SEPTEMBER 11, 2024
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ
A Mú Bíbélì Jáde Lédè Méje Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní August 2024
Èdè Ibinda
Ní August 2, 2024, Arákùnrin Carlos Hortelão tó wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lórílẹ̀-èdè Angola mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun àti ìwé Jẹ́nẹ́sísì, Rúùtù, Ẹ́sítà àti Jónà jáde lédè Ibinda. Ọjọ́ àkọ́kọ́ Àpéjọ Agbègbè ‘Ẹ Máa Kéde Ìhìn Rere!’ tá a ṣe nílùú Cabinda, lórílẹ̀-èdè Angola lọ́dún 2024 ni wọ́n mú Bíbélì náà jáde. Àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé mẹ́tàléláàádọ́ta (953) ló wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Gbogbo wọn ni wọ́n sì rí ẹ̀dà Bíbélì Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun náà gbà. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn èèyàn ti lè wa àwọn ìwé Bíbélì yìí jáde lórí jw.org àti JW Library.
Àwọn tó ń sọ ẹ̀dè Ibinda lórílẹ̀-èdè Angola ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́rìndínlógún (716,000) lọ. Èyí sì ni Bíbélì àkọ́kọ́ tó máa wà lédè Ibinda. Ní báyìí, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé márùnlélọ́gbọ̀n (335) ló wà níjọ mẹ́tàlá (13) àti àwùjọ kan tó ń sọ èdè Ibinda lórílẹ̀-èdè náà, inú wọn sì dùn gan-an nígbà tí wọ́n rí Bíbélì tó wà lédè ìbílẹ̀ wọn gbà.
Èdè Àwọn Adití Zimbabwe
Ní August 9, 2024, Arákùnrin Energy Matanda, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Zimbabwe mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì jáde ní Èdè Àwọn Adití Zimbabwe ní Àpéjọ Agbègbè ‘Ẹ Máa Kéde Ìhìn Rere!’ tá a ṣe nílùú Harare, ní Zimbabwe. Àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé márùn-ún (405) ló wá sí àpéjọ náà. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn èèyàn ti lè wa Bíbélì náà jáde lórí jw.org àti JW Library Sign Language.
Ọdún 2021 ni wọ́n mú ìwé Mátíù jáde ní Èdè Àwọn Adití Zimbabwe. Àtìgbà yẹn la ti ń mú àwọn ìwé míì tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì jáde díẹ̀díẹ̀ lédè yẹn. Àwọn tó ń sọ Èdè Àwọn Adití Zimbabwe tó mílíọ̀nù kan, lára wọn ni àwọn ará tí iye wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (377) tí wọ́n wà níjọ mọ́kànlá (11) àti àwùjọ mọ́kànlá (11) tó wà káàkiri orílẹ̀-èdè Zimbabwe.
Èdè Bulgarian
Ní August 11, 2024, Arákùnrin Mark Sanderson, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ fáwọn ará pé wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í tún Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti èdè Bulgarian ṣe. Nígbà tó sì ń sọ àsọyé tó kẹ́yìn ní Àkànṣe Àpéjọ ‘Ẹ Máa Kéde Ìhìn Rere!’ tá a ṣe nílùú Sofia, lórílẹ̀-èdè Bulgaria ní 2024, ó mú ìwé Mátíù, Máàkù àti Lúùkù tí wọ́n ti tún ṣe jáde. Àwọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti méjìdínlógún (5,418) ló wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn èèyàn sì ti lè wa ìwé mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí jáde lórí jw.org àti ní JW Library.
Ọdún 2009 ni wọ́n kọ́kọ́ mú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Bulgarian. Ní báyìí, àwọn ará tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ló wà ní Bulgaria, ìjọ mẹ́tàdínlọ́gọ́ta (57) ló sì wà níbẹ̀.
Èdè Aja
Ní August 16, 2024, Arákùnrin Bois Sylvain, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka West Africa mú ìwé Mátíù àti Máàkù jáde ní èdè Aja ní Àpéjọ Agbègbè ‘Ẹ Máa Kéde Ìhìn Rere!’ tá a ṣe nílùú Djakotomey, lórílẹ̀-èdè Benin lọ́dún 2024. Àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mọ́kànlélọ́gbọ̀n (631) ló wà ní àpéjọ náà. Àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé márùndínlógójì (435) míì tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ míì nílùú Abomey-Calavi, lórílẹ̀-èdè Benin wo ètò yìí látorí ìkànnì. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn èèyàn sì ti lè wa ìwé Bíbélì méjèèjì yìí jáde lórí jw.org àti JW Library.
