Yorùbá
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Túbọ̀ Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Lẹ́yìn Ìjì Líle Tó Jà
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/702018100/univ/art/702018100_univ_sqr_xl.jpg

Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní Tortola rèé, kí wọ́n tó tún un ṣe àti lẹ́yìn tí wọ́n tún un ṣe. Ó wà lára Gbọ̀ngàn Ìjọba márùn-ún tí ìjì Hurricane Maria bà jẹ ní erékùṣù British àti U.S. Virgin, òun sì ni wọ́n kọ́kọ́ tún ṣe.

JANUARY 19, 2018
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Túbọ̀ Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Lẹ́yìn Ìjì Líle Tó Jà

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Túbọ̀ Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Lẹ́yìn Ìjì Líle Tó Jà

NEW YORK​—Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣètò ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá lẹ́yìn tí ìjì líle tí wọ́n ń pè ní Hurricane Irma àti Hurricane Maria jà ní September 2017, tó sì ṣọṣẹ́ gidigidi ní àgbègbè Caribbean àtàwọn àgbègbè tó yí i ká. Ìròyìn tá a gbọ́ látọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní orílẹ̀-èdè Barbados, Cuba, Dominican Republic, Faransé àti ilẹ̀ Amẹ́ríkà jẹ́ ká mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí àwọn ará wa ṣe ń ṣèrànwọ́.

Àwọn Àgbègbè Tí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Barbados Ń Bójú Tó—Anguilla, Antigua àti Barbuda, Dominica, pẹ̀lú St. Maarten (ti Dutch)

Ìgbìmọ̀ mẹ́ta tó ń ṣètò ìrànwọ́, títí kan ìgbìmọ̀ kan tó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà nílẹ̀ Faransé, jọ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti ṣètò àwọn ará tó wà láwọn àgbègbè yìí ní àwùjọ-àwùjọ kí wọ́n lè bójú tó àwọn ohun pàtàkì táwọn tí ìjì náà ṣèpalára fún máa nílò ní kánjúkánjú. Àwọn ilé tá a ṣètò pé a máa tún kọ́ láwọn àgbègbè tí ẹ̀ka ọ́fíìsì Barbados ń bójú tó máa ná wa ní iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù méjì ààbọ̀ owó dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ara ohun tá a máa fi owó yìí ṣe ni pé a máa fi tún Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́jọ ṣe, pẹ̀lú ilé àwọn ará wa tí wọ́n jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà [122]. Ilé mọ́kàndínlógún [19] míì tiẹ̀ wà tá a máa tún kọ́ látòkèdélẹ̀.

Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní Grand Bay, lórílẹ̀-èdè Dominica, tí ìjì Hurricane Maria bà jẹ́ gan-an.

Àgbègbè Tí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Cuba Ń Bójú Tó

Ìròyìn tá a gbọ́ látọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì ni pé àwọn akéde tí ìjì líle Hurricane Irma ṣèpalára fún ti ń rí ìrànwọ́ tó péye gbà. Lára ohun tí wọ́n ń ṣe fáwọn akéde yìí ni pé àwọn aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì máa ń lọ bẹ̀ wọ́n wò.

Àgbègbè Tí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Dominican Republic Ń Bójú Tó

Ìgbìmọ̀ mẹ́ta tó ń ṣètò ìrànwọ́ rí i pé àwọn ṣèrànwọ́ fáwọn akéde mẹ́tàdínlọ́gọ́ta [57] tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí. Àwọn ará lágbègbè yẹn gbé oúnjẹ, omi, aṣọ àtàwọn nǹkan èlò míì wá. Nígbà tí oṣù October fi máa parí, wọ́n ti tún gbogbo ilé tó bà jẹ́ ṣe, wọ́n sì ti palẹ̀ gbogbo ìdọ̀tí ibẹ̀ mọ́. Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn lágbègbè yẹn ló ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú iṣẹ́ náà.

