Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀, Ìfẹ́ Máa Ń Mú Ká Ṣèrànwọ́

Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀, Ìfẹ́ Máa Ń Mú Ká Ṣèrànwọ́

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ran àwọn ará wa àtàwọn míì lọ́wọ́ nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀. Ìfẹ́ tá a fi ń hàn sí ara wa yìí fi han pé Kristẹni tòótọ́ ni wá.​—Jòhánù 13:35.

A máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ibi tá a ti ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn láàárín 2011 sí 2012. A ò ní wulẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe máa ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tu àwọn èèyàn nínú tá a sì tún máa ń bá wọn kẹ́dun. Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù tí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ṣètò ló sábà máa ń bójú tó èyí tó pọ̀ jù lára ìrànwọ́ yìí. Àwọn ìjọ tó wà káàkiri náà sì máa ń ṣèrànwọ́ lóòrèkóòrè.

Japan

Japan: Ní March 11, 2011, ìmìtìtì ilẹ̀ kan wáyé ó sì yọrí sí àkúnya omi, ọ̀pọ̀ èèyàn ni jàǹbá kàn ní àríwa orílẹ̀-èdè Japan. Gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé fi owó, iṣẹ́ ọwọ́ wa àtàwọn nǹkan míì ṣètìlẹ́yìn. Wo fídíò wa tó sọ̀rọ̀ nípa ìmìtìtì ilẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Japan àti bá a ṣe ṣèrànwọ́.

Brazil: Omíyalé, ilẹ̀ tó rì àti ẹrẹ̀ tó ya wọ̀lú pa ọ̀pọ̀ èèyàn. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó àwọn oúnjẹ tí kò lè tètè bà jẹ́ tó wúwo tó 840 àpò sìmẹ́ǹtì, 20,000 omi inú ike, àwọn ìdìpọ̀ aṣọ tó wúwo tó 200 àpò sìmẹ́ntì, àwọn nǹkan ìmọ́tótó tó wúwo tó 100 àpò sìmẹ́ntì, tó fi mọ́ àwọn oògùn àtàwọn nǹkan míì.

Kóńgò (Brazzaville): Nígbà tí ibi tí wọ́n ń kó àwọn ohun ìjà ogun sí bú gbàù, ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rin ló wó kanlẹ̀, ó sì ba ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìdínlọ́gbọ̀n [28] jẹ́. A fún àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn ní oúnjẹ àti aṣọ, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nítòsí sì tún gba àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kàn sílé.

Kóńgò (Kinshasa): A fún àwọn tó ní àrùn kọ́lẹ́rà ni oògùn. Òjò ńlá kan mú kí omíyalé ṣẹlẹ̀, a sì fún àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn ní aṣọ. A pèsè ìrànwọ́ ní ti ọ̀rọ̀ ìlèra, a fún àwọn tó wà ní ibùdó àwọn tí àjálù lé kúrò nílùú ní irúgbìn tí wọ́n lè gbìn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ.

Venezuela: Òjò ńlá kan tó rọ̀ fa omíyalé, ó sì tún mú kí ẹrẹ̀ ya wọ̀lú. Ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ ran 288 àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ọ̀rọ̀ kàn lọ́wọ́. Wọ́n kọ́ àwọn Ilé tuntun tó jù àádọ́ta [50] lọ. Yàtọ̀ síyẹn, ìgbìmọ̀ yìí tún ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ṣeé ṣe kí adágún omi Valencia tó ti ń kún àkúnya wu léwu.

Philippines

Philippines: Ìjì líle fa àkúnya omí ní àwọn apá ibì kan lórílẹ̀-èdè yìí. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn fi àwọn oúnjẹ àti aṣọ ránṣẹ́ sí àwọn tí ìṣẹlẹ̀ náà kàn, nígbà tí omi yẹn sì lọlẹ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nítòsí ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ.

Kánádà: Lẹ́yìn tí igbó ẹgàn kan múná nílùú Alberta, àwọn ìjọ fi owó tó pọ̀ gan-an ṣe ìtìlẹ́yìn kí ìjọ Slave Lake lè rí owó ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. Àmọ́ torí pé kì í ṣe gbogbo owó yẹn ni wọ́n lò tán, ìjọ yìí náà tún fi èyí tó ju ìdajì nínú owó yẹn ṣètìlẹ́yìn fún àwọn tí àjálú ṣẹlẹ̀ sí láwọn ibòmíì lágbàáyé.

Côte d’Ivoire: Kí ogun tó bẹ̀rẹ̀, nígbà tí ogun ń lọ lọ́wọ́ àti lẹ́yìn ogun, a pèsè oúnjẹ, ibùgbé àti ìrànwọ́ ní ti ọ̀rọ̀ ìlera fún àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn.

Fíjì: Nítorí òjò ńlá tó rọ̀, àkúnya omí mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí tó tó 192 pàdánù oko wọn, àtàwọn ibi iṣẹ́ tó ń mú oúnjẹ àti owó wọlé fún wọn. A fi ọ̀pọ̀ oúnjẹ ránṣẹ́ sí wọn.

