n hùwà àìtọ́ sí i,” wọ́n sì ti tẹ òfin àpapọ̀ àwọn ìjọba lójú. Àwùjọ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n náà tún rọ ìjọba Rọ́ṣíà pé wọn ò gbọ́dọ̀ fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn èyíkéyìí kan Arákùnrin Mikhaylov mọ́.

Ó tó ojú ìwé méjìlá tí ìgbìmọ̀ tí wọ́n ń pè ní Working Group on Arbitrary Detention (WGAD) fi kọ èrò wọn nípa Arákùnrin Mikhaylov, wọ́n sọ pé “kò sígbà tó ṣe ohun tó dí àlàáfíà ìlú lọ́wọ́.” Yàtọ̀ síyẹn, “kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé òun tàbí Ẹlẹ́rìí Jèhófà èyíkéyìí lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà jẹ́ oníwà ipá, wọn kì í sì í rọ àwọn míì pé kí wọ́n hùwà ipá.”

Ìgbìmọ̀ WGAD wá pinnu pé ńṣe ni Arákùnrin Mikhaylov “kàn lo ẹ̀tọ́ tó ní láti ṣe ìsìn tó wù ú” kò sì “yẹ kí wọ́n fàṣẹ ọba mú un débi tí wọ́n á fi jù ú sí àhámọ́ láìgbọ́ ẹjọ́ ẹ̀.” Nítorí náà, ó yẹ kí ìjọba san owó ìtanràn fún un torí pé kò ráyè ṣiṣẹ́ ní gbogbo àkókò tó fi wà lẹ́wọ̀n, àti pé wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n láì jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.

Ìgbìmọ̀ WGAD tún kíyè sí i pé kì í ṣe Arákùnrin Mikhaylov nìkan ni wọ́n ń fìyà jẹ nítorí ohun tó gbà gbọ́. Òun náà jẹ́ “ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tí wọ́n fàṣẹ ọba mú, tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n, tí wọ́n sì ti fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn nítorí pé wọ́n ń lo ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti ṣe ìsìn tó wù wọ́n,” ó sì jẹ́ ẹ̀tọ́ tí òfin àpapọ̀ àwọn ìjọba fọwọ́ sí. Torí náà, ìgbìmọ̀ WGAD jẹ́ kó ṣe kedere pé kì í ṣe Arákùnrin Mikhaylov nìkan lọ̀rọ̀ yìí kàn, ó tún kan bí wọ́n ṣe ń fi gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n láìtọ́ “lọ́nà tó jọ ti Ọ̀gbẹ́ni Mikhaylov.”

Ọ̀dọ́ ni Arákùnrin Mikhaylov nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣèrìbọmi nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) lọ́dún 1993. Lọ́dún 2003, ó fẹ́ Yelena, àwọn méjèèjì sì jọ ń sin Jèhófà.

Lọ́dún 2018, Arákùnrin àti Arábìnrin Mikhaylov kíyè sí i pé fún ọ̀pọ̀ oṣù làwọn aláṣẹ ti ń ṣọ́ wọn ni ti pé wọ́n ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ wọn lórí fóònù, wọ́n sì tọ́jú kámẹ́rà sílé wọn. Ní April 19, 2018, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣèwádìí ní Àgbègbè Ivanovo Lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kan Arákùnrin Mikhaylov, làwọn ọlọ́pàá tó dira ogun bá lọ tú ilé rẹ̀ yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́. Kò ju oṣù kan lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n fàṣẹ ọba mú un wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n, wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó ń fi owó ṣètìlẹ́yìn fáwọn “agbawèrèmẹ́sìn.” Wọ́n tú u sílẹ̀ lẹ́yìn tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lo oṣù mẹ́fà lẹ́wọ̀n. Torí pé ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ lórí ẹjọ́ rẹ̀, àwọn aláṣẹ ò jẹ́ kó rìnrìn-àjò, wọ́n sì ń ṣọ́ ọ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ bó ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀.

Oṣù mẹ́fà ni ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ní láti fèsì lórí ìpinnu tí ìgbìmọ̀ WGAD ṣe, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìgbìmọ̀ náà mọ̀ bóyá ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kan Mikhaylov ti parí, bóyá wọ́n ti san owó ìtanràn fún un, bóyá wọ́n sì ti ṣèwádìí nípa àwọn tó fìyà jẹ ẹ́ láìṣẹ̀.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìpinnu tí ìgbìmọ̀ WGAD ṣe yìí ló mú kí ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan dá Arákùnrin Teymur Akhmedov sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Lọ́dún 2017, wọ́n fàṣẹ ọba mú un, wọ́n sì rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún torí pé ó ń sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì láìfi dí àlàáfíà ìlú lọ́wọ́. Gbogbo ilé ẹjọ́ tó wà ní Kazakhstan ni wọ́n gbé ẹjọ́ náà lọ, àmọ́ kò lójú, ni agbẹjọ́rò Arákùnrin Akhmedov bá gbé ẹjọ́ náà lọ sọ́dọ̀ ìgbìmọ̀ WGAD. Nínú ìpinnu tí ìgbìmọ̀ WGAD ṣe ní October 2, 2017, wọ́n ní ìwà tí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Kazakhstan hù kò dáa, wọ́n sì ní kí wọ́n tú Arákùnrin Akhmedov sílẹ̀. Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà, ààrẹ orílẹ̀-èdè Kazakhstan wá sọ ọ́ ní gbangba pé Arákùnrin Akhmedov kì í ṣe ọ̀daràn. Ní April 4, 2018, wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n.

Yálà orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà máa ṣe ohun tí ìgbìmọ̀ WGAD ní kí wọ́n ṣe fún Arákùnrin Mikhaylov tàbí wọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn wa balẹ̀ torí Bíbélì sọ pé: “Aláyọ̀ ni ọkùnrin tí ó fi [Jèhófà] ṣe ibi ààbò.” Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa bójú tó àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n ń fi ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn ní Rọ́ṣíà, kí wọ́n lè rí i pé gbogbo ẹni tó bá nígboyà tó sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kò ní “ṣaláìní ohun rere.”​—⁠Sáàmù 34:​8, 10.