APRIL 2, 2019
KAZAKHSTAN
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kazakhstan Pe Àwọn Èèyàn Wá Ṣèbẹ̀wò Sáwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba
Bẹ̀rẹ̀ láti May 11 sí November 10, 2018, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kazakhstan pe àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá ṣèbẹ̀wò sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Lára àwọn tó tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà ni àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn akọ̀ròyìn, àwọn ọ̀mọ̀wé àtàwọn míì, ètò yìí sì jẹ́ kí gbogbo wọn mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lápapọ̀, àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ (1,500) ló lọ.
Àwọn ìlú tí Gbọ̀ngàn Ìjọba náà wà: (1) Öskemen, (2) Qaraghandy, (3) Qostanay, (4) Semey, (5) Shymkent, (6) Taldyqorghan àti (7) Taraz.
Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ni wọ́n ṣètò pé káwọn èèyàn náà wá, àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba náà sì wà ní ìlú méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ìyẹn ní ìlú Öskemen, Qaraghandy, Qostanay, Semey, Shymkent, Taldyqorghan àti Taraz. Àwọn tó wá síbẹ̀ rí àwọn nǹkan tó jẹ́ kí wọ́n mọ púpọ̀ sí i nípa ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kazakhstan, èyí tó ti bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1892. Wọ́n tún rí àwọn nǹkan tó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa ohun tá à ń gbé ṣe lóde òní, irú bíi Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a mú jáde lédè Kazakh lọ́dún 2014.
Arákùnrin Bekzat Smagulov tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òfin àti Ẹ̀ka Tó Ń Gbéròyìn Jáde ní ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Kazakhstan sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà láti wá ṣèbẹ̀wò, ìyẹn sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ irú ẹni tá a jẹ́ gan-an. Lára àwọn tó wá síbẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́ láti Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn lórílẹ̀-èdè Kazakhstan, àtàwọn akọ̀ròyìn láti ilé iṣẹ́ oníròyìn Kazakhstan-Öskemen, títí kan aṣojú láti ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn Rudnyi Altai àti Semei Vesti.”
Ẹnì kan tó jẹ́ olórí ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn ní àgbègbè kan, pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ méjì míì láti ẹ̀ka yẹn wà lára àwọn tó wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní ìlú Taldyqorghan. A tún rí ẹnì kan tó jẹ́ olóòtú ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn Zhetysu Dialog, nígbà tó yá, ẹni yìí gbé àpilẹ̀kọ kan jáde nínú ìwé ìròyìn níbi tó ti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún àwọn kan tó yọ̀ǹda ara wọn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba náà.
Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará wa tún pín Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé lọ́gọ́ta (560) fáwọn èèyàn ní èdè Kazakh àti Russian, àwọn èdè tí wọ́n ń sọ jù ní Kazakhstan. Inú wa dùn pé gbogbo nǹkan lọ bó ṣe yẹ, èyí sì mú ìyìn bá orúkọ Jèhófà, ó tún jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa “àwọn iṣẹ́ rere” wa.—Mátíù 5:16.
Ní ìlú Qaraghandy, Arábìnrin Saniya Akhmetzhanova ń fi èdè adití bá tọkọtaya kan tó wá ṣèbẹ̀wò sí Gbọ̀ngàn Ìjọba sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe máa ń kọ́ àwọn adití lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Àwọn ọmọ méjì ń wo fídíò Dáàbò Bo Ọmọ Rẹ lédè Russian ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nílùú Qaraghandy.
Arákùnrin Lev Gladyshev ń sọ ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kazakhstan fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní ìlú Qaraghandy, kódà Kudaibergen Beksultanov tó jẹ́ akọ̀wé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìlú yẹn náà wà níbẹ̀; Nikolay Sarsenbayev tó jẹ́ ọ̀gá ní ẹ̀ka kan tó ń ṣèwádìí lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn náà wà níbẹ̀; àti Nurlan Bikenov tó jẹ́ ọ̀gá ní Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn ní ìlú Qaraghandy.
Arábìnrin Aisha Yakovleva ń ṣàlàyé àwọn nǹkan tó wà lórí ètò ìṣiṣẹ́ JW Library® fún tọkọtaya kan tó wá ṣèbẹ̀wò sí Gbọ̀ngàn Ìjọba ní ìlú Taldyqorghan.
Arákùnrin Aleksey Alyoshin ń ṣàlàyé fáwọn tó wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní ìlú Taraz pé orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú àwọn ìwé àtàwọn nǹkan míì tó ti wà tipẹ́tipẹ́.
Ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní ìlú Öskemen, Arákùnrin Sergey Petkevich mú Ilé Ìṣọ́ kan tó ti pẹ́ dání, èdè Russian ni wọ́n sì fi kọ ọ́, ó fi ń ṣàlàyé ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kazakhstan fáwọn tó wà níbẹ̀. Lára àwọn tó wá síbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn ni Sergey Lebedev tó jẹ́ olórí nínú ẹgbẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní Edinstvo.
Arákùnrin Georgiy Pismenoy (lápá ọ̀tún) ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan tó wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní ìlú Qostanay. Àwọn tó wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba yẹn wo fídíò kan tó ti wà láti ọdún 1982, ìjọba fòfin de ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, wọ́n sì rí bí wọ́n ṣe ń dájọ́ fún arákùnrin mẹ́ta àti arábìnrin kan ní ìlú Qostanay torí pé wọ́n ní àwọn ìtẹ̀jáde wa lọ́wọ́, wọ́n ń tẹ̀ ẹ́ jáde, wọ́n sì ń pín in fáwọn èèyàn. Arákùnrin Pismenoy wà lára àwọn arákùnrin mẹ́ta tí wọ́n rán lọ sẹ́wọ̀n ọdún méjì àtààbọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Arákùnrin náà ń sọ ìrírí rẹ̀ nígbà tó wà lẹ́wọ̀n fáwọn tó wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba yẹn.
Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní ìlú Shymkent, wọ́n ń fi orin kí àwọn tó wá káàbọ̀, kódà wọ́n ń lo ohun ìkọrin tí wọ́n ń pè ní dombra lédè Kazakh (ẹni tó kángun sí apá ọ̀tún àti òsì).
Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní ìlú Qaraghandy.

