APRIL 17, 2020
FÍJÌ
Ìjì Líle Harold Ba Ọ̀pọ̀ Nǹkan Jẹ́ Láwọn Erékùṣù Vanuatu àti Fíjì
Ìjì líle kan tó lágbára tí wọ́n ń pè ní Cyclone Harold jà ní apá àríwá àwọn erékùṣù tó wà ní Vanuatu ní April 5, 2020, ó sì ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́. Lẹ́yìn ìyẹn, ní April 8, ó tún ṣọṣẹ́ ní àwọn erékùṣù tó wà ní Fíjì, ó sì tún ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́ níbẹ̀ náà. Nínú ìròyìn tá a kọ́kọ́ gbọ́, kò sí èyíkéyìí lára àwọn arákùnrin wa tó ṣèṣe, a ò sì gbọ́ pé ẹnì kankan lára wọn kú.
Àwọn akéde tó tó ọgọ́rùn-ún méjì àti ọgọ́rin (280) ló ń gbé ní erékùṣù Espiritu Santo, ìyẹn erékùṣù tó tóbi jù lápá àríwá Vanuatu. Ńṣe làwọn ilé sùn lọ bẹẹrẹbẹ, ó sì ba àwọn nǹkan ọ̀gbìn jẹ́, ohun kan náà ló ṣe láwọn erékùṣù míì tó wà nítòsí. Ní Fíjì, ó bá ilé àwọn ará wa bí ọgọ́rùn-ún méjì àti ọgọ́ta (260) jẹ́ gan-an. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣàkóbá gan-an, débi pé tipátipá ni wọ́n fi ń rí omi lo, iná ò sì, bẹ́ẹ̀ sì ni oúnjẹ ṣọ̀wọ́n.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní Fíjì ń ṣètò báwọn ará wa ṣe máa rí àwọn ohun tí wọ́n nílò. Bákan náà, àwọn alàgbà ìjọ ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin kí wọ́n lè tù wọ́n nínú kí wọ́n sì fún wọn níṣìírí. Inú wa dùn pé àwọn ará wa tó wà níbi tí ìjì ti jà yìí ń rí àbójútó torí pé wọ́n ń rí ìtùnú látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn ohun kòṣeémáàní tí wọ́n nílò sì ń tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́.—Òwe 17:17.

