Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Eritrea
Orílẹ̀-èdè Eritrea ni wọ́n ti ń gbógun ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jù. Àtìgbà tí orílẹ̀-èdè náà ti gbòmìnira lọ́dún 1993 ni ìjọba ti ń fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n léraléra, tí wọ́n fìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n sì ń yọ wọ́n lẹ́nu. Ní October 25, 1994, ààrẹ kéde pé ìjọba ti gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀tọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní pé wọ́n jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ torí pé wọn ò dá sí òṣèlú, wọ́n sì kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn pàtàkì tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilẹ̀ Eritrea.
Bí wọ́n ṣe ń gbógun ti àwọn Ẹlẹ́rìí láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, tí wọ́n sì ń ni wọ́n lára yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ nínú wọn sá kúrò nílùú. Àwọn tó ṣẹ́ kù níbẹ̀ ò rímú mí, ó sì gba kí wọ́n máa ṣọ́ra ṣe gidigidi tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ohunkóhun tó jẹ mọ́ ẹ̀sìn wọn. Látọdún yìí wá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Eritrea ti mú, tí wọ́n sì rán lọ sẹ́wọ̀n. Torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí àwọn kan ṣiṣẹ́ ológun ni wọ́n ṣe mú wọn, wọ́n mú àwọn míì torí pé wọ́n ń pàdé pọ̀ láti jọ́sìn Ọlọ́run, wọ́n sì ń bá àwọn míì sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, àmọ́ àwọn aláṣẹ ò sọ ìdí tí wọ́n ṣe mú àwọn míì. Tọkùnrin tobìnrin àtàwọn tó ti dàgbà ni wọ́n ń rán lọ sẹ́wọ̀n, kódà nígbà míì, wọ́n máa ń fi àwọn ọmọdé sẹ́wọ̀n. Ó ti lé ní ogún ọdún tí àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí ti wà lẹ́wọ̀n. Ìjọba ò pè wọ́n lẹ́jọ́ débi tí wọ́n á gbọ́ ẹjọ́ wọn, tí wọ́n á fi mọ̀ pé wọ́n jẹ̀bi kí wọ́n tó rán wọn lọ sẹ́wọ̀n.
Ìyà tó ń jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Eritrea yìí ti détí ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba láti ilẹ̀ Áfíríkà, Yúróòpù àti Amẹ́ríkà ti kàn sí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Eritrea lórí ọ̀rọ̀ yìí, àmọ́ ohun tí ìjọba ti ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí ò tó nǹkan. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ti kọ̀wé sí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè náà nílùú Asmara pé kí wọ́n jọ sọ̀rọ̀ yìí ní ìtùnbí-ìnùbí, àmọ́ ìjọba ò dá wọn lóhùn.