Àwọn tó lé ní mílíọ̀nù kan ó lé ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba (1,200,000) ló ń sọ èdè Aja lórílẹ̀-èdè Benin àti Tógò. Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gírí ìkì wà ní ìtumọ̀ Bíbélì méjì míì ní èdè Aja. Àmọ́, àwọn èèyàn kì í tètè rí i rà, yàtọ̀ síyẹn, èdè tí wọ́n fi túmọ̀ rẹ̀ kò rọrùn lóye. Bákan náà, Bíbélì méjèèjì ti yọ Jèhófà orúkọ Ọlọ́run kúrò. Ní báyìí, ìjọ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) àti àwùjọ kan tó ń sọ èdè Aja ló wà lórílẹ̀-èdè Benin. Yàtọ̀ síyẹn, ìjọ méjìlá (12) àti àwùjọ méjì tó ń sọ èdè náà wà ní Tógò, àwọn ará tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (1,300) ló sì wà nínú àwọn ìjọ yẹn. Inú gbogbo àwọn ará yìí ló dùn nígbà tí wọ́n gba Bíbélì tí ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ yéni, tó sì lo orúkọ Jèhófà.
Èdè Kinyarwanda
Ní August 16, 2024, Arákùnrin Jeffrey Winder, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe jáde lédè Kinyarwanda. Ọjọ́ àkọ́kọ́ Àpéjọ Agbègbè ‘Ẹ Máa Kéde Ìhìn Rere!’ tá a ṣe nílùú Kigali, lórílẹ̀-èdè Rwanda lọ́dún 2024 ni Arákùnrin Winder mú Bíbélì náà jáde. Àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti méjọ (9,908) ló wà ní àpéjọ yẹn. Àwọn míì tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún àti mọ́kànlélógójì (1,141) wà ní àpéjọ méjì míì tí wọ́n ń wo ètò náà látorí ìkànnì. Gbogbo àwọn tó wà láwọn àpéjọ yìí ló rí ẹ̀dà Bíbélì náà gbà. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn èèyàn sì ti lè wa Bíbélì yìí àtèyí tá a gbohùn ẹ̀ sílẹ̀ jáde lórí jw.org àti JW Library.
Àwọn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́tàlá (13,000,000) ló ń sọ èdè Kinyarwanda ní Rwanda. Wọ́n tún máa ń sọ èdè Kinyarwanda láwọn orílẹ̀-èdè míì bíi Democratic Republic of the Congo, Tanzania àti Uganda. Ọdún 2010 ni wọ́n kọ́kọ́ mú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Kinyarwanda. Ní báyìí, àwọn ará tó ju ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (35,500) ló wà níjọ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (634) tó ń sọ èdè Kinyarwanda ní Rwanda.
Èdè Sinhala
Ní August 16, 2024, Arákùnrin David Splane, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe jáde lédè Sinhala ní Àpéjọ Agbègbè ‘Ẹ Máa Kéde Ìhìn Rere!’ tá a ṣe nílùú Colombo, lórílẹ̀-èdè Sri Lanka lọ́dún 2024. Ọjọ́ àkọ́kọ́ àpéjọ agbègbè náà ni Arákùnrin Splane mú Bíbélì náà jáde, àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún méjì àti mẹ́tàléláàádọ́rin (4,273) ló sì wà níbẹ̀. Bákan náà, àwọn ẹgbẹ̀rún kan ó lé márùndínláàádọ́ta (1,045) tó wà ní àpéjọ agbègbè tó ń lọ lọ́wọ́ nílùú Chilaw, ní Sri Lanka náà wo ètò yìí látorí ìkànnì. Gbogbo àwọn tó wà láwọn àpéjọ méjì yìí ló rí ẹ̀dà Bíbélì náà gbà. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn èèyàn sì ti lè wa Bíbélì yìí jáde lórí jw.org àti ní JW Library.
Ó ti lé lọ́dún márùndínlọ́gọ́rin (75) báyìí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ àwọn ìwé wa sí èdè Sinhala. Ní báyìí, àwọn tó ń sọ èdè Sinhala lórílẹ̀-èdè Sri Lanka ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000,000), lára wọn ni àwọn ará wa tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti mẹ́jọ (4,808) tí wọ́n wà ní ìjọ méjìlélọ́gọ́ta (62) tó ń sọ èdè náà ní Sri Lanka.
Èdè Wallisian
Ní August 30, 2024, Arákùnrin Martin Décousus, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè New Caledonia mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Wallisian ní Àpéjọ Agbègbè ‘Ẹ Máa Kéde Ìhìn Rere!’ tá a ṣe lọ́dún 2024. Ìlú Nouméa ní New Caledonia àtàwọn abúlé méjì míì, ìyẹn Mala’e àti Wallis and Futuna ni wọ́n ti ṣe àpéjọ agbègbè náà. Orí ìkànnì làwọn tó wà láwọn abúlé yìí ti wo ètò náà. Gbogbo àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mẹ́tàdínlógún (317) tó wà ní àpéjọ náà ló rí ẹ̀dà Bíbélì náà gbà. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn èèyàn sì ti lè wa Bíbélì yìí jáde lórí jw.org àti ní JW Library.
Ọdún 2018 ni wọ́n mú Bíbélì Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Wallisian. Àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó jẹ́ mẹ́tàléláàádọ́jọ (153) tó wà níjọ méjì tó ń sọ èdè Wallisian ní New Caledonia àti ní Wallis and Futuna ń fojú sọ́nà láti lo Bíbélì tuntun yìí tí wọ́n bá ń wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì (35,000) tó ń sọ̀ èdè Wallisian láwọn ilẹ̀ yìí.

