Yorùbá
Wọ́n Fi Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́ Láwọn Orílẹ̀-Èdè Kan
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/1014757/univ/art/1014757_univ_sqr_xl.jpg

ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Viktor Stashevskiy ti wà lẹ́wọ̀n ní Crimea láti March 2021

Wọ́n Fi Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́ Láwọn Orílẹ̀-Èdè Kan

Wọ́n Fi Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́ Láwọn Orílẹ̀-Èdè Kan

Ní April 2026, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ lé ní igba ó lé mọ́kàndínlọ́gọ́rin (279).

Abala 18 nínú ìwé àdéhùn International Covenant on Civil and Political Rights sọ pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ sí òmìnira èrò, ẹ̀rí ọkàn àti ẹ̀sìn. Àmọ́ láwọn orílẹ̀-èdè kan, wọ́n máa ń fi ẹ̀tọ́ yìí du àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí ìjọba ń fìyà jẹ wọ́n láìtọ́, wọ́n sì ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n láìyẹ torí pé wọ́n ń ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́ tàbí torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè láti wọṣẹ́ ológun.

“Ẹ máa rántí àwọn tó wà nínú ẹ̀wọ̀n, bí ẹni pé ẹ jọ wà lẹ́wọ̀n.”—Hébérù 13:3.