Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW LANGUAGE

Àwọn Ohun Tó Wà Lórí JW Language

Àwọn Ohun Tó Wà Lórí JW Language

Èdè Tó Wà

Arabic, Bengali, Chinese Cantonese (Traditional), Chinese Mandarin (Simplified), Faransé, German, Gẹ̀ẹ́sì, Hindi, Indonesian, Italian, Japanese, Korean, Low German, Malay, Myanmar, Potogí, Russian, Spanish, Swahili, Tagalog, Thai, Turkish, Vietnamese.

 

Ohun Tá A Lè Lò Lóde Ẹ̀rí

Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú JW Language dá lórí ìwàásù, kíkọ́ni àtàwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì. Àwọn àṣàrò kúkúrú náà wà níbẹ̀ tí ẹni tó ń kọ́ èdè lè máa fi wéra ní èdè tó ń sọ àti èdè tó ń kọ́.

Bó O Ṣe Lè Kọ́ Èdè

  • Lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, máa ka ọ̀rọ̀ ní èdè tó ò ń sọ, kó o sì máa kà á ní èdè tó o fẹ́ kọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kejì

  • Gbọ́ bí ẹnì kan tó mọ èdè náà ṣe ń pe ọ̀rọ̀ tàbí bó ṣe ń kàwé

  • Wo àwọn fídíò tó dá lórí iṣẹ́ ìwàásù ní èdè tó o fẹ́ kọ́

  • Máa fi àwòrán kẹ́kọ̀ọ́

  • Wo bí wọ́n ṣe ń fi oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ hun ọ̀rọ̀ pọ̀ ní apá tá a pè ní Grammar

  • Ṣe ìdánrawò

    • Lábẹ́ Look: Yan ọ̀rọ̀ tó bá àwòrán tó o rí mu

    • Lábẹ́ Match: Yan àwọn ohun tó bára mu

    • Lábẹ́ Listen: Yan ọ̀rọ̀ tó bá ohun tó o gbọ́ mu

    • Lábẹ́ Flash Cards: Wò ó bóyá o mọ ìtúmọ̀ ohun tó o rí

    • Lábẹ́ Audio Lesson: Gbọ́ àtẹ́tísí tí wọ́n ti ń ka ọ̀rọ̀ jáde, ó máa dúró díẹ̀ fún ẹ kíwọ náà lè máa kà á tẹ̀ lé e

Ṣe É Bó O Ṣe Fẹ́

  • Tọ́jú àwọn àwòrán àtàwọn ọ̀rọ̀ tó o yàn láàyò kó o lè máa tètè rí wọn

  • Ṣe àtẹ́tísí lọ́nà táá fi máa yára sọ̀rọ̀ tàbí rọra sọ̀rọ̀

  • Jẹ́ kó fi álífábẹ́ẹ̀tì òde òní kọ ọ̀rọ̀ àbí kó má ṣe bẹ́ẹ̀

  • Wa ìsọfúnni tó wà lórí ẹ̀ jáde kó o lè máa lò ó láìsí íńtánẹ́ẹ̀tì

  • Ṣe àwọn fídíò lọ́nà tí kò fi ní jẹ àyè tó pọ̀ lórí fóònù ẹ

Fi Álífábẹ́ẹ̀tì Òde Òní Kọ Ọ̀rọ̀

Láwọn èdè tí kì í lo álífábẹ́ẹ̀tì òde òní, o máa rí i tá a fi álífábẹ́ẹ̀tì òde òní kọ ọ̀rọ̀ láwọn èdè yẹn.

Ìrànlọ́wọ́

Tó o bá níṣòro pẹ̀lú JW Language, jọ̀wọ́ kọ̀wé kúnfọ́ọ̀mù wa lórí ìkànnì,kó o sì fi ránṣẹ́.