Yorùbá
Ìjì Líle Ṣọṣẹ́ ni Gúúsù Ìpínlẹ̀ California
/assets/ct/79e1b14fff/images/syn_placeholder_sqr.png

FEBRUARY 1, 2018
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Ìjì Líle Ṣọṣẹ́ ni Gúúsù Ìpínlẹ̀ California

Ìjì Líle Ṣọṣẹ́ ni Gúúsù Ìpínlẹ̀ California

Ní January 9 lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìjì líle kan jà ní gúúsù ìpínlẹ̀ California. Ìjì yẹn ló fa ọ̀gbàrá púpọ̀ gan-an tó sì han àwọn ará ìlú léèmọ̀. Ìròyìn jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn mọ́kànlélógún [21] ló pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yẹn, ọ̀pọ̀ ilé ló wó, àwọn míì sì bàjẹ́.

Kò sí ọ̀kankan nínú àwọn ará wa tó kú sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Àmọ́ ní ìlú Burbank, ìjì yẹn ba ilé àtàwọn nǹkan ìní akéde kan jẹ́. Bákan náà, ní ìlú Ventura ìdílé mẹ́jọ ló ti sá kúrò nílé. Gbọ̀ngàn Ìjọba kankan kò bàjẹ́.

Àwọn Alábòójútó àyíká pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù àti àwọn aṣojú láti Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá. Ní irú àsìkò tí nǹkan nira yìí, àá máa báa lọ láti rántí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nínú àwọn àdúrà wa, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa fún wọn lókun tí wọ́n nílò.​—1 Pétérù 5:10.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Orílé Iṣẹ́: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000