Habtemichael Tesfamariam àti ìyàwó ẹ̀, Leterberhan Bezabih, kí wọ́n tó fi sẹ́wọ̀n

APRIL 25, 2018
ERITREA

Ẹlẹ́rìí Jèhófà Méjì Tó Ti Dàgbà Kú Sẹ́wọ̀n ní Eritrea

Ẹlẹ́rìí Jèhófà Méjì Tó Ti Dàgbà Kú Sẹ́wọ̀n ní Eritrea

Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì, ìyẹn Habtemichael Tesfamariam àti Habtemichael Mekonen, kú sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Mai Serwa nítòsí ìlú Asmara níbẹ̀rẹ̀ ọdún 2018. Ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 2008 ni wọ́n ti mú wọn, tí wọ́n sì ti fi wọ́n sẹ́wọ̀n torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Wọ́n fojú wọn gbolẹ̀ gan-an lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, díẹ̀ ló kù kí àkókò táwọn méjèèjì fi jìyà níbẹ̀ tó ọdún mẹ́wàá.

Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Mai Serwa ni Ọ̀gbẹ́ni Tesfamariam ti kú lójijì ní January 3, 2018, lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (76). Àwọn tí wọ́n jọ wà lẹ́wọ̀n sọ pé àrùn rọpárọsẹ̀ ló mú un. Ọdún 1942 ni wọ́n bí Ọ̀gbẹ́ni Tesfamariam ní Adi Yakulu, nílùú Mendefera lórílẹ̀-èdè Eritrea. Ó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1970, bí wọ́n sì ṣe fìyà jẹ ẹ́ tó, tí wọ́n tún jù ú sẹ́wọ̀n láìtọ́, kò yẹhùn lórí ohun tó gbà gbọ́. Ìyàwó rẹ̀, Leterberhan Bezabih, pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́rin àti ọmọbìnrin rẹ̀ mẹ́ta ṣì wà.

Ọ̀gbẹ́ni Mekonen kú sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Mai Serwa ní March 6, 2018, lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (77). Àwọn tí wọ́n jọ wà lẹ́wọ̀n sọ pé kíndìnrín rẹ̀ tó daṣẹ́ sílẹ̀ ló pa á. Ọdún 1940 ni wọ́n bí Ọ̀gbẹ́ni Mekonen ní abúlé Kudo Felasi lápá gúúsù orílẹ̀-èdè Eritrea. Ó ti lé ní ọdún márùndínlọ́gọ́ta (55) tó ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, òun náà ò sì yẹhùn lórí ohun tó gbà gbọ́ bíi ti Ọ̀gbẹ́ni Tesfamariam, láìka bí wọ́n ṣe fìyà jẹ ẹ́ tó, tí wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n láìtọ́. Ìyàwó tiẹ̀ náà, Mihret Ellias, ṣì wà, pẹ̀lú ọmọkùnrin kan àti ọmọbìnrin kan.

Wọ́n Mú Wọn Láìtọ́, Wọ́n sì Fìyà Jẹ Wọ́n

Ilé ni Ọ̀gbẹ́ni Mekonen wà ní July 2008 nígbà táwọn aláṣẹ mú un láìfi ẹ̀sùn kàn án, ilé náà sì ni Ọ̀gbẹ́ni Tesfamariam wà nígbà tí wọ́n mú un ní August 2008. Kò pẹ́ tí wọ́n fi ju àwọn méjèèjì sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Meitir táwọn èèyàn mọ̀ síbi tí wọ́n ti ń fìyà páni lórí, tó wà ní aṣálẹ̀ lápá àríwá ìlú Asmara. Wọ́n fayé ni wọ́n lára gan-an níbẹ̀, wọ́n sì hùwà ìkà sí wọn. Nígbà táwọn aláṣẹ fẹ́ dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóró lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, wọ́n fi wọ́n sínú ilé kan tí ìdajì ẹ̀ wà nínú ilẹ̀, wọ́n ń pe ibẹ̀ ní “àjà ilẹ̀.” October 2011 sí August 2012 ni wọ́n fi wà níbẹ̀. Ooru tó légbá kan tó máa ń mú lásìkò ẹ̀ẹ̀rùn han àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà léèmọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí oúnjẹ àti omi tí ó tó. Ibẹ̀ ni àwọn kan ti kó àrùn ọlọ́jọ́ pípẹ́.