Àwọn Àgbègbè Tí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Ilẹ̀ Faransé Ń Bójú Tó​—Guadeloupe àti St. Martin

Ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣètò ìgbìmọ̀ kan sí erékùṣù St. Martin, wọ́n tún ṣètò ibì kan tí ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ máa wà ní erékùṣù Guadeloupe, kí wọ́n lè máa bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé tó máa wáyé. Ó máa ná wa ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́rin owó dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Lára ohun tí wọ́n máa ṣe ni pé wọ́n á ṣàtúnṣe sí Gbọ̀ngàn Ìjọba méjìlá [12] ní erékùṣù Guadeloupe àti Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì pẹ̀lú ilé àwọn ará wa mẹ́rìnlélógún [24] ní erékùṣù St. Martin. Àwọn méjìlélógún [22] tó yọ̀ǹda ara wọn láti Ilẹ̀ Faransé, erékùṣù Guadeloupe àti Màtíníìkì ló máa ṣiṣẹ́ ìkọ́lé náà.

Ilé akéde kan ní St. Martin tó bà jẹ́ lẹ́yìn tí ìjì Hurricane Maria jà.

Àwọn Àgbègbè Tí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà Ń Bójú Tó​—Erékùṣù British àti U.S. Virgin, Florida, Georgia, Puerto Rico, Erékùṣù Turks àti Caicos

Àwọn akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá [13,000] ni ìjì líle náà ṣèpalára fún láwọn àgbègbè yìí. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ìgbìmọ̀ mẹ́rin tó ń ṣètò ìrànwọ́ ló ń ran àwọn ará wa lọ́kùnrin lóbìnrin lọ́wọ́, wọ́n sì ti parí apá àkọ́kọ́ nínú iṣẹ́ ìrànwọ́ yìí. Lára ohun tí wọ́n ti ṣe ni pé wọ́n ti ṣàtúnṣe sí èyí tó pọ̀ jù nínú ilé àwọn ará wa tó bà jẹ́, wọ́n sì pín oúnjẹ àti omi. Apá àkọ́kọ́ iṣẹ́ yìí ṣì ń lọ lórílẹ̀-èdè Puerto Rico àti ní erékùṣù British àti U.S. Virgin.

Àwọn òṣìṣẹ́ ń tún ilé ọ̀kan nínú àwọn akéde tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé igba [3,200] tó wà ní Puerto Rico ṣe lẹ́yìn tí ìjì líle jà.

Àpapọ̀ àwọn tó máa ṣèrànwọ́ láti tún àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ilé àwọn ará wa ṣe jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó dín mẹ́wàá [690]. Ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti àádọ́ta 450 máa ṣiṣẹ́ láwọn erékùṣù, igba ó lé ogójì [240] máa ṣiṣẹ́ ní Florida àti Georgia. Ohun tó lé ní ọgbọ̀n mílíọ̀nù owó dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà la máa ná sórí iṣẹ́ yìí, àwọn ibi tá a sì fẹ́ tún ṣe nìyí:

  • Erékùṣù British àti U.S. Virgin – Gbọ̀ngàn Ìjọba márùn-ún, ilé 190

  • Florida – Gbọ̀ngàn Ìjọba 40, ilé 1,174

  • Puerto Rico – Gbọ̀ngàn Ìjọba 106, Gbọ̀ngàn Àpéjọ méjì, ilé 1,216

  • Turks and Caicos – Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì, ilé 56

Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà fún gbogbo àwọn tó ń ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ yìí lókun. Ó dá wa lójú pé iṣẹ́ ìrànwọ́ yìí, títí kan bá a ṣe ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tu àwọn ará wa nínú, máa jẹ́ kí wọ́n lè borí ẹ̀dùn ọkàn tí àjálù fà bá àwọn ará wa, á sì jẹ́ kí wọ́n lè jọ máa sin Jèhófà, Ọlọ́run wa alágbára.​—Nehemáyà 2:18.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Barbados: John Medford, +1-246-438-0655

Dominican Republic: Josué Féliz, +1-809-595-4007

Ilẹ̀ Faransé: Guy Canonici, +33-2-32-25-55-55