Gánà: A pèsè oúnjẹ, irúgbìn, àtàwọn ibi tí èèyàn lè sùn sí fún àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn nígbà tí omíyalé ṣẹlẹ̀ ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè yìí.

Amẹ́ríkà: Ìjì líle ba ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhofà mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] jẹ́ ní ìpínlẹ̀ mẹ́ta, ó sì wó ilé àwọn méjìlá kanlẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn onílé náà ló ti ṣe ìbánigbófò ilé wọn, síbẹ̀ a ṣì fi owó ṣètìlẹ́yìn kí wọ́n lè lò ó fáwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì.

Ajẹntínà: Àwọn ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ran àwọn tí eérú òkè ayọnáyèéfín ba ilé wọn jẹ́ ní gúúsù orílẹ̀-èdè yìí.

Mozambique: Nígbà tí ọ̀dá omi ṣẹlẹ̀, a pèsè oúnjẹ fún àwọn èèyàn tó ju ẹgbẹ̀rún kan lọ tí ọ̀rọ̀ náà kàn.

Nigeria: A fi owó ṣèrànwọ́ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rìnlélógún [24] tí wọ́n ní jàǹbá ọkọ̀. A tún ṣèrànwọ́ fún àwọn tó wà ní apá àríwá orílẹ̀-èdè náà nítorí ogun kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tó sọ àwọn kan di aláìnílé lórí.

Benin: A pèsè oògùn, aṣọ, àwọ̀n apẹ̀fọn, omi tó mọ́ àti ibùgbé fún àwọn tí omíyalé ṣe lọ́ṣẹ́.

Dominican Republic

Dominican Republic: Lẹ́yìn tí ìjì ńlá jà nílùú Irene, àwọn ijọ̀ bá àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn tún ilé wọn ṣe wọ́n sì tún pèsè àwọn ìrànwọ́ míì.

Etiópíà: Nígbà tí ọ̀dá òmi ṣẹlẹ̀ ní àwọn ibi méjì kan, tí omíyalè sì tún ṣẹlẹ̀ níbòmíì, a fi owó ṣètìlẹ́yìn kí àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn lè rí ìrànwọ́ tó yẹ gbà.

Kéńyà: A fi owó ṣètìlẹ́yìn fún àwọn tí ọ̀dá òmi dá.

Màláwì: A pèsè ìrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n wà ní ibùdó àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí ní Dzaleka.

Nepal: Nígbà tí ilẹ̀ rì, ó ba ilé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan jẹ́. A ṣètò ibi kan tó lè máa gbé fún ìgbà díẹ̀, àwọn ìjọ tó wà nítòsí sì tún pèsè ìrànlọ́wọ́ míì tó yẹ.

Papua New Guinea: Àwọn bàsèjẹ́ dáná sun ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́jọ. A tún àwọn ilé míì kọ́ fún wọn.

Ròmáníà: Omíyalé sọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan di aláìnílé lórí. A kọ́ àwọn ilé míì fún wọn.

Málì: Àwọn ìjọ tó wà ní orílẹ̀-èdè Senegal fi owó ṣètìlẹyìn fún àwọn tí ọ̀dá omi ba irè oko wọn jẹ́.

Sierra Leone: Àwọn dókítà kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti orílẹ̀-èdè Faransé ṣètọ́jú àwọn tí ogun ṣe lọ́ṣẹ́.

Thailand: Ọ̀pọ̀ ibi ni omíyalé ti bá dúkìá àwọn èèyàn jẹ́. Àwọn tó ń pèsè ìrànwọ́ ṣàtúnṣe ọgọ́rùn-ún [100] ilé àti Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́fà.

Czech Republic: Lẹ́yìn tí omíyalé ba ọ̀pọ̀ ilé jẹ́ lórílẹ̀-èdè Czech Republic, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní orílẹ̀-èdè Slovakia to sún mọ́ wọn pèsè ìrànwọ́.

Sri Lanka: Èyí tó pọ̀ jù lára ètò ìrànwọ́ tó ń lọ lọ́wọ́ níbẹ̀ látàrí àkúnya omi tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ ló ti parí.

Sudan: A pèsè oúnjẹ, aṣọ, bàtà àtàwọn láílọ́ọ̀nù fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ogun lé kúrò nílùú.

Tanzania: Nígbà omíyalé, àwọn ìdílé mẹ́rìnlá pàdánù àwọn ohun ìní wọn. Àwọn ìjọ tó wà nítòsí fún wọn ní àwọn aṣọ àtàwọn ohun èlò inú ilé tí wọ́n nílò. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún ilé kan kọ́.

Sìǹbábúwè: Ọ̀dá omi fa àító oúnjẹ lápá ibì kan lórílẹ̀-èdè yìí. A fi oúnjẹ àti owó ṣètìlẹ́yìn fún àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn.

Bùrúńdì: A pèsè ìrànwọ́, tó fi mọ́ ìtọ́jú ìlera fún àwọn tó wà ní ibùdó àwọn tí àjálù dé bá.