Lọ́dún 2017, àwọn aláṣẹ kó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Meitir lọ sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Mai Serwa, wọ́n gba àwọn mọ̀lẹ́bí wọn láyè láti máa gbé oúnjẹ wá fún wọn níbẹ̀, wọ́n sì gbà wọ́n láyè láti máa gbàtọ́jú tí àìsàn tó le bá ń ṣe wọ́n. Inú àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà dùn pé wọ́n gbé wọn lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n míì tí nǹkan ti dẹrùn ju ti tẹ́lẹ̀, àmọ́ ràbọ̀ràbọ̀ ohun tójú Ọ̀gbẹ́ni Tesfamariam àti Ọ̀gbẹ́ni Mekonen ti rí ò tán lára wọn.

Habtemichael Mekonen àti ìyàwó ẹ̀, Mihret Ellias, kí wọ́n tó fi sẹ́wọ̀n

Ọ̀gbẹ́ni Tesfamariam àti Ọ̀gbẹ́ni Mekonen kọ́ ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà àkọ́kọ́ tó máa kú sẹ́wọ̀n tàbí tó máa kú kété lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀ ní Eritrea. Torí ìyà tí wọ́n fi jẹ àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti ìwà ìkà tí wọ́n hù sí wọn níbẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì míì kú sẹ́wọ̀n, àwọn mẹ́ta míì sì kú kété lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀. Ó kéré tán, Ẹlẹ́rìí Jèhófà méje tí wọ́n dá sílẹ̀ lẹ́wọ̀n lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn ṣì ń bá ìṣòro àìlera tó le gan-an fà á di báyìí, bẹ́ẹ̀, ohun tójú wọn rí lẹ́wọ̀n ló dá àìsàn sí wọn lára. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ṣì wà lẹ́wọ̀n ní Eritrea torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ jẹ́ mẹ́tàléláàádọ́ta (53), Tareke tó jẹ́ àbúrò Ọ̀gbẹ́ni Tesfamariam sì wà lára wọn.

“Ìwà Ìkà Gbáà” Ni Inúnibíni Tí Wọ́n Ń Ṣe

Ní June 8, 2016, Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè gbé ìròyìn kan jáde tó dá lórí ìwádìí Àjọ Tó Ń Ṣèwádìí Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní Eritrea (ìyẹn àjọ COIE). Ohun tó mú kí àjọ náà ṣèwádìí ọ̀hún ni pé wọ́n fẹ́ tọ pinpin bí àwọn aláṣẹ ṣe ń fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn du àwọn aráàlú ní Eritrea. Àjọ COIE rọ ìjọba Eritrea pé kí wọ́n “má fi òmìnira ẹ̀sìn tàbí ti ìgbàgbọ́ du àwọn èèyàn,” kí wọ́n sì “fòpin sí bí wọ́n ṣe ń mú àwọn èèyàn, tí wọ́n sì ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n láìnídìí torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́, pàápàá àwọn ẹlẹ́sìn pàtó kan, bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà,” kí wọ́n sì “dá gbogbo àwọn tí wọ́n mú láìtọ́, tí wọ́n tì mọ́lé láìnídìí sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láìbéèrè ohunkóhun lọ́wọ́ wọn.” Ibi tí àjọ COIE parí èrò sí ni pé “ìwà ìkà gbáà” ni bí ìjọba Eritrea ṣe ń ṣe inúnibíni sáwọn èèyàn torí ẹ̀sìn wọn.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń retí pé àwọn èèyàn kárí ayé máa gbọ́ nípa ikú tó pa Ọ̀gbẹ́ni Tesfamariam àti Ọ̀gbẹ́ni Mekonen àti pé ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí máa mú kí àwọn aláṣẹ tó lọ́kàn tó dáa ní Eritrea gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n láìtọ́ torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́.